Ikọ̀ ọmọogun ọlọ̀tẹ̀ kéde ìdádúró ogun ní DR Congo kí àwọn ohun ìrànwọ́ lè wọlé fáráàlú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ orilẹede G7 ati ajọ orilẹede ilẹ Yuroopu ti bu ẹnu atẹ lu rogbodiyan to bẹ silẹ lorilẹede naa eyi ti wọn tka si i gẹgẹ bi titapa si ẹtọ orilẹede DR Congo gẹgẹbi orilẹede to da duro labẹ aṣẹ ara rẹ.
Ikọ ọmọogun ọlọtẹ naa- ti wọn pe ara wọn ni Congo River Alliance- ti fi ẹsun kan ileeṣẹ ọmọogun orilẹede Congo pe wọn pa ọpọ araalu pẹlu lilo ado oloro.
Wn ni awọn ko ṣetan lati gba ilu kankan mọ.
Ninu atẹjade kan, awọn ọmọ ikọ ọmọogun ọlọtẹ naa ṣalaye pe "ohun to mu wa lọkan bayii ni didaabo bo awọn araalu ati ibudo ti a dimu bayii."
Wahala lẹkunjẹkun ti sọ omilẹgbẹ olugbe orilẹede DR Congo di alainile lori laarin ọdun mẹta. Lati ibẹrẹ ọdun 2025, o le ni ẹgbẹrun lọna irinwo eeyan ti ogun naa ti le kuro nile gẹgẹbi agbekalẹ ajọ to n mojuto aṣatipo lagbaye, UNRA.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Paul Kagame – to tun jẹ olori agba fun ikọ ọmọogun alaabo orilẹede Rwanda – ni oun ko mọ boya awọn ọmọ ogun orilẹede oun wa ni DR Congo.
"Ọpọ nnkan wa ti n ko mọ. Ṣugbọn bi o ba fẹ bi mi pe ṣe wahala to wa ni Congo kan Rwanda? Ati pe ṣe Rwanda yoo sa ipa gbogbo to ba yẹ lati daabo bo ara rẹ? Maa dahun pẹlu ifọwọsọya pe, bẹẹni"
Eyi ni ohun ti Aarẹ Kagame sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu CNN lọjọ Aje.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọṣa, nibayii, ẹgbẹ ajafẹtọ kaakiri ti n ke gbajare si ajọ agbaye gbogbo lati tubo koju oro si Rwanda ko le jawọ ninu ipa to n ko ninu wahala to n waye.
Minisita fun ibanisọrọ lorilẹede Congo ti ke si ajọ agbaye lati gbe igbesẹ ijiya to tọ fun Rwanda.
Patrick Muyaya ṣalaye fun ileeṣẹ akoroyinjọ Reuters pe, "ohun tokere julọ ninu igbesẹ lati ka wọn lọwọ ko ni ki wọn fi ijiya to yẹ jẹ wọn".
Aarẹ orilẹede Rwanda ati Congo yoo peju sibi ipade alaafia ajọ awọn orilẹede to wa lẹkun naa ti yoo waye ni orilẹede Tanzania lọjọ Ẹti.














