Wo ọmọdékùnrin tó jí bàbá rẹ̀ gbé, gba owó ìtúsílẹ̀ N2.5m lọ́wọ́ rẹ̀ kí wọ́n tó túu sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Kwara police
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara ni ọwọ awọn ti tẹ ọmọdekunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Issa Naigheti.
Oun lo ji baba rẹ gbe lati gba owo itusilẹ miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara SP Ajayi Ọkasanmi ṣalaye pe agbegbe Kambi nilu Ilọrin ni ọwọ ti ba afurasi naa.
O ni bi ọrọ ẹni to n wa owo lọ to pade iyi lọna lọrọ mimu ọmọde to ji baba rẹ gbe naa ṣe jẹ fawọn ọlọpaa nitori pe lasiko ti awọn ọlọpaa ikọ to n gbogun ti ijinigbe nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa n tọ pinpin awọn ajinigbe miran lọ ni wọn ṣe kongẹ ọmọdekunrin naa.
O ni akitiyan n lọ lọwọ lati rii pe wọn mu awọn alabaṣiṣẹ rẹ yooku.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara sọ pe afunrasi naa ti jẹwọ lasiko iwadii pe “lootọ loun atawọn meji kan gbimọ pọ lati ji baba oun, ti orukọ rẹ n jẹ Bature Naigboho gbe
lagbegbe Ighoho/Igbeti nipinlẹ yọ ti wọn si gba miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira ki wọn to fi silẹ.”
Ọgbẹni Ọkasanmi ni wọn yoo fi afurasi naa ṣọwọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ fun itẹsiwaju iwadii.












