Ìjọba UK yóò dá owó tó lé ní ₦5b tí àwọn olórí jí padà fún Naijiria

Oríṣun àwòrán, AFP
Ile ẹjọ kan ni Jersey, nilẹ Gẹẹsi, ti dajọ pe wọn le awọn dukia kan to jẹ ti Naijiria pada.
Eyii lo n waye lẹyin ti adajọ agba Jersey paṣẹ fun ile ẹjọ kan nibẹ pe ko ṣe bẹẹ.
Ile ẹjọ naa ni owo tabua to wa lawọn ile ifowopamọ kan nibẹ ṣeeṣe ko jẹ eyii ti awọn to n dari ijọba Naijiria ji ko lọdun 2014.
Ni bayii, Jersey ati ijọba Naijiria yoo jiroro lori bi wọn yoo ṣe da awọn owo ati dukia naa pada.
Ijọba Jersey sọ pe owo naa ni ijọba Naijiri fi ranṣe silẹ oun labẹ asia pe oun fẹ ra ohun ija oloro lati koju ikọ Boko Haram laarin ọdun 2009 si 2015.
O ṣalaye siwaju pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ọpọ ninu owo ti ijọba Naijiria fẹ fi ra ohun ija oloro naa ni awọn kan ninu ijọba ọhun n ko si apo ara wọn lọdun naa lọhun.
Atẹjade lati ọọfisi adajọ agba Jersey sọ pe igbagbọ wa pe awọn mọlẹbi awon to wa nijọba ṣaaju eto idibo ọdun 2015 lo pin owo ọhun.
Adajọ agba Mark Temple KC sọ pe ijọba Jersey ṣiṣẹ takuntakun ni ifọwọsowọpọ pẹlu ijọba Naijiria lati gba awọn dukia naa pada.
O ni “Ẹjọ yii lẹẹkan si n ṣafihan agbara ofin gbigbeṣẹle ti a gbe kalẹ lọdun 2018 eyii to faye gba wa lati gba awọn ohun ti awọn eeyan ji ko ki a si da wọn pada fun awọn to tọ si.
“Ni bayii, mo ti ṣetan lati jiroro pẹlu ijọba Naijiria lori ọna ti a maa gba lati da awọn dukia naa pada.














