Àwọn afurasí olóògùn owó pa ìyá ọlọ́mọ méjì, gé orí, ọkàn àtàwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ míràn lọ

Oríṣun àwòrán, OGUN/POLICE
Ní ọjọ́ kẹrin oṣù Kìíní ọdún 2023 ni tọkọtaya kan,Taiwo Olutufese Ajalorun àti Salawa Oyenusi Ajalorun ti kó sí gbaga ọlọ́pàá ní ìlú Ijebu-Ode.
Yàtọ̀ sí àwọn tọkọtaya yìí, àwọn mẹ́fà mìíràn ló tún ń káwọ́ pọ̀yìn rojọ́ ní àgọ́ ọlọ́pàá fẹ́sùn wí pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú arábìnrin kan, Oyindamola Adeyemi, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún.
Àwọn afurasí náà Lukman Oladele, Kayode Ibrahim, Bello Akeem, Alebiosu debayo, Fatai Rashhed àti Fatai Jimoh.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi léde lọ́jọ́ Karùn-ún, oṣù Kìíní, ọdún 2023 ní ọjọ́rú ọjọ́ Kẹrin oṣù Kìíní ọdún ni ọwọ́ tẹ àwọn afurasí náà.
Oyeyemi nínú àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2022 ni ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ojo Omolara lọ fẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Obalende, Ijebu-Ode wí pé alábàgbéé òun, Oyindamola Adeyemi jáde nílé tí àwọn kò sì rí ìpadàbọ̀ rẹ̀.
Ó ní Omolara ní àwọn ti ń pe fóònù Oyindamola títí àmọ́ tí nọ́mbà rẹ̀ kò lọ.
,
Agbẹnusọ ọlọ́pàá tẹ̀síwájú pé nígbà tí àwọn ọlọ́pàá àgọ́ Obalende ń bọ́ láti ibi ìwọ́de tí wọ́n ṣe lọ láti ṣàwárí ọmọbìnrin náà ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejìlá, ọdún 2022 ni wọ́n rí òkú kan ní ẹgbẹ́ títì èyí tí wọ́n ti yọ orí àti àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ mìíràn lọ.
Àwọ̀tẹ́lẹ̀ ni wọ́n fi dá òkú Oyindamola mọ̀ lẹ́yìn tí àwọn oníṣẹ́ ibi ti gé orí rẹ̀ lọ
Ó ní àwọn ọlọ́pàá gbé òkú náà lọ sí mọ́ṣúárì tí wọ́n sì pe Omolara àti àwọn ẹbi Oyindamola ti wọ́n ti ṣaájú wá sí ilé ẹjọ́ pé àwọn ń wá ọmọ àwọn láti wá òkú náà bóyá ó jọ ti ẹni tí wọ́n ń wá.
Ó fi kun pé àwọ̀tẹ́lẹ̀ ni Omolara fi da Oyindamola mọ̀ nítorí àwọn oníṣẹ́ ibi tó gbẹ̀mí lọ́rùn rẹ̀ ti gé orí àtàwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ mìíràn lọ.
“Nígbà tí Omolara ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Oyindamola ni ẹni náà ni DPO ọ̀gá ọlọ́pàá Obalende, Murphy Salami da àwọn ọlọ́pàá sígboro láti ṣàwárí àwọn tó ṣiṣẹ́ ibi náà lẹ́yẹ ò sọkà.”
“Ìwádìí àwọn ọlọ́pàá náà ni wan ti ṣàwárí Taiwo Olutufese Ajalorun tó jẹ́ babaláwo tí wọ́n bá fóònù itel tí olóògbé náà ń lò ní ọwọ́ rẹ̀.”
Oyeyemi ní ìgbà tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò ilé rẹ̀ ní wọ́n bá ike kan tó kún fún ẹ̀jẹ̀ olóògbé nínú ilé rẹ̀ bákan náà.
Ó fi kun pé lẹ́yìn tí àwọn fi póró òfin gbé Taiwo ló jẹ́wọ́ àwọn ti wọ́n jọ ṣiṣẹ́ ibi yìí tí àwọn sì nawọ́ gán Lukman Oladele tí wọ́n bá ẹsẹ̀ olóògbé náà ní ilé rẹ̀ àtàwọn mìíràn tí wọ́n jọ lọ́wọ́ níbẹ̀.
Lukman Oladele àti Taiwo tó jẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin Oyindamola ló fun lọ́rùn pa kí wọ́n tó gé ẹ̀yà ra rẹ̀ fún títà - ọlọ́pàá
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà fi kun pé nígbà tí àwọn ń ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún Taiwo àti Lukman ni wọ́n jẹ́wọ́ pé àwọn méjéèjì ni àwọn fún Oyindamola lọ́rùn pa nígbà tó wá ṣe àbẹ̀wò sí Taiwo tó jẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀.
Wọ́n ṣàlàyé pé lẹ́yìn tí àwọn pa Oyindamola tán ni àwọn gé orí, ọwọ́ rẹ̀ méjéèjì, ẹsẹ̀ àtàwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ mìíràn tí àwọn sì lọ tà á fún àwọn tó máa ń lò ó fún ògùn owó.
Wọ́n ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náírà (#30,000) ni àwọn ta ẹsẹ̀ méjéèjì tí àwọn sì ta ọkàn rẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà (#50,000) fún Akeem Bello.
“A ṣì ń wá ẹni tó ra orí olóògbẹ́ lọ́wọ́ wọn nítorí onítọ̀hún ti na pápá bora.”
“Àwọn afurasí náà jọ́wọ́ pé èèyàn kẹta tí àọn máa pa nìyí.”
Oyeyemi ní Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Ogun, Lanre Bankole ti darí pé kí àwọn gbé ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó rí sí ìwà ọ̀daràn fún ìwádìí tó péye.















