'Àìsàn jẹjẹrẹ gba ohùn àti ìgbéyàwó lọ́wọ́ mi'
- Author, Komla Adom
- Role, Journalist
- Reporting from, BBC News, Accra
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ṣíṣe àyẹ̀wò àìsàn jẹjẹrẹ máa ń mú àwọn ìròyìn nípa ìrora, àforítì, ìfẹ́ àti ìrètí dání. Bí àìsàn yìí ṣe ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn fínra, oníkálukú ló ní ìrìnàjò tirẹ̀ tí kò jọ ti ẹlòmíràn.
Àkòrí ìpolongo àìsàn jẹjẹrẹ ti ọdún yìí ni "United by Unique".
Àkòrí yìí ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìnira àti ìrora táwọn tó ní àìsàn jẹjẹrẹ àtàwọn tó ti la àìsàn náà kọjá máa ń kojú àmọ́ tí wọn kò lè bá ẹnì kankan sọ.
Ọ̀kan lára àwọn tó ń bá àìsàn yìí fínra ni Mary Amankwah Fordwor, agbẹ̀bí ní ilé ìwòsàn St Anthony Catholic Hospital ní orílẹ̀ èdè Ghana tó ní àìsàn jẹjẹrẹ ọ̀nà ọ̀fun.
"Mo ri pé ibìkan ń wú níbi ọrùn mi, kò dùn mí, bẹ́ẹ̀ ni kò lọ," Mary tó ti bí ọmọ méjì sọ fún BBC. Àwọn dókítà padà sọ fún pé àìsàn jẹjẹrẹ ló mú níbi tó wú náà tó ń lo ògùn sí.
Iṣẹ́ abẹ mẹ́rìnlá ni Mary padà ṣe lẹ́yìn ìgbà náà tó sì nílò láti yọ ẹ̀yà ara tó fi ń sọ̀rọ̀. Kódà, ìmọ̀ ẹ̀rọ "voice prosthesis" ló ń lò láti máa fi sọ̀rọ̀ báyìí.
Bẹ́ẹ̀ náà ni kò lè jẹun dáadáa mọ́ bíi ti ìgbà kan.
Kò pẹ́ púpọ̀ tó dé ipò ọ̀gá àgbà lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ ni wọ́n sọ fún un pé ó ní àìsàn yìí. Àìsàn yìí ṣàkóbá fún un ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà tí kò lérò tó fi mọ́ pípàdánù ìgbéyàwó rẹ̀ ọdún méjìlá.
Àjọ tó ń rí sí ètò ìlera àgbáyé, World Health Organization, WHO ní èèyàn mílíọ̀nù kan ó lé ọgọ́rùn-ún kan ló máa ń ní àìsàn jẹjẹrẹ nílẹ̀ Áfíríkà ní ọdọọdún àti pé èèyàn 700,000 ló máa ń ba lọ.
Ní àgbáyé, mílíọ̀nù mẹ́wàá èèyàn ni àìsàn jẹjẹrẹ ń pa ní ọdọọdún gẹ́gẹ́ bí àjọ náà ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, Mary Amankwah Fordwor
"Nígbà tí mò ń ṣe ìtọ́jú àìsàn jẹjẹrẹ mi pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé "chemo àti radiation" mo ri bí àwọn èèyàn ṣe ń kú, èyí ló mú mi ṣí ìkànnì WhatsApp kan láti máa ṣe kóríyá fáwọn tí a jọ ní àìsàn yìí pé ìrètí ṣì wà lẹ́yìn àìsàn jẹjẹrẹ."
Mary ń gbìyànjú láti lo ìkànnì TikTok, Instagram àti YouTube láti fi máa ṣe ìpolongo nípa àìsàn jẹjẹrẹ.
Tó bá ṣe àbẹ̀wò sáwọn ilé ẹ̀kọ́, ilé ìjọsìn àtàwọn àwùjọ mìíràn, ohun tó máa ń polongo ni gbígba àwọn tó ní àìsàn yìí mọ́ra.
"Mi ò mọ nǹkan tó ń jẹ́ kí èèyàn nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ tàbí ní ìgboyà nínú ara rẹ̀ títí tí mo fi ní àìsàn jẹjẹrẹ.
Àwọn dókítà kò lè sọ pàtó nǹkan tó fà àìsàn jẹjẹrẹ ọ̀nà ọ̀fun tí Mary ní àmọ́ WHO sọ pé ìdá àádọ́rùn-ún àwọn èèyàn, ara ló máa ń ṣe àkóso àìsàn jẹjẹrẹ àti pé ààrùn human papillomavirus (HPV) ló sábà máa ń fa àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara èyí tó níiṣe pẹ̀lú àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara obìnrin, ọkùnrin, ojú ìdí, ẹnu àti ọ̀nà ọ̀fun.
