Ẹ̀ẹ̀gàn mi ti dògo - Ooni Ile-Ife

Aworan Ooni of Ife

Oríṣun àwòrán, Others

Ooni ti ilu ile ife, Ọba Adeyeye Ogunwusi, ni gbogbo ẹẹgan oun lo ti dogo lẹyin ti oun koju awọn lasigbo kan lọdun to kọja.

Ooni sọ eleyi nigba to n kopa ninu akanṣe adura ti ẹgbẹ awọn ọmọ lẹyin Kristi (CAN) gbe kalẹ ni paapa Afewonro niluu Ile Ife.

Oba Ogunwusi lewaju awọn Kristẹni ninu kikọ orin ọpẹ ati iyin fun Jesu Kristi, to si ni ohun to dara ju ni ki gbogbo eeyan maa fi ọpẹ ransẹ di Oba oke.

“Ti n ba wo ẹyin mi, mo ṣe akiyesi pe aye mi kun fun ara ati iyanu Ọlọrun Ọba lẹyin gbogbo lasigbo ti mo doju kọ, sugbọn lonii, Ọlọrun gbe mi leke gbogbo awọn isoro naa.

“Lọdun to kọja, mo joko si ibi bayi pẹlu ẹdun ọkan to ba aye mi ja, eyi ti n ko le salaye sugbọn ọpẹ fun Ọlọrun, ẹẹgan mi ti dogo.

“Mo ṣe akiyesi pe lati igba ti mo ti bẹrẹ ni Ọlọrun ti wa pẹlu mi. O han gbangba pe Ọlọrun wa laye. Omugọ eeyan lo maa ni ko si Ọlọrun.

Jesu Kristi wa pẹlu mi lori itẹ Ọba- Ooni

Ooni Ogunwsi wa rọ awọn Kristẹni lati di opo Jesu Kristi mu nitori pe oun nikan ni ọmọ Ọlọrun ati pe oun lo wa pẹlu oun, to si ba oun gbe lori itẹ Ọba.

Ooni ni ko si ẹni to ba Ọlọrun sowo pọ to padanu ati pe ko ki n ṣe gbogbo nkan ni owo ni igbesi aye.

O ni bi oun ṣe bọ awọn eeyan ni ounjẹ ati awọn nnkan miiran, lo jẹ anfani lati ọdọ Ọlọrun Ọba.

Oba Ogunwusi ni oun ko ni dẹkun lati maa fi ọpẹ ransẹ si Ọlọrun Ọba fun anfani to fun oun, bẹẹni oun ko ni dẹkun awọn isẹ akanṣe ti oun ṣe niluu Ile Ife