Àwọn ọmọẹ̀yìn àwọn olóṣèlú alátakò ń kojú àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn ìbò ààrẹ lórílẹ̀èdè DRC

paa kan n ju tajutaju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ọlọpaa lorilẹede Democratic Republic of Congo atawọn ẹgbẹ alatako lorilẹede naa gbena woju ara wọn ni ilu Kinshasha tii ṣe olu ilu orilẹede naa.

Awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lorilẹede DRC n pe fun wiwọgile esi ibo aarẹ to waye lorilẹede naa lọsẹ to kọja.

Awọn eekan aṣiwaju awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lorilẹede DRC ti pariwo sita pe arumọjẹ lasan ni eto idibo sipo aarẹ to waye lorilẹede naa lọsẹ to kọja, wọn si n beere fun atundi ibo ọhun.

Ọpọlọpọ awọn eeyan lo farapa lasiko ti awọn ọlọpaa yin ibọn tajutaju si awọn oluwọde kan ti wọn si tun ju okuta pada si wọn ni ilu Kinshasha.

Ijọba orilẹede DRC ti gbẹsẹ le iwọde lorilẹede naa, pẹlu aṣẹ pe ko ni si ayekaye fun ẹnikẹni lati pagidina eto idibo lorilẹede naa.

Awọn oṣiṣẹ eto idibo nibẹ ko tii sọ ni pato iye awọn ibudo idibo ti idibo ti waye ati iye awọn eeyan to dibo lasiko idibo aarẹ lorilẹede Democratic Republic of Congo, DRC to waye ni ogunjọ oṣu kejila ọdun 2023.

Nnkan bii miliọnu mẹrinlelogoji oludibo lo forukọsilẹ fun eto idibo kaakiri nnkan bii ẹgbẹrun marundinlọgọrin ibudo idibo kakkiri orilẹede naa.

Ninu ibo to le ni miliọnu mẹsan ti wọn ti ka bayii, Aarẹ Felix Tshisekedi lo n lewaju pẹlu ida ọgọrin.

Aarẹ Tshisekedi n dije fun saa keji.

Moise Katumbi , ilumọọka oniṣowo kusa atiere bọọlu lo n ṣe ipo keji pẹlu ida mẹrindinlogun.

Martin Fayulu, to n lọgun pe wọn ja oun lole aṣeyọri ninu ibo ọdun 2018, lo n ṣe ipo kẹta pẹlu nnkan bii ida mẹrin ninu ọgọrun.

Awọn ololufẹ Ọgbẹni Fayulu dana sun taya ọkọ, wọn si gbe ina woju awọn agbofinro niwaju olu ileeṣẹ ipolongo rẹ to wa ni ilu Kinshasa.

Ọgbẹni Fayulu ni mọkanla ninu awọn ololufẹ oun lo ṣeṣe, bẹẹni awọn ọlọpaa pẹlu sọ pe agbofinro meji lo fara ṣeṣe.

Awọn oluwọde kan ni ilu Kinshsa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oniruru kudiẹkudiẹ lo ba idibo naa, eyi to mu ki wọn sun un siwaju di ọjọ keji lawọn agbegbe kan lorilẹede naa.

Awọn oloṣelu alatako tun fi ẹsun kan ajọ eleto idibo lorilẹede naa pe wọn n ṣe agbodegba fun iwa magomago ati jiji apoti ibo gbe lọna ati jẹ ki Aarẹ Tshisekedi pada sipo aarẹ fun saa keji.

Amọṣa, ajọ naa ti sẹ pe irọ balau ni awọn ẹsun naa.

Orilẹede DR Congo tobi ju orilẹede France lọ ni ida mẹrin, ṣugbọn awọn ohun amayedẹrun to yẹ fun igbayegbadun araalu ko si nibẹ. Koda ọna to dara ko wọ awọn ilu nlanla nibẹ pẹlu.

Nnkan bii ida meji ninu mẹta ọgọrun eeyan to wa lorilẹede naa lo jẹ wi pe inu oṣi ati iṣẹ ni wọn n gbe to si jẹ pe iye ti wọn n gba lojumọ ko ju dọla meji ati diẹ.

Bakan naa lawọn oludibo tun dibo fun awọn aṣojuṣofin agbegbe laarin awọn ẹgbẹrun lọna ọgọrun oludije to dije fun awọn ijoko ile aṣofin naa.

Idibo ko waye lẹkun ila oorun orilẹede naa nitori wahala abo to mẹhẹ.