Wo ipa tí àdínkù owó epo bẹntiróòlù tí Dangote ṣẹ̀ṣẹ̀ kéde yóò ní lórí aráàlú

Aworan ile epo ati Aliko Dangote

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

O ṣeeṣe ki owo epo bẹnitiroolu walẹ kaakiri orilẹede Naijiria laipẹ lẹyin ti ileeṣẹ ifọpo rọbi Dangote to wa nipinlẹ Eko kede adinku iye owo ti wọn n gbe lita epo bẹntiroolu kan lati N950 to N890 lati ibudo ifọpo.

Gẹgẹ ti atẹjade kan ti ileeṣẹ Dangote fi sita, lati ọjọ Abamẹta ọjọ kinni oṣu Keji ọdun yii ni adinku ti ba owo epo bẹntiroolu.

Ileeṣẹ ṣalaye ninu atẹjade ọhun pe adinku yii ko ṣẹyin bi owo epo ṣe walẹ lọja agbaye epo rọbi.

Ileeṣẹ Dangote ṣalaye wi pe ''igbeṣẹ ileeṣẹ ifọpo Dangote lati kede adinku yii wa ni ibamu pẹlu ileri rẹ lati maa jẹ kawọn onibaara ra janfaani nigba kugba ti adinku ba ti ba owo epo lọja agbaye.''

Anthony Chiejina to jẹ adari ẹka ibaraẹnisọrọ ileeṣẹ naa sọ pe igbesẹ yii ko tun ṣẹyin bi ileeṣẹ naa ti keede afikun owo epo bẹntirolu lọjọ kọkandinlogun oṣu Kinni yii niga ti owo epo lọ soke lọja agbaye.

O ṣalaye ninu atẹjade naa pe ileeṣẹ Dangote ko ro o lẹẹmeji lati lati kede adinkun owo epo bẹntiroolu lẹyin to walẹ lọja agbaye lati le mu adinku ba inira ti ọwọngogo epo n fa fawọn ọmọ Naijiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ipa ti adinku owo epo bẹntiroolu ti Dangote kede yoo ni lori araalu

Ninu atẹjade ti ile ifọpo rọbi Dangote fi sita ọhun ni o ti sọ pe adinku owo epo bẹtntiroolu yoo ni ipa to dara ni gbogbo ẹka ọrọ-aje Naijiria.

Ipa akọkọ ti yoo ni nipe igbesẹ yii mu adinku ba iye ti araalu n ra epo bẹntiroolu lita kan ni Naijiria.

Ile iṣẹ naa tun sọ pe adinku owo epo yii yoo jẹ ki nnkan to wọn gogo walẹ ni Naijiria.

Bakan naa ni ileeṣẹ Dangote sọ ninu atẹjade to fi sita pe adinku owo epo yii yoo tun jẹ igbe aye ọmọ Naijiria rọrun si.

Ileeṣẹ ifọpo Dangote wa ke pe awọn alagbata epo bẹntiroolu lati jẹ kawọn araalu janfaani adinku iye ti wọn n gbe epo bẹntiroolu bayii ibudo ifọpo nipa gbigbe owo ti wọn n ta lita bẹntiroolu kan walẹ.

Ileeṣẹ naa ni ifọwọsopọ awọn alagbata epo yoo jẹ ki eto imupadabọsipo eto ọrọ aje Naijiria eyi ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu so eso rere.

Ileeṣẹ Dangote ṣalaye ninu atẹjade naa pe erongba ijọba Aarẹ Tiniubu ni lati ri pe orilẹede Naijiria ko gbe epo wọle mọ lati ilẹ okeere.