Ní ọdún 2019, HPV ṣokùnfà àìsàn jẹjẹrẹ 620,000 fáwọn obìnrin, tó sì fà àìsàn jẹjẹrẹ 70,000 fáwọn ọkùnrin káàkiri àgbáyé.
Ìjábọ̀ àjọ WHO lọ́dún 2022 ní orílẹ̀ èdè Ghana ṣàfihàn rẹ̀ pé àìsàn jẹjẹrẹ ọ̀fun ló wà ní ipò kẹtàdínlógún nínú àwọn àìsàn jẹjẹrẹ méjìlélọ́gbọ̀n tó gbajúmọ̀ ní orílẹ̀ èdè náà pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ṣàkọ́lẹ̀ àìsàn jẹjẹrẹ 227 ní ọdún náà nìkan.
Ní Áfíríkà, àìsàn jẹjẹrẹ ọ̀fun 10,665 ni wọ́n ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ lọ́dún 2022.
Dókítà Ama Boatemaa Prah ti ilé ìwòsàn Ghana Korlebu Teaching Hospital sọ pé àìsàn jẹjẹrẹ ọ̀fun ṣe é tọ́jú tí wọ́n bá tètè ṣàwárí rẹ̀.
Ó ní ara àwọn àmì àpẹẹrẹ rẹ̀ ni kí èèyàn máa húkọ́ fún ọjọ́ pípẹ́, kí ohùn èèyàn máa há fún ìgbà pípẹ́, kí èèyàn má lè gbé nǹkan mì láì sí ìrora.
"Àwọn àgbàlagbà ló máa ń ní àìsàn jẹjẹrẹ ọ̀fun tẹ́lẹ̀ àmọ́ a ti ń ri lára àwọn ènìyàn tí ọjọ́ orí wọn kò ì tíì pé ogójì ọdún báyìí."
Pẹ̀lú bí Mary ṣe ti bọ́ lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ ọ̀fun yìí, àwọn dókítà ní kò ì tíì bọ́ lọ́wọ́ pé kò ní àìsàn jẹjẹrẹ mọ́.
"Kìí ṣe ohùn mi nìkan ni àìsàn jẹjẹrẹ ọ̀fun mú lọ, ó gba ìgbéyàwó ọdún méjìlá lọ́wọ́ mi."
Èyí jẹ́ kí òun náà wà lára àwọn obìnrin tí ọkọ wọn máa ń kọ̀ sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ní àìsàn jẹjẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Michigan ṣe lọ́dún 2014.
Ìwádìí náà ní ìdá mọ́kànlélọ́gbọ̀n àwọn obìnrin lọ máa ń pàdánù ìgbéyàwó nígbà tí wọ́n bá ní ìpèníjà ìlera.
Ìwádìí mìíràn tí àjọ Fred Hutchinson Cancer Research ṣe lọ́dún 2009 sọ pé ìdá obìnrin 20.8 ló máa pàdánù ìgbéyàwó nígbà tí wọ́n bá ní àìsàn jẹjẹrẹ, tó sì jẹ́ pé ìdá 2.9 ló máa ń pàdánù ìgbéyàwó wọn.
Àwọn onímọ̀ ní Ghana sọ pé níṣe ni ìpèníjà náà ń peléke si bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àkọ́ọ́lẹ̀ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀.
Mary ní òun kìí gbàgbé láti máa rán ara òun létí pé nǹkan tó dára ní òun ṣe nípa mímú ẹ̀mí òun ṣáájú ìgbéyàwó. Ó ní àwọn òbí òun àtàwọn ọmọ òun méjèèjì wà níbẹ̀ fún òun bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan tí òun ń lá kọjá kò tètè yé wọn níbẹ̀rẹ̀.
"Ìyá mi sọ fún wa pé òun ní àìsàn jẹjẹrẹ, tí a lọ ṣe àyẹ̀wò si ní ilé ìwòsàn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ kan, ẹ̀rù bà mí pé ṣé kò ní jáde láyé àmọ́ inú mi dùn pé ó wà láyé pẹ̀lú wa," Emmanuella, ọmọ Mary sọ.
Dókítà Prah júwe Mary gẹ́gẹ́ bí ohun ìwúrí fáwọn akẹgbẹ́ rẹ̀. "Akíkanjú obìnrin tó máa ń fi ìdùnnú hàn ní gbogbo igba ni. Mo fẹ́ káwọn yòókù mú ìrírí rẹ̀, kí wọ́n sì ní ìrètí pé àwọn máa borí àìsàn jẹjẹrẹ wọn.













