Ọkọ àti ìyàwó rí òkú ọmọ wọn mẹ́ta tí wọ́n ń wá nínú ẹ̀rọ́ yìnyín 'freezer', ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Aworan Udochukwu Samuel Ejezie

Oríṣun àwòrán, Udochukwu Samuel Ejezie

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ibanujẹ dori agba kodo lọjọ kinni oṣu Keji ọdun yii nipinlẹ Anambra lẹyin ti iroyin iku awọn ọmọde mẹta ti wọn jẹ ọmọ kan naa jade niluu Nnenwi

Ọgbẹni Udochukwu Samuel Ejezie to jẹ baba awọn ọmọ naa sọ fun BBC Igbo pe iṣẹlẹ ọhun waye lẹyin ile iwosan fasiti ẹkọṣẹ iṣẹgun Nnamdi Azikwe niluu Nnenwi.

Ejezie ṣalaye pe iyawo oun fawọn ọmọ naa silẹ nile nigba toun lọ sile ẹkọ Our Lady of Lords ni Ihiala fun idanwo kan, amọ, ko ri ọkan kan ninu awọn ọmọ ọhun nile nigba to pada de.

''Awọn ọmọ yii maa n sare pade iyawo mi ni to ba ti pada de bẹyẹn, ṣugbọn ko ri awọn ọmọ naa ki i kaabọ nigba to de.

Bata wọn nikan lo ṣakiyesi wi pe o fọn kalẹ kaakiri,'' Ejezie ṣalaye.

Baba awọn ọmọ naa ṣalaye pe wọn mọ ọgba yi ile tawọn n gbe ka, ati pe awọn nikan ati mama ẹni to nile ọhun lawọn n gbe inu ile naa.

Amọ, o fidi rẹ mulẹ pe mama yii ko si nile lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.

Ọgbẹni Ejezie ni awọn alabagbe awọn mii tun ni awọn akẹkọọ imọ iṣegun, o ni awọn akẹkọọ yii ko le mọ nkankan nipa iku awọn ọmọ wọn.

Ejezie ni oun ko gbagbọ pe awọn eeyan kan lo awọn ọmọ oun fun ogun owo, bi ko ṣe pe wọn mọọmọ huwa ika yii lati fi da oun loju ni.

Chikazor Ogochukwu Ejezie to jẹ iyawo rẹ ni oun tiẹ kọkọ ro pe awọn ọmọ naa ti lọ ṣọọṣi ni nigba toun o ri wọn nile lẹyin toun pada de.

O ni bayii loun bẹrẹ si ni wa wọn to fi di ago mẹjọ alẹ ti oun si sọ fawọn ara adugbo pe ki wọn ran oun lọwọ lati wa wọn.

Chikazor ni ''mo beere lọwọ iyawo ọrẹ ọkọ mi tawọn ọmọ mi maa dijọ lọ ṣoọṣi pẹlu awọn ọmọ ti wọn naa, ṣugbọn o ni awọn ọmọ awọn ko lọ ṣọọṣi lọjọ naa.

Aladugbo wa lo sọ fun mi pe oun ri ọkunrin meji kan to wa si ile wa nigba ti mi o si nile.''

O ni awọn tẹsiwaju nipa wiwa awọn ọmọ yii titi ti awọn fi ri wọn ninu ẹrọ amu nkan tutu firiiji.

Bi wọn ṣe ri oku ọmọ mẹta ninu 'freezer'

Aworan Udochukwu Samuel Ejezie ati iyawo rẹ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni iroyin kan sọ pe awọn eeyan lo ṣeku pa awọn ọmọ mẹta naa, obinrin meji ati ọkunrin ọmọ ọdun marun un ti wọn si ko ara wọn sinu ẹrọ firiiji amu nkan tutu.

Iroyin naa sọ pe niluu Nnenwichi ni Nnenwi nipinlẹ Anambra ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Iroyin ọhun tun fi idi rẹ mulẹ pe mama awọn ọmọ yii to jẹ olukọ ati nọọsi lọ fun idanwo kan lọjọ ti iṣẹlẹ yii waye.

Nigba ti iya awọn ọmọ yii pada de ni o ri pe gbogbo ilẹkun ile awọn ti wa ni ṣiṣi silẹ, to ko si ri awọn ọmọ rẹ mọ.

Lẹyin ti wọn wa awọn ọmọ yii si gbogbo ibi ti wọn le wa wọn si lai ri wọn ni wọn wo inu firiiji ti wọn si ba oku wọn nibẹ.

Baba awọn ọmọ naa sọ pe awọn ti fọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti, awọn si ti gbe oku awọn ọmọ naa lọ si ile igbokusi.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Igbo, o si ṣalaye pe ọrọ naa ti de iwaju ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe iwadii iwa ọdara lati ṣe iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.

Ti ẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni wọn ri oku ọmọde mẹta ninu ọkọ kan niluu Nise nipinlẹ Anambra yii kan naa.