Èèyàn 28 jóná kọjá àlà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ l'Ondo

Aworan iṣẹlẹ ijamba ọkọ to waye nipinlẹ Ondo

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ to n ri si oju opopona lorilẹede Naijiria ti kede pe o din diẹ ọgbọn eeyan to padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ ijamba ọkọ to waye ni oju ọna marose Benin- Ore- Ijebu Ode ni agbegbe Onipetesi.

Iṣẹlẹ naa waye ni ijọba ibilẹ Odigbo ni irọlẹ ọjọ Satide ọjọ kinni oṣe keji ọdun 2025.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Ọga agba fun FRSC nipinlẹ Ondo, Samuel Ibitoye ni iwadii fihan pe ọkan ninu ọkọ to ṣagbako ijamba ọkọ rinna tako ofin oju ọna.

"Ọgbọn eeyan lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba yii. Eeyan mejidinlọgbọn jọna kọja ala, ti ori si ko awọn meji yọ ṣugbọn wọn padanu gbẹmi mi lasiko ti wọn n gbe wọn lọ ile iwosan."

Ọṣujumikoro to ba ileeṣẹ iroyin abẹle The Punch sọrọ ni bi awọn ọkọ mejeeji ṣe kọlu ara wọn ni wọn gba ina lẹsẹkẹsẹ.

"A wa ni itọsi nigba ti a ṣadede gbọ ariwo. Nigba ti a de si ibẹ, ni a ri ọkọ meji ti wọn kọlu ara wọn, ti wọn si n jọna nigba ti awọn eeyan to wa ninu wọn tiraka lati sa jade.

"Ko pẹ ni awọn ajọ FRSC de sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn suure gbe awọn meji ti ori ko yọ lọ si ile iwosan. Ẹwẹ a gbọ pe awọn meji naa padanu ki wọn to de ile iwosan."