Nǹkan tó yẹ kóo mọ̀ nípa ọdún Oshoosi ní Ile Ife

Aworan oriṣa Ọṣọọṣi ati Ọọni ile ifẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ni ilẹ Yoruba, gbogbo oriṣa ni ọpọ gbagbọ pe wọn jẹ oninuurẹ sugbọn pataki ni Obatala jẹ ni ilẹ Yoruba, paapa niluu Ile Ife.

Odun Oshoosi jẹ ayẹyẹ to n ma n waye ni ọdọdun lati fi anfani silẹ fun awọn to jẹ ẹlẹsin Obatala lati gba adura.

Oshoosi jẹ oriṣa ilẹ Yoruba sugbọn ti ọpọ awọn lo n bọ lati oke okun paapa orilẹede Brazil ati Cuba.

Oshoosi yí pada si okuta, ti wọn yoo si gbe orí okuta naa síta lasiko ọdun.

Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa ọṣọọṣi gan

Aworan ajọdun Ọṣọọṣi

Oshoosi jẹ oriṣa to n dirọ mọ ṣíṣe Ọdẹ, Igbo, ẹranko ati Ọla.

Aburo Ogun laakaye ni Oshoosi jẹ to si ogboju ode ninu igbo.

Ẹranko ni wọn fi n bo Oshoosi.

O ni ẹru kan ti orukọ rẹ n jẹ 'Ka to ka ki ki kí, ka fi ẹnu rẹ sọ lẹ', to si jẹ pe oun lo kun ile Oshoosi ni funfun lati fi apẹẹrẹ Ọlọrun han

Aworan Oriṣa Ọṣọọṣi

Igbagbọ awọn ẹlẹsin Obatala ni pe bi awọn eeyan ṣe n pe jọ ṣe ẹṣin bẹrẹ lati Ile Ife gẹgẹ bii alaye ti itan fi lelẹ

Awọn naa ka a si awọn ẹṣin bi Kristẹni ati esin musulumi.

Bakan naa ni wọn gbagbọ pe Oshoosi tí waye saaju Jesu Kristi ati Anọbi Muhammad.

Bawo ni wọn ṣe n ṣe ọdun yii?

Aworan Ọọni ati ọkan ninu awọn olori rẹ

Aṣọ funfun ni awọn ẹlẹsin ibilẹ yii ma n wọ lati fi ṣe ayẹyẹ yii

Ọpọ eeyan kaakiri origun mẹrẹrin agbaye lo ma peju si ojude ojubọ Obatala paapa Ooni ti ilu ile ife, Oba Enitan Ojaja Ogunwusi.

Ooni yoo pẹlu awọn olorisha bi wọn ba se n gbe orí oriṣa síta fun etutu.

Yatọ si Ooni, awọn oloye ilu Ile Ife ni yoo wa niluu Ile Ife lasiko Ọdun Oshoosi.