Ará ìlú yarí lórí àìrí owó náìrà tuntun gbà ní bánkì

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Lẹyin ipolongo nina owo naira tuntun ti ijọba apapọ pasẹ pe ki banki apapọ orilẹede yii gbe jade, ọpọ awọn araalu ni wọn kò tíì rí owo tuntun naa rara tabi ki wọn fi ọwọ kan an. Pupọ ninu awọn ọmọ orilẹede yii ni wọn ni awọn owo yii ko si ni inu ẹrọ ATM ati awọn baanki.

Bo ti jẹ wi pe laarin ọjọ mejidinlọgbọn sì akọkọ yii ni banki apapọ orilẹede yii yọ dá owo nina awọn ọwọ atijo naa duro.

Akọroyin BBC ṣabẹwo si awọn agbegbe kan ni ilu Abuja, nibi ti o ti beere lọwọ awọn araalu kan oye wọn nipa airi awọn owo tuntun ni agbegbe Unguwar Area 2,

Arakunrin kan ti a n pè ni Alhaji Haruna sọ pe “Lootọ ni mo rii lọwọ ọkunrin kan ni Kano ni ọsẹ to kọja.

Sùgbọ́n n kò dì í mú lọ́wọ́ mi, nítorí pé mo tilẹ̀ lọ sí báńkì láti yọ owó, ṣùgbọ́n n kò rí i.”

Akọroyin BBC naa tun lọ si Herbert Macaulay Street ni agbegbe Wuse, nibi ti o ti ṣabẹwo si ẹrọ ATM kan ni iwaju banki kan.

O ba awọn kan sọrọ ̀, wọn ́n sì sọ fun un pe ko si owo tuntun nínú bankì náà.

Bakan naa lo ri fun awon olugbe ilu Abuja , nigbati opo wọn fi aidunnu won han si ai rí owo naa.

Lọjọ kẹsan-an, oṣu kinni odun yii ni, ijọba orilẹede Naijiria yoo bẹrẹ si ni mu aṣẹ banki apapọ orilẹede yii se lati fi opin si iye owo ti awọn araalu le yọ kuro ninu akoto owo banki wọn, igbesẹ ti o fa ariyanjiyan kaakiri orilẹede yii..