Ọkọ̀ òfurufú tó gbé ọmọ tó ń ṣàárẹ̀, ìyá rẹ̀, àtàwọn míì já lulẹ̀ ní US
- Author, Max Matza, Madeline Halpert & Christal Hayes
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Ọkọ̀ òfurufú ètò ìlera kan tó gbé ọmọdé tó ń ṣe àárẹ̀, ìyá rẹ̀, àtàwọn òṣìṣẹ́ mẹ́fà mìíràn já lulẹ̀ ní ìlà oòrùn àríwá orílẹ̀ èdè Philadelphia.
Ọ̀pọ̀ ilé àti ọkọ̀ ni ìjákulẹ̀ ọkọ̀ òfurufú náà ṣàkóbá fún báwọn ilé àti ọkọ̀ náà ṣe gbiná nígbà tó já lé wọn lórí.
Ọkọ̀ òfurufú náà ló ń gbé ọmọ tó ń ṣe àárẹ̀, ìyá rẹ̀ àtàwọn òṣìṣẹ́ ìrìnnà òfurufú náà ló wà nínú rẹ̀ lásìkò tí ìjákulẹ̀ náà wáyé.
Gomina Pennsylvania, Josh Shapiro nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní àwọn mọ̀ wí pé àwọn kan yóò bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá náà lọ.
Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè ní Amẹ́ríkà sọ lórí ìkànnì X pé ọmọ orílẹ̀ èdè Mexico ni àwọn mẹ́fà tó wà nínú ọkọ̀ òfurufú náà.
A kò tíì lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá ẹnikẹ́ni móríbọ́ lọ́wọ́ ikú nínú àwọn mẹ́fà tó wà nínú ọkọ̀ òfurufú náà.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn US fi léde, agbenusọ ilé ìwòsàn Temple University Hospital-Jeanes ní Philadelphia ṣàlàyé pé èèyàn mẹ́fà tí ọkọ̀ òfurufú náà ṣèkọlù sí nílẹ̀ ni àwọn ti ṣe ìtọ́jú wọn.
Mẹ́ta nínú àwọn mẹ́fà náà ló ti gba ìtọ́jú tí wọ́n sì dá wọn sílẹ̀ nílé ìwòsàn àmọ́ tí a kò mọ bí ìlera àwọn mẹ́ta ṣe rí.

Oríṣun àwòrán, Pennsylvania Representative Jared Solomon
Ọmọdé tó wà nínú ọkọ̀ náà ló ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn kan ní US fún àìsàn gbẹ̀mí gbẹ̀mí kan tó ń yọ ọ́ lẹ́nu, tí wọ́n sì ń padà sí Tijuana, Mexico kí ìjàm̀bá náà to wáyé.
Agbenusọ ìgbìmọ̀ tó ń dóòlà ẹ̀mí nínú ọkọ̀ òfurufú, Shai Gold sọ pé ìyá ọmọ náà, awakọ̀ òfurufú méjì, Dókítà kan àti òṣìṣẹ́ ètò ìlera kan ló wà nínú ọkọ̀ náà lásìkò tí ìjàm̀bá náà wáyé.
Aṣojú Mexico ní Philadelphia fi ìkéde síta lórí ìkànnì X rẹ̀ pé kí ọmọ orílẹ̀ èdè Mexico tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá ṣe àkóbá fún kàn sí àwọn lórí àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tí wọ́n fi léde.
Agbègbè tí kò jìnà sí ilé ìtajà Roosevelt Mall ni ìjàm̀bá náà ti wáyé. Ilé ìtajà náà máa ń ní èrò tó pọ̀, tí ọ̀pọ̀ ilé àti ṣọ́ọ̀bù sì kún agbègbè náà.
Fídíò kan tó gba orí ayélujára ṣàfihàn bí ọkọ̀ òfurufú náà ṣe ń já wálẹ̀, tó sì gbiná ńlá.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ pé níṣe ni àjálù àwọn ọkọ̀ tó ń gbiná gba gbogbo ojú títì, tí iná ńlá sì sọ ní ojú ọ̀run.
Ọkùnrin kan tó bá iléeṣẹ́ ìròyìn CBS sọ̀rọ̀ sọ pé òun ń wá ọkọ̀ kọjá ní agbègbè náà ni òun ṣàdédé gbọ́ ìró ìbúgbàmù, tí gbogbo èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Kí la mọ̀ nípa ọkọ̀ òfurufú tó já náà?
Ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ ọjọ́ Ẹtì ni ọkọ̀ òfurufú, Learjet 55 já lulẹ̀ lẹ́yìn tó kúrò ní pápákọ̀ òfurufú Northeast Philadelphia Airport.
Kò rìn ju máìlì mẹ́rin lọ láti pápákọ̀ òfurufú tó ti kúrò tó fi já lulẹ̀.
Àjọ tó ń rí sí ìrìnnà òfurufú Amẹ́ríkà, FAA sọ pé pápákọ̀ òfurufú Springfield-Branson National Airport ní Missouri ni ọkọ̀ náà ń lọ.
Gẹ́gẹ́ bí FlightAware, iléeṣẹ́ tó máa ń tọpinpin ọkọ̀ òfurufú ṣe sọ, iléeṣẹ́ kan tó ń jẹ́ Med Jets ló ń ṣàmójútó ọkọ̀ náà.
FAA àti àjọ tó ń mójútó ààbò ètò ìrìnnà ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ohun tó fa ìjàm̀bá náà.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ méjì tí ọkọ̀ òfurufú méjì forí sọra ní Washington DC níbi tí èèyàn mẹ́tàdínláàdọ́rin (67) ti pàdánù ẹ̀mí wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Were you in the area? Did you witness the incident? If it is safe to do so, please get in touch,













