BBC ṣàbẹ̀wò sí Goma, ibi táwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ M23 ti ń ṣèjọba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Paul Njie
- Role, BBC News, Goma
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Bí mo ṣe ń wa ọkọ̀ wọ inú ìlú Goma, DR Congo, ó ṣòro fún mi láti gbàgbọ́ pé ibí yìí ni ogun ti ń wáyé.
Níṣe ni àwọn èèyàn pọ̀ lójú títì tí kò jìnà sí ẹnubodè DR Congo pẹ̀lú Rwanda. Báwọn kan ṣe ń mórílé ọ̀nà ibi iṣẹ́ wọn, làwọn tó ń kiri ọjà ń bá káràkátà wọn lọ ní ẹsẹ̀ títì, bẹ́ẹ̀ làwọn ọlọ́kọ̀ náà ń pèrò sọ́kọ̀.
Àmọ́ síbẹ̀, kò ju ìṣẹ́jú péréte lọ tí èèyàn fi máa fura pé ìjọba tuntun ti gbòde ní ìlú náà.
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ M23 gba àkóso Goma, ìlú tó wà ní tó èèyàn mílíọ̀nù méjì ní ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè DR Congo lẹ́yìn táwọn àti àwọn ọmọ ogun fìjà pẹ́ẹ́ta.
Kò dín ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù náà, táwọn bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn mìíràn sì tún farapa gẹ́gẹ́ bí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN àti ìjọba Congo ṣe sọ.
M23, tó kún fún àwọn ẹ̀yà Tutsis ní ẹ̀tọ́ àwọn ẹ̀yà tí kò pọ̀ ni àwọn ń jà fún àmọ́ ìjọba DR Congo ní àwọn ohun àlùmọ́nì tó wà ní ẹkùn ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè náà ló wà lójú àwọn ikọ̀ tí orílẹ̀ èdè Rwanda ń ṣe àtìlẹyìn fún náà.

Àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ náà kò kojú alátakò kankan – níṣe ló dàbí pé wọ́n ti wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́.
Nígbà tí ikọ̀ ìròyìn dé ilé ìwòsàn kan lára àwọn ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó farapa.
Níbẹ̀ ni mo ti pàdé Nathaniel Cirho tó jẹ́ dókítà ìṣègùn òyìnbó tí òun náà ń gba ìtọ́jú.
Àdó olóró kan ló balẹ̀ sí ilé tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilé rẹ̀, tí ìkọlù àdó olóró náà sì ṣe ìjàm̀bá fún òun àti àwọn alábàágbé rẹ̀.
Dókítà Cirho ṣàlàyé pé apá ni òun ti ṣèṣe àmọ́ bàbá ẹni ọdún márùndínláàdọ́rin tó farapa ní ikùn látàrí ìkọlù náà jáde láyé lẹ́yìn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún un.
Ìyá àgbàlagbà kan náà ń gba ìtọ́jú pẹ̀lú lílo oxygen láti fi fà èémí látàrí bí ó ṣe fà ọta ìbọn yọ lápá ara rẹ̀.
Ó ní fúnra òun ni òun ń tọ́jú ojú egbò ọta ìbọn náà fún ọjọ́ mélòó kan kí àwọn ọmọ ogun M23 tó gbé òun ló sí ilé ìwòsàn.
Ìyá náà ní kí wọ́n gbé òun lọ sí ilé ìwòsàn aládàni nítorí pé òun kò gbádùn ìtọ́jú táwọn dókítà ní ilé ìwòsàn ìjọba ń fún òun nítorí èrò tó pọ̀ níbẹ̀.
Síbẹ̀, níṣe ni àwọn ilé ìwòsàn ń kún si látàrí báwọn tó ń farapa ṣe ń wọlé wá fún itoju.
Dókítà kan tí kò fẹ́ kí a dárúkọ òun nítorí ààbò sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ni àwọn ti ṣe ìtọ́jú wọn.
Ó ní èèyàn 315 ni àwọn ṣe ìtọ́jú lọ́jọ́ Àìkú tí ìjà bẹ̀rẹ̀ láàárín àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ M23 àti iléeṣẹ́ ológun Congo.
Ó sọ pé àwọn èèyàn tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) ló wà ní ilé ìwòsàn àwọn tó ń gbà ìtọ́jú látàrí bí wọ́n ṣe farapa tó.
Ó ní orí ni ẹlòmíràn fi gba ọta ìbọn, àwọn mìíràn ní apá, ikùn, ẹsẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹ̀ka tó ń mójútó jíjà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ní UN ti ṣèkìlọ̀ pé àwọn igun méjèèjì ń lo ìbálòpọ̀ tipátipá gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà ogun.
