Àwọn òṣìṣẹ́ MAPOLY fẹ̀hónúhàn nítorí àìrí owó oṣù, owó ìfẹ̀yìntì àtàwọn àjẹmọ́nú míì gbà

Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonise Moshood Abiola tí ó wà ní ìlú Abẹ́òkúta, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ogun ti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ilé ẹ̀kọ́ gíga náà pá lọ́jọ́ru ọ̀sẹ̀ yìí.
Ìdí tí wọ́n fi gbé ìgbésẹ̀ náà bí ijọba àti àwọn adari ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe kùnà láti san owó oṣù mẹ́ta, owó ifẹyinti bí àádọ́ta oṣù àti gbígbegidina igbega lẹ́nu ìṣe wọn.
Ẹgbẹ́ àwọn àgbà òṣìṣẹ́ tí kìí ṣe olukọ, SSANU àti àwọn akẹgbẹ wọn, SAANIP bù ẹnu àtẹ́ lu ijọba ipinlẹ Ogun látàrí bí wọ́n ṣe ń kọ etí ọgbọin sì ìpè wọn láti bí oṣù mẹ́ta sẹyin.
Alaga ẹgbẹ́ SSANU ní ilé ẹ̀kọ́ gága MAPOLY, Kolawole Shopade ṣàlàyé pé, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ awọn ni wọ́n ti kú látàrí àìrí owó tọju ará wọn .
Nígbà tí ọ̀pọ̀ wa nínú idubulẹ àìsàn ọlọjọ pípẹ́ nítorí àìrí owó ifẹyinti àti àwọn owó ajẹmọnu mii gba láti bí ọdún mẹrin sẹ́yìn.
Alága ẹgbẹ́ SAANIP, Comrade Dada Olalekan ni tìrẹ, fi kun pé àwọn ò ní kọ láti tí ọgbà ilé ẹ̀kọ́ náà pá tí ìjọba ipinlẹ Ogun ti àwọn adari ilé ẹ̀kọ́ náà bá kọ láti fún awọn ní ẹtọ àwọn tí àwọn n beere.
Ìrètí wá pé, iwọde àti ifẹhonuhàn náà yóò tún béèrè padà ní ọjọ́ Ẹtì, ìyẹn tí kò bá sì àyípadà lórí ìbéèrè ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yìí.
A máa san owó oṣù kan nínú oṣù mẹ́ta ta jẹ wọ́n lónìí - MAPOLY
Alukoro ilé ẹ̀kọ́ náà, Ogbeni Yemi Ajibola ni ìrètí wá pé àwọn òṣìṣẹ́ náà yóò rí owó oṣù kàn gba lonii nínú oṣù mẹ́ta tí wọ́n jẹ wọ́n.
Ó ṣàlàyé pé, igbese tí ń lọ lọ́wọ́ láàárín àwọn adari ilé ẹ̀kọ́ náà àti ìjọba láti wá ìyànjú sì ìbéèrè àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonise Moshood Abiola.
Bawo ni ọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀?
Láti ọdún bí mẹta seyin ni ile ẹ̀kọ́ gbogbonise Moshood Abiola tí ń kojú ìṣòro àìrí owó oṣù san fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ látàrí bí àjò tí ó ń sedanwo JAMB ṣe gbé ìlànà tuntun kalẹ lórí ìlànà gbigba akẹ́kọ̀ọ́ wọlé sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga lorile-ede Nàìjíríà.
Èyí lo fà tí edinku ṣe bá iye ọmọ tí ilé ẹ̀kọ́ gbogbonise Moshood Abiola ń gba láti bí ọdún mẹta sẹ́yìn tí ó sì mú kí n kàn fa sẹ́yìn nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ náà nítorí owó tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń san ni wọ́n ń lo láti fi san owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́.
Idi nìyẹn tí àwọn adari ilé ẹ̀kọ́ yìí ṣe gbé igbese nínú oṣù karùn-ún ọdún tí ó kọjá láti fi kún owó ilé ìwé tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà ń san ṣùgbọ́n tí igbiyanju náà já sí pàbó.















