Ìjọba fi ọ̀ǹtẹ̀ lu títa oògùn ìṣẹ́yún ní America

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba orilẹ-ede Amẹrika ti fayegba tita oogun iṣẹyun mifepristone ni awọn ilẹ itaoogun abele fun igba akọkọ lẹyin ti aarẹ Joe Biden ṣe ayipada ofin to dena rira oogun iṣẹyun ni Amẹrika.

Bo tile jẹ wi pe ofin titun naa kọ fayegba rira awọn oogun naa lai si ifọwọsi akọsẹmọsẹ oniṣegun.

Ofin titun yii ni yoo jẹ ki awọn obinrin orilẹ-ede Amẹrika ni ominira lati ra oogun iṣẹyun lai jẹ wi pe wọn de ile iwosan.

Ṣaaju ile ẹjọ kan lorileede Amẹrika ti wọgile igbejọ to fofinde oyun ṣiṣẹ ti awọn ipinlẹ kọọkan ni orilẹede Amẹrika naa gbẹsẹ le lilọ oogun iṣẹyun ni awọn ipinlẹ wọn.

Ile iwe Guttmacher Institute pro-choice ninu iwadii fihan pe ole diẹ ninu idaji awọn ọmọ orilẹede Amẹrika ni wọn ṣẹ oyun pẹlu lilọ oogun.

Igbesẹ naa ni awọn ajo to risi itọju alaboyun ati itọju ọmọde gbosuba fun.

Ṣugbọn ọsẹsẹ ki iṣelu orilẹede Amẹrika ṣakoba fun ofin titun yii nitori isejọba ipinlẹ kọkan yatọ.