Àwọn aláṣẹ CBN ṣàbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sáwọn mọ̀lẹ́bí tọkọtaya tí wọ́n dáná sun l'Abẹokuta

Tọkọtaya tí wọ́n dáná sun mọ́lé àti àwòrán ilé wọn

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn alakoso banki agba orilẹ-ede Naijiria, Central Bank of Nigeria (CBN) ṣabẹwo ibanikẹdun si awọn mọlẹbi tọkọtaya ti awọn amookunṣeka pa, ti wọn si tun dana sun niluu Abẹokuta loru aisun ọdun tuntun.

Tọkọtaya naa, Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye to jẹ ọga agba lẹka eto ipawowọle (Marketing Manager) ati Arabinrin Olubukola Fatinoye toun naa jẹ oṣiṣẹ fasiti eto ọgbin l'Abẹokuta, FUNAAB l'awọn kan ṣe ikọlu si ile wọn, ti wọn si tun lọ ju ọmọ wọn ati alabagbe wọn sodo.

Iroyin aburu naa l'awọn eeyan ṣi n sọ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, nitori pe kayeefi lo n jẹ.

BBC YORUBA rii gbọ pe nnkan bi aago mejila aabọ ọsan ni awọn alakoso banki agba naa de ile awọn oloogbe yii to wa lagbegbe GRA, Ibara niluu Abẹokuta.

Gbara ti wọn de ile naa, inu ọgba ile to wa niwaju ile awọn oloogbe yii ni wọn wọ lọ lati ṣe ipade papọ pẹlu awọn mọlẹbi.

Mọlẹbi Oloogbe Kẹhinde ati mọlẹbi Oloogbe Olubukola la gbọ pe awọn alakoso CBN ọhun ṣe ipade apapọ pẹlu, nibi ti wọn ti kọminu lori iṣẹlẹ naa, ti wọn si ṣeleri wi pe awọn yoo ṣe atilẹyin to ba yẹ fun wọn.

Àwọn òṣìṣẹ́ CBN lásìkò tí wọ́n ṣàbẹ̀wò sílé tọkọtaya tí wọ́n dáná sun ní Abeokuta
Àwọn ẹbí àtàwọn òṣìṣẹ́ CBN lásìkò tí wọ́n ṣe àbẹ̀wò sí ẹbí àwọn tọkọtaya tí wọ́n dáná sun ní Abeokuta

Nibi ipade ọhun ni Ọgbẹni Christopher Ṣomide ati Jinmi Bajẹla ti sọrọ lorukọ mọlẹbi mejeeji, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe iṣẹlẹ naa ba wọn lọkan jẹ pupọ.

Alakoso to lewaju igbimọ alakoso CBN naa, ẹni to kọ lati darukọ ara rẹ sọ pe wiwa ti awọn wa, ko ṣẹyin aṣẹ Gomina banki agba, Godwin Emefiele.

Alakoso ti awọn oṣiṣẹ banki agba ọhun lati Abuja, Eko ati Abẹokuta kọwọrin pẹlu rẹ fi ye ipade naa wi pe adanu nla ni iku Ọgbẹni Kẹhinde Fatinoye jẹ fun wọn

O ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii alabaṣiṣẹpọ to ni iwa irẹlẹ, to si fẹran alaafia, ati pe ko fẹran ki eeyan baa banujẹ nitosi rẹ, ti yoo si ṣe iranwọ to ba yẹ.

Siwaju sii lo sọ pe oun nigbagbọ wi pe gbogbo awọn to lọwọ si iku awọn oloogbe naa lọwọ maa tẹ laipẹ lati foju wọn winna ofin, ti idajọ ododo yoo si waye.

Ikú ẹ̀gbọ́n mi kò gbọdọ̀ lọ lófo– àbúrò tọkọtaya tí wọ́n dána sun ní Abeokuta pàrọwà síjọba

Wọ́n ti sọ ìdílé wa sí kolobo -Seun Fatinoye

Àwọn tọkọtaya tí wọ́n dáná sun àti àbúrò ọkọ, Seun Fatinoye

Oríṣun àwòrán, TVC

Bí ìwádìí ṣe ń tẹ̀síwájú láti ṣe àwárí àwọn afòkùnṣèkà tí wọ́n ń máa ń tafà sínú ìmọ́lẹ̀ tí wọ́n dáná sun tọkọtaya kan ní Ibara, Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun.

Lẹ́yìn tí àwọn oníṣẹ́ ibi náà dáná sun àwọn tọkọtaya náà ni wọ́n tún mú ọmọ bíbí wọn àti ọmọ ọ̀dọ̀ tí wọ́n lọ jù wọ́n sínú odò ògùn.

Ọjọ́ méjì lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n ṣàwàrí òkú ọmọ wọn nínú odò náà àmọ́ tí orí kó ọmọ ọ̀dọ̀ ilé wọn yọ tí òun ṣì wà láyé tó sì wà ní ilé ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú.

Nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn iléeṣẹ́ TVC sọ̀rọ̀, àbúrò Kehinde Fatinoye, Seun Fatinoye sọ wí pé gbogbo ìdílé olóògbé ni àwọn oníṣẹ́ láabi náà ti parun.

Seun Fatinoye nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní nínú oṣù Kẹfà ọdún tó kọjá ni ẹbí náà pàdánù ọmọ kan nínú àwọn ọmọ méjì tí wọ́n bí kó tó di pé àwọn oníṣẹ́ ibi náà tún wá pa gbogbo ẹbí tó kù báyìí.

Èmi ni ikú kò bá pà dípò ẹ̀gbọ́n mi nítorí tó bá wà láyé nǹkan kò ní ṣe ìdílé mi – Seun Fatinoye

Awọn tọkótaya tí wọ́n dáná sun

Oríṣun àwòrán, Family

Ó ní nǹkan ìbànújẹ́ ńlá ni ikú ẹ̀gbọ́n òun jẹ́ fún òun nítorí pé ohun tí ẹ̀gbọ́n òun máa ń dí fún òun pọ̀ púpọ̀.

Seun Fatinoye ní òun gan ni ikú kò bá múlọ nítorí òun ní ìgbàgbọ́ pé tí ẹ̀gbọ́n òun bá wà láyé ìyà kò le jẹ ẹbí tí òun bá fi kalẹ̀.

Ó wá rọ ìjọba àti àwọn ọlọ́pàá láti jọ̀wọ́ jàre ṣe iṣẹ́ wọn bí i iṣẹ́ láti lè fi ìdí òdodo múlẹ̀ lórí àwọn tí wọ́n wu ìwà láabi náà.

Ó fi kun pé wọ́n gbọ́dọ̀ wá àwọn tó ṣiṣẹ́ ibi náà, kí wọ́n fojú wọn winá òfin kí wọ́n sì lè fi ohun tó ṣokùnfà ìgbésẹ̀ wọn múlẹ̀.