Kí ló dé tí ìlú Goma nílẹ̀ Congo ṣe pàtàkì àti ìdí tí ikọ̀ ọmọ ológun ọlọ̀tẹ̀ M23 ṣe fẹ́ gbà á?

Àwọn tó ń ṣe àtìpó ń kó érù wọn kúrò ní Munigi àti Kibati, ti wọ́n sì ń sá lọ sí Goma

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Àwọn tó ń ṣe àtìpó ń kó érù wọn kúrò ní Munigi àti Kibati, ti wọ́n sì ń sá lọ sí Goma
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Níṣe ni ìlú Goma ní ẹkùn ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè Democratic Republic of Congo ló tún ti ń gbóná janjan báyìí bí ìkọlù ọlọ́dún pípẹ́ tó ń wáyé láàárín àwọn alájàngbìlà tí a mọ̀ sí M23 àtàwọn ológun Congo ṣe tún peléke si èyí tó ti mú kí èèyàn tó lé ní 400,000 sá kúrò ní ilé wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí nìkan. Kí ló dé tí ẹnu fi ń kun Goma?

Àwọn wo ni M23?

M23 jẹ́ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n ya kúrò lára iléeṣẹ́ ológun láti bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn pẹ̀lú ẹ̀sùn pé àwọn fẹ́ dá ààbò bo àwọn ẹ̀yà Tutsi tí wọ́n ti ń kojú ìdẹ́yẹsí fún ìgbà pípẹ́.

Àwọn onímọ̀ ní àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé sọ pé orílẹ̀ èdè Rwanda, tó sún mọ́ Congo ló ń ṣe àtìlẹyìn fún ẹgbẹ́ náà àmọ́ ìjọba Rwanda ti jiyàn ẹ̀sùn yìí lọ́pọ̀ ìgbà.

Ṣáájú ni Rwanda ti sọ pé àwọn aláṣẹ DR Congo ń ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù ìpànìyàn tó wáyé sáwọn ẹ̀yà Tutsis àti Hutus.

Ní ọdún 2012 ni àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ yawọ Goma fún ọjọ́ mẹ́wàá kí wọ́n tó kúrò lẹ́yìn tí àwọn àjọ àgbáyé bẹ̀rẹ̀ sí ní takò wọ́n.

Lẹ́yìn ìgbà náà ni apá iléeṣẹ́ ológun Congo, pẹ̀lú àtìlẹyìn àwọn ilẹ̀ òkèrè, ká ikọ̀ náà tí wọ́n sì lé wọn kúrò ní orílẹ̀ èdè náà. àwọn ọmọ ogun M23 ní kí ìjọba gba àwọn sí iléeṣẹ́ ológun padà pẹ̀lú àdéhùn pé wọn yóò máa dá ààbò bo àwọn ẹ̀yà Tutsi.

Àmọ́ nígbà tó di ọdún 2021, ikọ̀ náà tún gbé ohun ìjà padà, pé ìjọba kò mú àwọn ilérí tí wọ́n ṣe ṣẹ.

Ọ̀pọ̀ àwon ẹkùn ní ìlà oòrùn DR Congo ni ikọ̀ M23 tún ti gba àkóso wọn. Àwọn onímọ̀ nípa UN sọ pé àwọn ọmọ ogun Rwanda tó lé ní 4,000 ló ń bá M23 ṣiṣẹ́ ní ìlà oòrùn.

Àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ M23 ń yíde káàkiri Goma ní ìlà oòrùn Democratic Republic of Congo, lẹ́yìn tí wọ́n gbàkóso ìlú náà lọ́wọ́ ìjọba lọ́dún 2012.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ M23 ń yíde káàkiri Goma ní ìlà oòrùn Democratic Republic of Congo, lẹ́yìn tí wọ́n gbàkóso ìlú náà lọ́wọ́ ìjọba lọ́dún 2012.

Ibùjókòó Goma

Goma jẹ́ ìlú tó ṣe pàtàkì sí ètò òṣèlú àti ọrọ̀ ajé ní ẹkùn àríwá Lake Kivu tó wà ní ẹnubodè Rwanda.

Àwọn èèyàn tó ń gbé ibẹ̀ lé ní mílíọ̀nù kan èyí tó mu jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí jùlọ ní Congo. Ilẹ̀ rẹ̀ tó jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá jẹ́ kó jẹ́ ojúkò okoòwò pẹ̀lú Rwanda.

Goma sún mọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ìlú tí wọ́n ti ń wakùsà, tí wọ́n sì ń pèsè àwọn ohun àlùmọ́nì bíi wúrà, tin,cobalt àti coltan lọ sí ilẹ̀ òkèrè. Bẹ́ẹ̀ náà ló ní àwọn ọ̀nà àti ètò ìrìnnà òfurufú tó dára. Ọ̀pọ̀ àwọn ikọ̀ apẹ̀tùsááwọ̀ àjọ UN ló ń fi ibẹ̀ ṣe ibùgbé, tí èyí sì ń pọnkún àwọn okoòwò àti àjọ àgbáyé tó ń lo ibẹ̀.

Àwọn United Nations Organization Stabilization Mission in the Democratic Republic of the Congo (MONUSCO)

Àwọn ohun ọrọ̀ Goma

DR Congo ni ìdá àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo cobalt tó wà ní àgbáyé wà. Coblat jẹ́ ohun àlùmọ́nì tó ṣe pàtàkì láti fi ṣe bátìrì lithium-ion tó wà fún fóònù, ọkọ̀ tó ń lo iná àtàwọn sígà ìgbàlódé.

Ìdúnkokò ogún tó ṣeéṣe kó wáyé ní DR Congo yóò ṣe àkóbá fún ìpèsè ohun àlùmọ́nì yìí, tó sì lè mú kí iye rẹ̀ gbẹ́nu sókè àti pé kó má sì í fún ìṣàmúlò àwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè ohun àmúṣagbára.

Àwọn awakùsà ní ibùdó ìwakùsà cobalt mine ní Tulwizembe, Katanga province, Democratic Republic of Congo, November 25, 2015.

Tí Goma bá ṣubú ńkọ́?

Ààrẹ DR Congo, Félix Tshisekedi sọ lọ́dún 2023 pé "Goma kò ní ṣubú láéláé". Ìlérí láti ri pé àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ kúrò ní ìlú náà wà lára ìlérí tó ṣe fáwọn èèyàn Congo èyí tó túmọ̀ sí pé ìṣubú Goma yóò nípa lórí ìtúnyànsípò ààrẹ náà.

DR Congo ti já okùn ọ̀pọ̀ àjọṣepọ̀ tó ní pẹ̀lú Rwanda èyí tó mú kí àkọwé àpapọ̀ UN, Antonio Guterres ṣèkìlọ̀ pé ìkọlù tó ń wáyé yìí le di ogun ẹnubodè ìlú méjì.

Bákan náà ló tún máa àlékún bá ìnílò ohun ìdẹ̀kùn èyí tí kò kó nǹkan mọ́ látàrí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé káàkiri àgbáyé.

Bí ikọ̀ M23 ṣe ń pọ̀ si lẹ́kùn ìlà oòrùn, níṣe láwọn èèyàn ń sá kúrò nínú àwọn ìlú kéréje, tí wọ́n ń sá lọ sí ilé ìwòsàn ní Goma.

Àjọ ajáfẹ́tọ̀ọ́ Human Rights Watch ní ó ṣeéṣe káwọn ará ìlú bá ogun lọ tí iléeṣẹ́ ológun bá gbéná wojú àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ M23.