Ènìyàn márùn-ún pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ayẹyẹ ọdún tuntun ní Oyo

Oríṣun àwòrán, Others
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ènìyàn márùn-ún kan ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní ìjọba ìbílẹ̀ Afijio lọ́jọ́ ọdún tuntun.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá Oyo, Adewale Osifeso nínú àtẹ̀jáde kan ní lásìkò tí àwọn ẹgbẹ́ kan ń ṣe ayẹyẹ ọdún tuntun ní ìlú Akinmorin, ìjọba ìbílẹ̀ Afijio ni ìṣẹ̀lẹ̀ aburú náà wáyé.
Osifeso ṣàlàyé pé àwọn ẹgbẹ́ kan ló ń ayẹyẹ ọdún tuntun kí wàhálà tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín wọn nígbà tí ọ̀kan nínú wọn ṣàdédé wa mọ́tò ní ìwàkuwà wọ ibi ayẹyẹ náà.
Ó fi kun pé óṣojúmikòró tó wà níbi ayẹyẹ sọ wí pé ọkùnrin kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí wọ́n ń ṣayẹyẹ ni àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ báwí fún bí ó ṣe wa ọkọ̀ wọ inú ibi tí ayẹyẹ ọ̀hún ti ń wáyé.
Ó ní bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe bawí kò tẹ́ ẹni lọ́rùn tó sì fa awuyewuye láàárín wọn.
“Àwọn àgbàlagbà tó wà níbẹ̀ báwọn dási tí wọ́n sì báwọn parí ọ̀rọ̀ náà ṣùgbọ́n ọkùnrin tó wa ọkọ̀ náà kò dùn sí bí wọ́n ṣe bawí.”
“Ìdí nìyí tó fi wọ inú ọkọ̀ rẹ̀ padà tó sì ní òun máa ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ohun tí a rí ni pé ó fi ọkọ̀ rẹ̀ gba àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn míì tí iye wọn ń lọ bíi mẹ́wàá níbi tí wọ́n ti ń jọ lọ́wọ́.”
Ìròyìn nígbà tí ọkùnrin náà ṣe ìjàmbá yìí tan ló bọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ tó sì na pápá bora.
Àmọ́ ènìyàn mẹ́ta nínú àwọn ọ̀rẹ́ ọkùnrin náà tó wà nínú mọ́tò lásìkò tí ìjàmbá náà wáyé ti wà ní àgọ́ ọlọ́pàá.
Osifeso ní ìwádìí ṣì ń tẹ̀síwájú àti pé ní kété tí àwọn bá ti ní àfikún ìròyìn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni àwọn máa fi ìròyìn síta.















