Ìjọba Nàìjíríà yí ohùn padà, wọ́n ní irọ́ ni pé àwọn fẹ́ fowó kún owó iná mọ̀nàmọ̀nà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ni irọ to jina si otitọ ni iroyin to n lọ kiri pe ijọba fẹ fi owo kun owo ina mọnamọna.
Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti oludamọran fun Aarẹ Bola Tinubu lori eto agbara, Olu Arowolo Verheijen fi lede fun awọn akọroyin.
O ni ọpọ awọn eeyan lo si ọrọ oun gbọ, ti wọn si n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri pe ijọba fẹ fi ida marundinladọrun kun owo ina mọnamọna.
O ni lẹyin afikun to waye fun awọn to wa ni iṣori A (Band A) ni ọdun 2024, owo ti ijọba ti pa wọle lati ibi owo ina ti san owo toto ida marundinlaadọrun owo ti wọn nilo lati mu ina wọle, ti ijọba si n san iyoku.
Olu Verheijen wa fi da awọn araalu pe ijọba yoo saa gbogbo agbara lati mu afikun ba ina mọnamọna ni ọjọ ọla.
Ni ọdun 2024, ijọba Naijiria yọ owo iranwọ kuro lori owo ina mọnamọna, eyi to fa afikun si owo ina fun awọn eeyan to wa ni iṣori A (Band A) kaakiri orilẹede Naijiria.
Afikun yii ọpọ koroju si, ti wọn si bu ẹnu atẹlu ijọba.
Ìdí tí owó iná mọ̀nàmọ́ná tí aráàlù ń san ní Nàìjíríà yóò fi lọ sókè láìpẹ́ rèé - Ìjọba

Oríṣun àwòrán, PA Media
Ijọba apapọ ti sọ fawọn ọmọ Naijiria lati gbaradi fun afikun owo ina mọnamọna mii eyi ti yoo waye laipẹ.
Oludamọran Aarẹ Bola Tinubu lori nnkan amuṣagbara, Olu Verheijen, lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu awọn akọroyin niluu Da es Salaam lorilẹede Tanzania.
Verheijen wa nibi apero kan ti banki agbaye ṣe atilẹyin fun lorilẹede Tanzania nibi ti Naijiria ti sọ erongba rẹ lori ati na $32bn lati jẹ ki ina mọnamọna duro deedee titi ọdun 2030.
Ijọba n gbero wi pe awọn olokowo aladani ni yoo gbe $15.5bn kalẹ, nigba ti ijọba yoo wa iyooku pẹlu iranwọ banki agbaye ati banki idagbasoke fun ilẹ Afirika, ADB.
Oludamọran aarẹ lori ohun amuṣagbara sọ pe ijọba ni lati ṣafikun owo ina pẹlu ida meji ninu ida mẹta ki araalu to le maa sanwo to wa ni ibamu pẹlu owo ti ijọba n lo lati pese ina.
Verheijen ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ijọba yoo tun fi owo iranwọ sori owo ina lẹyin to ba ṣe afikun owo tariifu tan ki o le rọrun fawọn mẹkunnu.
O ni afikun owo tariifuu yii ni ijọba fẹ lo lati ṣawọn atunṣe irinṣẹ ina mọnamọna ki o le jẹ nnkan koriya fawọn olokowo aladani lati le dokowo si ileeṣẹ amunawa ati apinaka.
Igbesẹ afikun owo tariifu ina wa lati ọdọ awọn ileeṣẹ apinaka ti wọn ti jẹ gbese silẹ
''Ọkan lara awọn ipenija ti a fẹ wa ojutuu si laipẹ ni jijẹ kawọn araalu maa sanwo ina to wa ni ibamu pẹlu owo ti ijọba fi n pese ina mọnamọna.
Eleyii ṣe pataki ki ijọba le pa owo gidi wọle ti yoo jẹ koriya fawọn olokowo adani ati lati jẹ ko rọrun fawọn ti ko rọwọ họri,'' Verheijen lo sọ bẹẹ.
Verheijen ni igbesẹ lati ṣe afikun owo tariifu ina wa lati ọdọ awọn ileeṣẹ apinaka ti wọn ti jẹ gbese silẹ.
Lọdun 2013 ni ijọba sọ ileeṣẹ mọnamọna Naijiria di ti aladani, amọ, iye ti ajọ NERC to n ri si ọrọ ina mọnamọna ko to lati lo fun awọn ileeṣẹ amunawa lati pese ina fun araalu.
Owo iranwọ ti ijọba n da sori ina ni wọn tun fi n gbera, amọ, o nira lati jere gọbọi fawọn ileeṣẹ apese ina ọba.
Verheijen sọ pe orilẹede Naijiria nilo idokowo gidi lẹka ina mọnamọna fun idagbasoke.
O ṣalaye pe ninu ina 14 'gigawatts'' ti Naijiria n pese, mẹjọ pere ninu rẹ lawọn ileeṣẹ apinaka le pin kaakiri Naijiria, nigba ti marun pere ninu rẹ lo le wọ ile awọn eeyan ati awọn okowo.















