Ìbànújẹ̀ ní ọdún tuntun, àwọn ènìyàn tẹ ara wọn pa!

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

O kere tan eniyan mẹsan lo ti ku lẹyin ti awọn oluworan tẹ ara wọn pa nigba ti wọn n ṣe ayẹyẹ ọdun tuntun ni ilu Kampala ni orilẹede Kampala.

Awọn ọmọde naa ni iroyin ni pe wọn ku ninu ikọlu naa ti o waye nigba ti ile itaja nla kan n safihan awọn ina alaranbara ‘’fireworks’’ lati ṣe ayẹyẹ ọdun

Oṣojumikoro kan to so iṣẹlẹ naa ni awọn eniyan to fi mọ ọrẹ oun lo ku nigba ti wọn ko le mi mọ nitori ọpọ ero to pọ ti wọn si n kọlu ara wọn.

Igba akọkọ ni yii ti wọn gba ki awọn eniyan korajọ lẹyin ajakalẹ aarun Covid-19

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn ni awọn eniyan to n kọlu ara wọn nitori wọn n rin ti wọn si kọju si ara wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iṣẹlẹ naa waye nitori awọn to lọ si ayẹyẹ kan n jade nigba ti awọn ti wọn fẹ wa wo ina alaranbara n wọle ni igba kan naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Kampala ni ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan ni wọn wa si ibi ayẹyẹ orin ni ile itaja Freedom City Mall.

Awọn ọmọde marun un ni wọn ku lẹyin ti wọn tẹ wọn pa lasiko iṣẹlẹ naa

Amọ ijọba ni awọn eniyan mẹsan ni wọn ku lapapọ to fi mọ awọn ti wọn gbe lọ si ileewosan.