Wo ìdí tí ìjọba Canada fi òfin de àwọn àjèjì láti ra ilé níbẹ̀

Ile gbigbe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba orilẹ-ede Canada ti ṣe ofin kan ti yoo mu ko di eewọ fun awọn ti kii ṣe ọmọ orilẹ-ede naa lati rai le si.

Lọwọlọwọ, iye ti wọ̀n n ta ile kan ni Canada bẹrẹ lati C$777,200 ($568,000), eyi to ju owo to n wọle fun idile lọ lẹyin ti wọn ba yọ ow ori.

Bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kinni, ẹnikẹni ti kii ba ṣe ọmọ Canada, tabi to ni iwe igbelu lailai, ko nii le ra ile gbigber. Ẹni ti ọwọ ba tẹ pe o ru ofin yii, yoo san ẹgbẹrun mẹwaa Dọla Canada fun owo itanran.

Ṣugbọn ṣa, ofin tuntun yii yọ awọn eeyan kan silẹ.

Ninu atẹjade kan to fi sita ni ipari oṣu Kejila, ọdun 2022, ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ile gbigbe sọ pe awọn akẹkọọ lati ilẹ okeere, to ti lo ju dun marun-un ni Canada le ra ile.

Bakan naa ni fun awọn to jẹ ogunlende nibẹ, ati ẹni to ni iwe aṣẹ lati ṣiṣẹ fun igba diẹ ni Canada naa le ra ile.

Minisita fun ọrọ ile, Ahmed Hussen sọ pe ofin naa yoo fi opin si bi awọn eeyan kan ṣe n ra ile bi ẹni n ra nkan ipanu, dipo ibi ti awọn eeyan yoo ma a gbe pẹlu ẹbi wọn.

Ọgbẹni Hussen sọ pe pẹlu ofin yii bakan naa, awọn n gbe igbesẹ lati ri daju pe ipese ile wa fun anfaani gbogbo eeyan to n gbe ni Canada.

Lootọ ni owo ile dinku diẹ ni Canada, amọ o ṣi wọn ju iye to jẹ lọdun mẹwaa sẹyin.

Ida mẹtalelogoji ninu ọgọrun lo fi wọn si i ju ti ọdun 2013, nigba ti ile rira wa ni C$522,951.

Iye owo to n wọle fun awọn idile ni Canada mu ko nira lati rowo ra ile to n fi ojoojumọ wọn si.

Ni awọn ilu meji to tobi ju ni Canada, Toronto ati Vancouver, iye ti wọn n ta ile wọ miliọnu kan Dọla. Eyi mu ki wọn o fi orukọ wọn si ara ilu mẹwaa to wọ́n julọ fun igbeaye ẹda.

Orilẹ-ede New Zealand lo kọkọ ṣe iru ofin yii lọdun 2018, lati fi ofin de awọn to n ra ile sibẹ lati ilẹ okeere.

Igbesẹ naa waye lasiko ti orilẹ-ede naa koju ọwọn gogo cile, ti awọn eeyan ko si rowo rà.