Kí ló ń fa ìfànfà láàárín Gómìnà Adeleke àti Ọba ìlú Iragbiji lórí oyè Aragbiji?

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/AbdurRasheed Olabomi
Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun lábẹ́ ìdarí Gómìnà Ademola Adeleke ti fèsì sáwọn ẹ̀sùn tí Aragbiji ti ìlú Iragbiji, Oba AbdurRasheed Olabomi fi kàn án lórí jíjẹ oyè Aragbiji.
Láìpẹ́ yìí ni ìjọba ìpínlẹ̀ Osun buwọ́lu àṣẹ kan pé ìdílé Lagbua náà lè máa jẹ ọba Aragbiji ti ìlú Iragbiji.
Àṣẹ náà ní ìdílé Lagbua ló máa jẹ́ ìdílé karùn-ún, tí yóò sì máa jẹ ọba kẹ́yìn lásìkò tí ìyànsípò ọba yóò bá wáyé.
Àṣẹ àti ìkéde ìjọba yìí kò tẹ́ Ọba Olabomi lọ́rùn rárá, bó ṣe ní ìjọba ìpínlẹ̀ náà fẹ́ gba ọ̀nà ẹ̀bùrú láti gbé ìdílé mìíràn wọnú ìlànà oyè ọba jíjẹ ìlú náà.
Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní, ọdún 2025, Oba Olabomi rọ gómìnà Adeleke láti tún ìpinnu rẹ̀ gbé yẹ̀wò àti pé ìgbésẹ̀ rẹ̀ le dá wàhálà kalẹ̀ ní ìlú.
Ọba Olabomi ní òun gbàgbọ́ pé ìgbésẹ̀ fífi ìdílé Lagbua sára ìdílé tó lè máa jẹ oyè Aragbiji ní ọwọ́ kan òṣèlú nínú.
Ó ní kìí ṣe pé ìṣèjọba Gómìnà Adeleke ti gbé ìgbìmọ̀ kankan dìde láti ìgbà tó ti wà lórí ipò láti ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ oyè náà.
Ó wòye pé ìgbésẹ̀ yìí le da omi àláfíà ìlú Iragbiji tó ti wà ní pẹ̀lẹ́ kùtù láti bíi ọgọ́ta ọdún rú ni.
Ọba náà tẹmpẹlẹmọ pé ìdílé oyè mẹ́rin ló ń jọba ní ìlú Iragbiji àti pé ìdílé tí Gómìnà Adeleke ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lu náà kò sí lára wọn rárá.
Ọba Olabomi rọ ìjọba láti ṣe ìdádúrò ìgbésẹ̀ náà lójúnà àti lè ri pé àláfíà tó ti ń jọba ní ìlú Iragbiji ń tẹ̀síwájú.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fèsì
Ẹ̀wẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ti wà fún Ọba Olabomi lésì pé níṣe ló fẹ́ da ọwọ́ bo òótọ́ nípa oyè Aragbiji jíjẹ àti pé ó fẹ́ sọ ọ̀rọ̀ náà di ọ̀rọ̀ òṣèlú ni.
Ìjọba Osun nínú àtẹ̀jáde kan tí Kọmíṣánnà fọ́rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ àti òye jíjẹ, Amofin Dosu Babatunde fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kìíní, oṣù Kejì, ọdún 2025 sọ pé Gómìnà Adeleke kò fi ọ̀rọ̀ oyè náà ṣe òṣèlú rárá gẹ́gẹ́ bí Aragbiji ṣe fẹ̀sùn kàn.
Babatunde sọ nínú àtẹ̀jáde náà pé gómìnà Adeleke ní àṣẹ láti dá sí ọ̀rọ̀ ìlú tó fi mọ́ pípè fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá ti kọjá lójúnà àti fìdí òótọ́ àti òdodo múlẹ̀.
Ó ṣàlàyé ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìpínlẹ̀ Osun ṣe àyípadà sí ìgbésẹ̀ tí ìjọba kan ti gbé tẹ́lẹ̀ ni lórí bí wọn kò ṣe fàyè gba ìdílé Lagbua lẹ́tọ̀ọ́ láti máa jẹ oyè Aragbiji.
Ó sọ pé lábẹ́ ìṣèjọba Ọmọọba Olagunsoye Oyinlola ni wọ́n ti gbé ìgbìmọ̀ olùwádìí kan dìde lọ́dún 2010 láti ṣèwádìí ọ̀rọ̀ oyè Aragbiji àti ìdílé Lagbua tó ń bèèrè fún fífi àwọn sínú ọmọ oyè tó lè jẹ Aragbiji.
Kọmíṣánnà náà ṣàlàyé pé Adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun tó wà ní ìlú Osogbo ló dárí ìgbìmọ̀ náà lásìkò ọ̀hún àti pé gbogbo àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lórí oyè Aragbiji ló jẹ́rìí ìgbìmọ̀ náà.
Ó ní oṣù Keje ọdún 2010 ni ìgbìmọ̀ náà gbé àbọ̀ ìwádìí rẹ̀ fún ìjọba àmọ́ ìjọba kò gbé ìjábọ̀ náà yẹ̀wò títí tí ìṣèjọba rẹ̀ fi parí.
Ó fi kun pé ọdún 2013 ni ìjọba lábẹ́ ìdarí Gómìnà Rauf Aregbesola tó ṣe àgbéyẹ̀wò ìjábọ̀ ìgbìmọ̀ ọ̀hún, tí wọ́n sì da àbọ̀ ìwádìí náà nù pé ọ̀rọ̀ tó ti pẹ́ ni ẹbí náà ń hú síta.
Babatunde ní ẹbí Lagbua kò kó àárẹ̀ ọkàn lórí ìpinnu ìjọba yìí, tí wọ́n sì kọ̀wé ránṣẹ́ sí ìjọba lẹ́yìn tí Gómìnà Adeleke gbàkóso ìjọba Osun láti tún bá àwọn ṣe àgbéyẹ̀wò ìjábọ̀ ìgbìmọ̀ ọdún 2010 náà.
Ó ní èyí ló mú kí ìjọba gbé ìgbìmọ̀ dìde láti ṣàyẹ̀wò ìjábọ̀ ìwádìí ìgbìmọ̀ náà kí wọ́n sì ṣe àtúnṣe to bá yẹ.
Ó fi kun ìgbìmọ̀ náà rí pé ìjábọ̀ ọ̀hún sọ pé ìdílé Lagbua yẹ lọ́mọ oyè nítorí orúkọ wọn wà nínú ìwé oyè Aragbiji jíjẹ ti ọdún 1951 àti 1956 àmọ́ tí kò sí orúkọ wọn nínú ìwé oyè jíjẹ ti ọdún 1958.
Ó sọ pé àwọn ẹ̀rí yìí ló mú kí gómìnà kéde pé kí wọ́n fi orúkọ ìdílé Lagbua sínú àwọn ìdílé tí yóò máa jẹ oyè Aragbiji láti ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní, ọdún 2025.
Ìjọba ní àwọn kò kórira àwọn èèyàn ìlú Iragbiji tàbí da omi àláfíà ìlú náà rú gẹ́gẹ́ bí Ọba Olabomi ṣe fẹ̀sùn kàn bíkòṣe láti ri pé àwọn tí oyè tọ́ sí náà gbà ẹ̀tọ́ wọn.