Tí dókítà ilé ìwòsàn yìí náà sì fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ bí ó ṣe sọ pé kò dín ní obìnrin mẹ́wàá tí ilé ìwòsàn àwọn tí tọ́jú látara Ìfipábánilòpọ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbúgbàmù àti ìró ìbọn ti lọ sílẹ̀ ní ìlú Goma, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn iléeṣẹ́ àti ṣọ́ọ̀bù ni kò ì tíì padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn. Àwọn ṣọ́ọ̀bù kan ti bẹ̀rẹ̀ sí ní tá ọjà padà làwọn agbègbè kan, tí kò sì rí bẹ́ẹ̀ làwọn agbègbè mìíràn. Bákan náà ni àwọn ilé ìfowópamọ́ ṣì wà ní títì pa.
Àwọn mìíràn ṣì wà nínú ìbẹ̀rùbojo pé ìkọlù mìíràn ṣì tún lè wáyé nítorí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ni ẹkùn North Kí ẹ lápapọ̀.
"Àwọn èèyàn ń bẹ̀rù, ẹ̀rù ṣì ń ba èmi náà nítorí àwọn tó dá gbogbo wàhálà yìí sílẹ̀ ṣì wà láàárín wa, a ò sì mọ nǹkan tó ń lọ," oníṣòwò kan Sammy Matabishi sọ.
"Àmọ́ ohun tó burú jùlọ ni pé a ò rí èèyàn bá wa ra ọjà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti sá lọ sí Bukavu, Rwanda, Kenya àti Uganda.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ oníṣòwò tó máa ń kó ọjà wọ orílẹ̀ èdè náà láti ilẹ̀ òkèrè ni kò rí ọjà kó wọlé mọ́ báyìí látàrí ìjà náà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú ló ti gba kámú lórí pé M23 ni yóò máa ṣe àkóso ìlú náà báyìí.
M23 tí gba àkóso ọ́fíìsì gómìnà ológun ti North Kivu, ẹni tí wọ́n pa bí wọ́n ṣe ń wọ Goma.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ náà ló wà káàkiri ìlú náà, táwọn kan sì ń yíde gbogbo ìlú náà pẹ̀lú ohun ìjà lọ́wọ́.
Fún gbogbo ìgbà tí a lò ní Goma, a ò rí ọmọ ogun DR Congo kan ní agbègbè náà àyàfi ọkọ̀ wọn kan tí wọ́n ti pa tì.
Níṣe ni ọta ìbọn àtàwọn ohun ìjà mìíràn kún ilẹ̀ lẹ́bàá ibi tí àwọn tó ń pẹ̀tù sí aáwọ̀ láti àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé tó ń dá ààbò bo àwọn ará ìlú lọ́wọ́ ìkọlù àwọn M23 wà.
Richard Ali tó ń gbé ní agbègbè náà sọ pé ní kété táwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ náà dé ní wọ́n rọgba yí àwọn ológun ká.
"Ọ̀pọ̀ wọn ló bọ́ aṣọ ogun wọn dànù, àwọn mìíràn sọ nǹkan ìjà ogun owó wọn nù, tí wọ́n sì ń wọ aṣọ ará ìlú, àwọn mìíràn sá lọ pátápátá."

Bí M23 ṣe ń fò fáyọ̀ pé àwọn ṣẹ́gun, ìjọba DR Congo ń jiyàn rẹ̀ pé M23 kò gba gbogbo mọ́ àwọn lọ́wọ́.
Ìjọba ń fẹ̀sùn kàn M23 pé wọ́n gba ilẹ̀ àwọn lọ́nà àìtọ́ pẹ̀lú àtìlẹyìn Rwanda tí wọ́n sì ṣèlérí láti gba gbogbo àyè wọn padà.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Rwanda ti jiyàn ṣíṣe àtìlẹyìn fún M23, ohun tí wọ́n ń sọ báyìí ni pé jíja ogun ní ẹnubodè àwọn jẹ́ ìpèníjà sí ààbò orílẹ̀ èdè àwọn.
Ìlú Bukavu, tó jẹ́ olú ìlú South Kivu ni ìròyìn sọ pé àwọn ọmọ ọlọ̀tẹ̀ náà mórílé báyìí, tí wọ́n sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti dé Kinshasa tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀ èdè DR Congo.
Ní báyìí, Goma ni ibi tí ìdìtẹ̀gbàjọba tó lágbára tí wáyé jùlọ. Ohun tó ń wáyé ṣeéṣe kó jẹ́ àfojúsùn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Congo tí M24 bá fi lè ráyè ju bí wọ́n ṣe wà lọ.
Àfikún ìròyìn látọwọ́ Robert Kiptoo àti Hassan Lali ní Goma












