Wo ohun tó fa awuyewuye lórí ìfẹ̀yìntì àti ọjọ́ orí ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà, Kayode Egbetokun

IGP Kayode Egbetokun, ọga ọlọpaa pata fun orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, IGP Kayode Egbetokun/ X

Àkọlé àwòrán, IGP Kayode Egbetokun, ọga ọlọpaa pata fun orilẹede Naijiria.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lọjọ Ẹti to kọja ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Nigeria Police Service Commission (PSC), ṣe pinnu pe awọn ọlọpaa tọjọ ori wọn ti ju ọgọta ọdun (60) lọ, pẹlu awọn ti wọn ti lo ju ọdun marundinlogoji (35) lẹnu iṣẹ gbọdọ fẹyinti kia.

PSC fẹnuko si ipinnu yii lẹyin ipade kan to waye, latari bawọn eeyan ṣe n sọ pe IGP Kayode Egbetokun ti i ṣe ọga ọlọpaa Naijiria ti too fẹyinti nitori ọjọ ori rẹ.

Oṣu Kẹsan-an ọdun 2024 ni Kayode Egbetokun pe ọgọta ọdun looke eepẹ.

Atẹjade ti agbẹnusọ wọn, Ikechukwu Ani, fi sita, sọ pe bi wọn ṣe pari ipade ni wọn ti ni ki awọn ọlọpaa to ti pe ọgọta ọdun maa lọ sile.

Bẹẹ naa ni wọn si jawe ifẹyinti fun awọn ti wọn ti lo ọdun marundinlogoji lẹnu iṣẹ ọlọpaa.

Wọn ni awọn yi ofin ọdun 2017 to ti n fi aaye gba awọn eeyan naa pada, ki wọn maa lọ silee wọn.

Atẹjade ọhun sọ pe IGP Kayode Egbetokun naa ti gbọ nipa ipinnu tuntun yii.

Ṣugbọn ko ni i kuro lọfiisi di 2027.

Kí ló dé tí IGP Egbetokun yóò fi wà lẹ́nu iṣẹ́ títí di 2027?

IGP Kayode Egbetokun, ọga ọlọpaa pata fun orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, The Nigerian Police

Àkọlé àwòrán, IGP Kayode Egbetokun, ọga ọlọpaa pata fun orilẹede Naijiria.

Báwo ni ìpè fún ìfẹ̀yìntì Egbetokun ṣe bẹ̀rẹ̀

Gbara ti Aarẹ Tinubu yan IGP Egbetokun ni 2023 ni awuyewuye ti bẹrẹ.

Ile igbimọ ijọba apapọ si ṣe atunṣe ofin kan nigba naa, to faaye gba a lati wa lẹnu iṣẹ ju igba to yẹ ko wa nibẹ lọ.

Ṣugbọn awuyewuye asiko yii bẹrẹ nigba ti Omoyele Sowore, ondupo aarẹ ni 2023, sọ pe ayederu ọlọpaa ni Egbetokun, pẹlu bo ṣe tun wa lẹnu iṣe lẹyin to ti pe ọgọta ọdun.

Eyi lo mu ileeṣẹ ọlọpaa fi ẹsun didunkooko mọni lori ayelujara kan Sowore.

Sowore foju ba kootu, ẹsun to si n jẹjọ rẹ lori Egbetokun bayii jẹ mẹrindinlogun (16 count charges)