Ìgbéyàwó gbajúgbajà òṣèré tíátà, Yomi Gold tí forí sánpọ́n lẹ́yìn ọdún kan!

Oríṣun àwòrán, Others
Gbajugbaja oṣere tiata, Yomi Alore ti ọpọ mọ si Yomi Gold ti kede pe oun ati iyawo oun ti tuka lẹyin ọdun kan ti wọn ṣe igbeyawo.
Ninu atẹjade to fi si oju opo Instagram lati kede iyapa wọn lo ti fi orukọ iyawo rẹ Ameenah sita.
Yomi Gold ni awọn mejeeji lo pinu lati pin ya , ki onikaluku lọ ni ilọ tirẹ.
‘’Emi ati Meenah ti pinu lati pinya’’
‘’Mo fẹ ki awọn ara ati ọrẹ mo bi o ṣe n lọ ni mo ṣe sọrọ jade. Ko si akoko lati jẹ onidajọ ẹnikẹni , nitori ti ifẹ ba ti ku ko si ohun ti a le ṣe si’’
Lasiko to n dupọ lọwọ awọn ololufẹ wọn, lo salaye pe Ameenah yẹ ko fẹ ẹlomiran to dara ju oun lọ.
‘’Mo fi asiko yii dupẹ lọwọ awọn eniyan fun aduroti wọn.’’
‘’Eniyan to dara ni Meenah, to si yẹ ko fẹ ẹni to dara ju mi lọ.’’
‘’Ẹni ti yoo fẹran rẹ ju bi o ti fẹ lọ, iru eniyan bẹẹ ni o tọ si Meenah’’
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
‘’Mi o dara to, amọ maa gbiyanju lati jẹ ẹni rere ju bayii lọ.’’
‘’A nilo lati fi iroyin sita nitori awọn to mọ wa, ki wọn le mọ ohun ti a pinnu lati ṣe’’
‘’O dami loju pe asiko to dara yoo waye nigba diẹ si’’
Ti ẹ ko ba gbagbẹ igbeyawo Yomi Gold akọkọ pẹlu Victoria Ige fi ori sanpọn lẹyin ọmọ meji ni ọdun 2012.
Lẹyin naa ni Yomi Gold ṣe igbeyawo pẹlu Ameenah ni Oṣu Kini, ọdun 2022, ti wọn si bimọ ni oṣu kẹrin, ọdun naa, ki wọn to ṣeṣẹ wa kede ipinya wọn.












