Kò sí òtítọ́ nínú ìròyìn pé à gbé alága àjọ INEC lọ sí ilé ẹjọ́ – DSS

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede Naijiria, DSS ti ni ko si otitọ ninu iroyin pe awọn gbe alaga eto idibo lorilẹede Naijiria, Mahmood Yakubu lọ si ileẹjọ.
Ajọ DSS fidi eyi mulẹ ninu atẹjade gba ọwọ agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Peter Afunanya.
Ajọ ọhun ni iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin pe ileẹjọ lo da awọn duro lati maṣẹ fi panpẹ ofin mu alaga ajọ INEC naa.
‘’Ẹsun ti wọn fi kan Yakubu ni pe ko si otitọ ninu awọn ohun ini to kọ silẹ fun ijọba’’
Ninu atẹjade naa ni wọn ti ni awọn to n gbe iroyin ẹlẹjẹ naa fẹ da omi alaafia orilẹede Naijiria ru.
‘’Ohun ti wọn fẹ ṣe ni lati fẹ ki awọn eniyan rọ wi pe awọn kẹyin si ileeṣẹ eto idibo ni Naijiria.’’
‘’Amọ ko si ohun ti awọn ẹni ibi naa le ṣe nitori idibo yoo lọ ri irọwọrọṣẹ ni Naijiria’’
‘’Bakan naa ni a o ri pe ko si eru tabi magomago ni eto idibo gbogboogbo ti yoo waye ni Naijiria.’’
Ajọ DSS naa wa fi da awọn ọmọ Naijiria ati awọn ajọ lagbaye loju pe awọn yoo gbe igbeṣẹ lati ri pe ko si wahala lasiko idibo naa.
Wọn si rọ awọn eniyan lati fi ọwọ so ọwọ pọ lati jẹ ki alaafia ati iṣọkan jọba ni Naijiria.
Ti a ko ba gbagbe, laipẹ yii ni ileẹjọ giga wogile ẹsun pe Yakubu ko ṣe otitọ pẹlu awọn ohun ini to fi lede pe oun ni.
Bakan naa ni wọn fi ofin de ileeṣẹ agbofinro lati maṣe iwadii rẹ.
Mọ̀ nípa balógun ISWAP tí ọwọ́ DSS tẹ̀ fún ìkọlù sí ẹ̀wọ̀n Kuje àti àwọn mìí

Oríṣun àwòrán, Ijọba Naijiria
Ileeṣẹ alaabo ọtẹlẹmuyẹ DSS, sọ pe awọn ti mu ọgagun ikọ agbesunmọmi ISWAP, Abdulmumin Ibrahim Otaru, ti ọpọ mọ si Abu Mikdad, ati igbakeji rẹ, Saidu Suleiman, lọjọ kẹta, oṣu Kinni, ọdun 2023.
Gẹgẹ bi ikede ti DSS fi sita, Otaru ni oriṣiriṣi ibudo awọn agbesunmọmi yika ipinlẹ Kogi, to si ti ṣe agbatẹru awọn ijinigbe ni Kogi ati Ondo.
“Lasiko iwadii ni a fi idi rẹ mulẹ pe Ọgagun agba ni Otaru, ninu ikọ agbesunmọmi Islamic State West Africa Province (ISWAP), to si jẹ agbatẹru awọn ikọlu nla to n waye.
Diẹ lara awọn ikọlu ti DSS sọ pe Abu Mikdad lọwọ ninu rẹ
Diẹ lara awọn ikọlu ti DSS sọ pe Abu Mikdad lọwọ ninu rẹ
Gẹgẹ bi ohun ti DSS sọ, , Abdulmumin Ibrahim Otaru mọ nipa awọn ikọlu bii:
- Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, 2022 - Ikọlu to waye si olu ileeṣẹ ọlọpaa ni Eika-Ohizenyi, nijọba ibilẹ Okehi, nipinlẹ Kogi. Isipẹtọ ọlọpaa kan, Idris Musa kú, wọn si tun ji ibọn Ak-47 rifle meji lọ lasiko ikọlu naa.
- Ọjọ karun-un, oṣu Keje, 2022 – Ikọlu nla to waye si ọgba ẹwọn Kuje nili Abuja
- Ọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, 2022 – Ikọlu si ileeṣẹ West African Ceramics Ltd (WACL) ni ijọba ibilẹ Ajaokuta, nipinlẹ Kogi. Ọmọ orilẹ-ede India mẹta ni wọn ji gbe.
Wọn tun pa ọmọ India kan, ọlọpaa meji, ati awakọ ileeṣẹ naa meji. DSS sọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, 2022, ni awọn ti wọn ji gbe gba itusilẹ.
- Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2022 – Ajọ DSS sọ pe Abu Mikdad lo ṣe agbatẹru bi ado oloro ṣe dun nitosi aafin ọba Ohinoyi ti ilẹ Ebira, nilu Okene, nipinlẹ Kogi. eyi waye ni wakati diẹ ṣaaju ki Aarẹ Muhammadu Buhari lọ sibẹ lati ṣí awọn iṣẹ akanṣe.
Ko din ni eeyan mẹta to ku nibi ikọlu naa.
Ajọ DSS sọ pe awọn afurasi naa ti wa ni atimọle bayii, ti wọn o si gbe wọn lọ sile ẹjọ to ba ya.
Bakan naa ni wọn sọ pe awọn yoo ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ alaabo to kù, lati gbogunti iṣẹ awọn agbesunmọmi, ati awọn iwa ọdaran mii to n dunkooko mọ aabo ni Naijiria.














