Abẹnugan ilé aṣòfin Osun ní Oyetola yóò padà sípò gómínà kó tó di July 5, 2023

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun, Timothy Owoeye ní òun gbàgbọ́ pé gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ náà, Gboyega Oyetola yóò padà sípò gómìnà.
Níbi ìfilọ́lẹ̀ ìpolongo ìbò Tinubu/Shettima tó wáyé ní ìlú Osogbo, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà ni Owoeye ti ní òun ní ìgbàgbọ́ pé kó tó di ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Keje ọdún 2023 ni Oyetola ma ti padà sípò gómìnà.
Owoeye tó ṣe ìràntí pé ní ọjọ́ karùn-ún oṣù Keje ọdún 2019 ni ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé Oyetola ló jáwé olúborí nínú ìbò tó wáyé lọ́dún 2018.
“Ẹni tó bá mọ̀ wọ́n kó lọ sọ fún wọn pé kó tó di ọjọ́ karùn-ún oṣù Keje ọdún 2023, Oyetola máa padà gẹ́gẹ́ bí gómìnà.”
“Wọ́n rò wí pé àwọn máa le yí èsì ìbò lọ gbé àmọ́ a dúpẹ́ fún Ọlọ́run pé ìmọ̀ ẹ̀rọ BVAS ti tú gbogbo àṣírí wọn.”
Owoeye rọ àwọn ènìyàn láti ṣe àtìlẹyìn fún wọn níbi ètò ìdìbò ààrẹ tí yóò wáyé nínú oṣù Kejì ọdún 2023.
Abẹnugan ilé aṣòfin kò bọ̀wọ̀ fún ìjọba àwaarawa - PDP

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ti bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ tí Abenugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun sọ pé Oyetola yóò gba ipò lọ́wọ́ gómínà Adeleke.
Alága PDP ní Osun, Adekunle Akindele nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta láti fèsì sí Owoeye ní ọ̀rọ̀ tí Abẹnugan ilé aṣòfin náà sọ kò bá ètò ìjọba àwaarawa mu.
Adekunle ní Owoeye kò bọ̀wọ̀ ọ́fíìsì rẹ̀ ló ṣe le sọ irú ọ̀rọ̀ tó sọ náà ní ìtagbangba àti pé níṣe ló ń lẹ̀dí àpòpọ̀ láti da ìpínlẹ̀ náà rú.
Ó ní ó yẹ kí abẹnugan náà gbé ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ sílẹ̀ kó sọ òdodo fún Oyetola láti gbà pé àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun ti fi ìbò sọ̀rọ̀ pé àwọn ò ṣetán láti tẹ̀lé Oyetola mọ́.
Ó ní ó yẹ kí Owoeye tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun fún ọ̀rọ̀ tí ó sọ nítorí kìí ṣe ohun tí àwọn ará ìlú fẹ́ gbọ́ ló ń sọ.
Ọlọ́run ti fi hàn mí pé máa padà sípò gómìnà Osun - Oyetola

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹ ó rántí pé a ti mú ìròyìn wá pé Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Osun, Gboyega Oyetola ní ó dá òun lójú pé òun máa padà gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Osun láìpẹ́ ọjọ́.
Oyetola ní Ọlọ́run ti fi han òun pé òun máa jáwéw olúborí níbi ìgbẹ́jọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò tó ń lọ lọ́wọ́.
Ó ní òun máa gba ẹ̀tọ́ òun padà lọ́wọ́ gómìnà Adeleke àti ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP.
Oyetola ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC sọ̀rọ̀ ní ìlú Osogbo níbi àkànṣe ètò àdúrà kan tí wọ́n ṣe láti fi káàbọ̀ sí ìpínlẹ̀ Osun fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó kúrò lórí ipò.
Gómìnà àná náà ní nǹkan méjì tí Ọlọ́run fi han òun ni pé òun máa padà sípò gómínà Osun àti pé olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, Asiwaju Bola Tinubu náà máa gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò ọdún yìí.
Ó tẹ̀síwájú pé Ọlọ́run mọ̀-ọ́n-mọ̀ fún òun ní ìsinmi nítorí ọdún mẹ́rin ni òun fi sin àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Osun láì sinmi rárá.
Ó fi kun pé kò sí ẹnikẹ́ni tó le dẹ́rùba àwọn ní ìpínlẹ̀ Osun nítorí náà kí àwọn ènìyàn lọ fi ọkàn balẹ̀ nítorí dídùn ni ọsàn máa so fún àwọn nígbẹ̀yìn.















