Bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ lórí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ tí wọ́n fi kan dókítà Olaleye rèé

Dókítà Femi Olaleye

Oríṣun àwòrán, Others

Ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹrin oṣù Kìíní ọdún 2023 ní ìgbẹ́jọ́ dókítà Olufemi Olaleye tó ń kojú ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kan tún wáyé ní ilé ẹjọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko.

Dókítà Akinwunmi Oyadipe tó wá jẹ́rìí ní ilé ẹjọ́ ní àyẹ̀wò fi hàn pé àpá wà ní ojú ara ọmọ tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé dókítà Olaleye fipábálòpọ̀ náà.

Oyadipe ṣàlàyé pé nínú oṣù Kẹta ọdún 2022 ni Aderemi Olaleye mú ọmọ ọ̀hún wá sí ilé ìwòsàn Mirabel Centre níbi tí òun ti ń ṣiṣẹ́ fún àyẹ̀wò láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n fi ipá ba lòpọ̀ láti ọdún 2020.

Ó ní nígbà tí àwọn ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu fún ọmọ náà ló ṣàlàyé fún àwọn pé Dókítà Olaleye máa ń fipá bá òun lòpọ̀ tó sì máa ń fún òun ní ògùn láti lò lẹ́yìn ìbálòpọ̀ náà àti pé dókítà Olaleye tún máa ń dúnkokò mọ́ òun pé òun kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni.

Ó fi kun pé ìwádìí àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n fipá bá ọmọ náà lòpọ̀ ní tòótọ́.

Agbẹjọ́rò Dókítà Olaleye, Babatunde Ogala wá bèrè lọ́wọ́ dókítà Oyadipe pé ṣé ìwádìí fi hàn pé dókítà Olaleye ló fipá bá ọmọ náà lòpọ̀ àmọ́ Oyadipe ní òun kò lè fìdí ìyẹn múlẹ̀ nítorí òun kò sí níbẹ̀ nígbà tí wọ́n ń ṣe é.

Ogala tún bèrè pé ṣe ìwádìí wọn le ṣàfihàn ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ fipá bá ọmọ ọ̀hún lòpọ̀ èyí tí Oyadipe fun lésì pé ìmọ̀ ìṣègùn kò ì tíì débẹ̀ àmọ́ ìwádìí le ṣàfihàn rẹ̀ tí wọ́n bá ń fipá ènìyàn lòpọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.

Olùjẹ́rìí mìíràn tún jẹ́rìí tako dókítà Olaleye

Dókítà Olaleye àti òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n nígbà tí wọ́n ń kúrò ní ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Others

Ṣaájú kí dókítà Oyadipe tó bẹ̀rẹ̀ jíjẹ́ ẹ̀rí tirẹ̀ ni ọlọ́pàá kan tó wà lára àwọn tó ṣe ìwádìí ẹjọ́ náà ti kọ́kọ́ jẹ́rìí tako dókítà Olaleye.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọlọ́pàá Esther Ngozi Igbeneweka tẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ní oṣù Kẹta ọdún 2022 ni wọ́n kọ́kọ́ gbé ẹjọ́ náà wá sí àgọ́ ọlọ́pàá àwọn.

Igbeneweka ní lẹ́yìn náà ni àwọn gba ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọmọ ọ̀hún, ìyàwó dókítà Olaleye, Aderemi Olaleye tó gbé ẹjọ́ náà wá sí àgọ́ àwọn, àṣọ́nà ilé wọn àti dókítà Olaleye fúnra rẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé dókítà Olaleye jiyàn gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn fi kàn-án àmọ́ àwọn da dúró sí àgọ́ àwọn nígbà náà fún ìwádìí tó péye.

“Lẹ́yìn náà lá mú ọmọ náà lọ káàkiri fún ìwádìí kíkún, ìwádìí wa sì fihàn wí pé wọ́n fipá bá ọmọ náà lòpọ̀.”

Igbeneweka tún sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nígbà náà pé ọmọ ọ̀hún kò sọ ìṣẹ̀lẹ̀ náà fún ẹnikẹ́ni títí di ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta ọdún 2022.

“Àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ní Anthony ni a padà gbé ẹjọ́ náà lọ nígbà tí a ò parí ìwádìí wa nítorí Aderemi Olaleye tó wá fẹjọ́ sùn ṣe ìrìnàjò kúrò ní Nàìjíríà.”

Nígbà tí agbẹjọ́rò Dókítà Olaleye, Babatunde Ogala bèèrè lọ́wọ́ ọlọ́pàá náà pé ṣé ó rí fídíò ibi tí ìfinípábánilòpọ̀ náà ti wáyé, Igbeneweka ní fídíò wà àmọ́ òun kò wò ó.

Bákan náà ni Igbeneweka ní òun kò ṣe ìwádìí ọjọ́ orí ọmọ náà lẹ́yìn tí dókítà Olaleye ní ọjọ́ orí ọmọ ọ̀hún ti lé ní ọdún méjìdínlógún nígbà tó máa fi dé ilé àwọn dípò ọdún mẹ́ẹ̀dògùn tí Aderemi Olaleye ní ọmọ náà jẹ́.

Ogala tún bèèrè ìdí tí wọn kò fi tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìwádìí wọn tí ọlọ́pàá náà sì fun lésì pé nítorí Aderemi Olaleye kò sí ní Nàìjíríà nígbà náà ṣùgbọ́n àwọn máa ń sọ̀rọ̀ dada.

Lẹ́yìn gbogbo atótónu ni adájọ́ Ramon Oshodi wá sún ọjọ́ ìgbẹ́jọ́ mìíràn sí ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù kìíní ọdún 2023.