Kevin McCarthy di olórí tuntun nílé aṣojúṣòfin Amẹ́ríkà

Aworan McCarthy, olori ile aṣojuṣofin ilẹ Amẹrika

Oríṣun àwòrán, screenshot

Aṣofin Kevin McCarthy ti di olori ile aṣojuṣofin orilẹede Amẹrika lẹyin pọlọpọ ifigagbaga to gbona girigiri eyi to fẹrẹ le ja si ẹṣẹ kikan laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican Party nile aṣofin naa.

Eto idibo marundinlogun ni wọn ṣe laarin awọn mọ ileegbimọ aṣojuṣofin naa ki Aṣofin McCarthy to wọle pẹlu bi o ṣe jẹ pe ẹgbẹ oṣelu rẹ lo pọ julọ nile aṣofin naa.

Olori ileegbimọ aṣojuṣofin lo wa nidi igbọnnu eto gbogb nile aṣojuṣofin, oun si ni o wa ni ipo kẹta si aarẹ orilẹede Amẹrika, eyi to tumọ si pe bi ko ba si aarẹ tabi igbakeji rẹ nile, ọwọ rẹ ni aṣẹ iṣakoso ijọba orilẹede Amẹrika.

Ninu ọrọ to kọ si oju opo Twitter rẹ lẹyin to wọle, aṣofin McCarthy sọ pe: “Mo lero pe ohun kan yoo han gedegbe lẹyin ọsẹ yii: N o ni kaarẹ rara. N ko ni kaarẹ rara nitori ẹyin eeyan ilẹ Amẹrika.”

Aarẹ Joe Biden ti ki aṣofin McCarthy ku oriire to si fi kun pe ireti oun ni lati jumọ ṣiṣẹ pọ pẹlu rẹ ati ẹgbẹ oṣelu Republican Party.

Aarẹ Biden ni: “Ireti awọn eeyan orilẹede Amẹrika ni pe awọn adari wọn yoo ṣeto ijọba lna ti yoo maa gbe ifẹ araalu leke ju ohunkohun lọ nigba gbogbo, asiko yii gan ni a nilo eyi.

Awọn ọmọ ẹgbẹ Republican party ti ṣeleri lati tanna iwadii si awọn okoowo ẹbi aarẹ Biden ati iṣejọba rẹ.

Bi awọn aṣofin ẹgbẹ oṣelu Republican party ṣe n ṣe ajọyọ lawọn akẹgbẹ wọn lẹgbẹ oṣelu Democratic party pa lọlọ ti ko si si eyikeyi ninu wọn to patẹwọ tabi dawọ idunnu nigba ti wọn kede McCarthy gẹgẹbi olubori.

Awọn aṣofin nibi ijoko ile lati yan olori wọn

Oríṣun àwòrán, screenshot

Ninu ọrọ akọkọ to sọ lẹyin to de ipo, Aṣofin McCarthy yannana ohun ilepa rẹ gẹgẹ bi adari ile, ninu eyi ti a ti ri mimu adinku ba owo ori ọja, didaabobo aala orilẹede Amẹrika pẹlu Mexico ati didẹkun ohun to pe ni “inawo apa ni Washigton”

Wakati mejila gbako lawọn aṣofin naa lo ki wọn to ri ọrọ yiyan olori ile naa yanju.

Igba akọkọ niyi ti ọrọ yiyan olori ileegbimọ aṣojuṣofin ni Amẹrika yoo maa la ọpọlọpọ idibo lọ lati yan lati ọdun 1860 lasiko imura fun ogun abẹle to waye to waye nibẹ. Igba mẹrinlelogoji ọtọọtọ ni wọn dibo lọdun naa lọhun ki wọn to rii yanju.

Ẹgbẹ oṣelu Republican party gba ijoko to pọ julọ nile aṣojuṣofin Amẹrika lasiko idibo aarin saa to waye loṣu kọkanla ọdun 2022. Ijoko igba ati mejilelogun 222 ni wọn ni ti ẹgbẹ oṣelu Democratic party si ni ijọko igba ati mejilelaadọfa, 212.