Èmi àti Mo Bimpe ti kọ etí ikún sáwọn tó ń pe ìyàwó mi lágàn - Adedimeji

AWoran Lateef Adedimeji ati Mo Bimpe

Oríṣun àwòrán, Lateef Adedimeji/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọmọ ni arikẹ, ọmọ ni ariyọ, ọmọ ni i ṣe ilede lẹyin ẹni, ki Eledua jẹ ka ri ọmọ gbe jo.

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Lateef Adedimeji, ti sọ pe oun ati iyawo oun Mo Bimpe ti kọ eti ikun sawọn to n pe aya oun ni agan.

Ninu ifọrọwerọ kan ti o ṣe laipẹ yii ni Adedimeji ti sọ pe gbogbo eebu atawọn ọrọ kobakungbe tawọn eeyan n sọ sawọn tori ai tii bimọ ko tun irun kankan lara awọn mejeeji.

Nigba to n fesi sọrọ kan tawọn eeyan kan sọ pe Lateef funra rẹ ti bimọ ki o to ṣe igbeyawo pẹlu Mo Bimpe ati pe obinrin kan to n fẹ wa niluu London, Adedimeji dahun wi pe awọn eeyan to n sọrọ ko mọ ohunkohun nipa igbesẹ idile oun lori ati bimọ.

''Koda, awọn kan n pe iyawo mi ni agan, amọ, gbogbo ọrọ yii ko ni ipa kankan lara wa.

Gbogbo igba ni emi ati iyawo mi maa n sọrọ nipa rẹ tori awọn eeyan maa n tabuku wa gan an ni lori itakun ayelujara.

Laipẹ yii ni iyawo mi fi ibi ti ẹnikan ti pe ni agan han mi, o ni ọpọ igba lawọn eeyan maa n pe oun loriṣiiriṣii bayii.

Mo ni lati sọ fun un wi pe ko maa ronu nipa rẹ tori ohun ti wọn n sọ yoo pada ṣẹlẹ nigba ti asiko ba to.

Awọn eeyan o mọ boya ọkọ ati iyawo pinnu lati ma tete bimọ lẹyin igbeyawo wọn.''

''ko si bawọn eeyan ko ṣe ni sọ nipa ẹnikẹni to ba di ilumọọka lẹnu iṣẹ rẹ''

Adedimeji tawọn n wo ere rẹ 'Lisabi' lọwọ bayii lori Netflix sọ pe ara awọn ipenija tawọn to jẹ ilumọọka lẹnu iṣẹ maa n koju ni ọrọ tawọn eeyan n sọ nipa ẹbi oun.

O ni oun ati iyawo oun ti pinnu lati dara awọn ni inu dun, ati wi pe ọrọ tawọn eeyan n sọ nipa awọn ti di ipakọ o gbọ suti, ọri ẹlẹgan lo daru.

Adedimeji ni ''ko si bawọn eeyan ko ṣe ni sọ nipa ẹnikẹni to ba di ilumọọkan lẹnu iṣẹ rẹ.

Amọ, ohun to ṣe pataki ni pe ki a gbajumọ awọn nnkan to ṣe pataki eyun n ni ifẹ ati awọn afojusun wa.''

Ọpọ eeyan lo ti n sọ nipa Mo Bimpe wi pe ko gbewọn to lati jẹ aya Lateef, ṣugbọn awọn mejeeji ṣe ara wọn lọkan lai na an ohun tawọn eeyan n sọ nipa wọn.

Lateef tiẹ sọ pe ko si ohun tawọn eeyan ko le sọ si ẹni to ba ti jẹ ilumọọka lẹnu iṣẹ rẹ.

''Awọn mi le fẹran rẹ, bakan naa, awọn eeyan mii le korira rẹ.

Ohun to ṣe pataki ni pe ki eeyan mọ nnkan ti o n ṣe tori a mọ pe kii ṣe gbogbo eeyan ni fẹran wa.