Ẹ fi ọkàn balẹ̀, Covid-19 tó n ràn ní China, UK àti US kò tíì wọ Naijiria- NCDC

Ẹni to n se ayẹwo covid-19

Oríṣun àwòrán, ncdc

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun ni Naijiria, NCDC, ti fi awọn ọmọ Naijiria lọkan balẹ pe ko si ifoya lori ẹ̀dà Covid-19, Omicron, to tun n tàn kalẹ ni China, UK ati US.

Ajọ NCDC sọ pe aarun naa ko tii wọ Naijiria.

Ọjọru, ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2023, ni NCDC sọ ọrọ naa ninu atẹjade lori ibi ti nkan de lori itankalẹ Covid-19.

Ninu atẹjade naa, ẹda Omicron BF.7 lo n pọ si ni China, ti ẹ̀dà XBB.1.5 si gbilẹ ni UK ati US.

Oludari ajọ naa, Dokita Ifedayo Adetifa, sọ pe lati oṣu Keje, 2022, ni ẹda B.5.2.1 ti wa ni Naijiria, to si ṣeeṣe ki awọn yooku naa ti wọle laimọ.

“NCDC n sa gbogbo ipa rẹ lati mojuro Covid-19 ni Naijiria. Lati oṣu Kejila, ọdun 2021, ti Omicron ti wọn Naijiria, ni ẹda rẹ (BQ.1/BQ.1.1) naa ti gbalẹ.

“Ko si si eyikeyi ẹda yii to ni ohunkohun ṣe pẹlu bi aarun naa ṣe pọ si, tabi iye awọn to wa nileewosan tabi kú, ni Naijiria.”

Bakan naa lo sọ pe ẹda XBB.1.5 ati BF.7 lo n fa itankalẹ ọtun ni awọn orilẹ-ede kan, amọ ko tii wọ Naijiria.

Awọn igbesẹ wo ni ajọ NCDC n gbe lati dena itankalẹ ni Naijiria?

Ninu atẹjade ti oludari ajọ NCDC fi sita, ajọ naa sọ pe ibudo amojuto pajawiri ninu ajọ naa n tọpinpin bi aarun naa ṣe n rìn ni China, United Kingdom, United states, South Africa, India, ati awọn orilẹ-ede mii ti ọpọ eero ma n wa lati ibẹ si Naijiria.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ti ko gba abẹrẹ ajẹsara aarun naa lo n sọ di eero ileewosan tabi pa, to fi mọ awọn to ni aarun aṣekupani miran lara.

NCDC sọ pe igbesẹ pataki fun awọn ọmọ Naijiria lati gbe, ni pe ki wọn o gba abẹrẹ ajẹsara wọn, gẹgẹ ọna gboogi lati daabo bo ara wọn lọwọ Covid-19.

Bakan naa ni wọn ni bi nkan ba ṣe ri titi ipari ọsẹ yii, ni yoo sọ iru igbesẹ ti ijọba yoo gbe e , lara eyi ti ayẹwo awọn arinrinajo ni papakọ ofurufu yoo wa.