Nítorí Obasanjo kò fẹ́ kí ọmọ Yorúbá òmíràn ga ju òun lọ ni kò fi ṣàtìlẹyìn fún Tinubu-YWG

Obasanjo ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ẹgbẹ́ The Yoruba Welfare Group, YWG ti fọ ara wọn mọ́ lórí ìbuwọ́lù tí ààrẹ àná Nàìjíríà, Olóyè Olusegun Obasanjo ṣe fún olùdíje sípò ààrẹ Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí ààrẹ ẹgbẹ́ YWG, Abdulhakkem Adegoke Alawuje buwọ́lù ní Obasanjo àti Pa Ayo Adebanjo ti sọ pàtàkì àti ipò wọn nú nínú Afenifere nítorí wọ́n kọ̀ lati tẹ̀lé ohun tí àpapọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá ń lọ.

Àtẹ̀jáde náà tí agbẹnusọ ẹgbẹ́, Alàgbà Yinka Salaam fi síta ní àwọn kò lọ́wọ́ nínú ìbuwọ́lù Peter Obi gẹ́gẹ́ tí Obasanjo àti Pa Adebanjo ṣe ti ṣe.

Wọ́n ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti dìbò àti láti ṣe àtìléyìn fún ẹni tó bá wù wọ́n àmọ́ ohun tó dájú ni pé kìí ṣe wí pé wọ́n ń gba ẹnu àwọn ọmó Yorùbá sọ̀rọ̀ rárá.

Alawuje fi kun pé ó ṣeni láàánú pé Obasanjo kò fẹ́ kí àwọn ọmọ Yorùbá mìíràn gbérí ní gbogbo bó ṣe máa ń kọ̀ láti ṣe àtìlẹyìn fún ọmọ Yorùbá mìíràn tó bá ń wá ipò.

Ó ní irú ìwà tí Obasanjo ń wù yìí ti wáyé rí láyé olóògbé Obafemi Awolowo lọ́dún 1979 sí 1983 àti nígbà tí olóògbé MKO Abiola náà ń wá ipò Ààrẹ lọ́dún 1993.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún fi kun pé níṣe ló yẹ kí Obasanjo fi ara rẹ̀ sípò àgbà tó wà kó sì máa wòye gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí orílẹ̀ èdè yìí mìíràn bí i Yakubu Gowon, Ibrahim Babangida, Mustapha AbdulSalami, Theophilus Danjuma àti Goodluck Jonathan ṣe máa ń ṣe.

Alawuje ní Obasanjo wà lára àwọn tó bá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà jẹ́ dé ibi tó dé lónìí tí kò sì fẹ́ kó ní àtúnṣe ló ṣe ń wá ọ̀nà láti fi ẹni tí wọ́n lè kàn máa fà ní tẹ̀tẹ́ sórí ipò.

Ó wá fi kun pé kí Obasanjo àti Adebanjo ṣàtìlẹyìn fún ẹnikẹ́ni tó bá wù wọ́n àmọ́ kí wọ́n yé tàbùkù ìran Yorùbá mọ́ pẹ̀lú ìwà wọn.