Kò ṣeé má gbọ̀ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Wọ́nyi ni àwọn kò ṣeé má gbọ̀ọ́ ìròyìn káàkiri àgbáyé
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ṣebi wọn ni ori-ade kii sunta ni?

Bẹẹ ni Yoruba n n wi, amọ ki lo o ri?

Ọba Abdulsemiu Ogunjọbi, to fiya jẹ agbalagba oloye nita gbangba ma lo sun ọgba ẹwọn niluu Ilaro mọju

Adajọ majisireeti lo paṣẹ pe ki wọn gbe Kabiyesi naa ṣogba ẹwọn lẹyin ti igbiyanju rẹ lati gba beeli fori ṣanpọn

Kan si BBC.Com/Yoruba fun ẹkunrẹrẹ

'''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Ikunlẹ abiamọ o

Ki lo tun de, ta lo sọmọ nu?

Ọkọ àti ìyàwó kan lo maa rí òkú ọmọ wọn mẹ́ta tí wọ́n ń wá nínú ẹ̀rọ́ amu nkan tutu firiiji

Eyi ma pọju o, nibo niṣẹlẹ ọhun ti waye?

Alaye lori iroyin yii ati nnkan ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ wa lori ikanni BBC Yoruba

''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Gbogbo awọn to wa nidi rogbodiyan to bẹ silẹ niluu Esa-Oke ni foju wina ofin

Gomina Ademola Adeleke lo sọrọ yii lasiko abẹwo rẹ silu naa

Lẹyin aawọ to ṣẹlẹ laarin ilu Esa-Oke ati Ido Ayegunle lori iyansipo ọba tuntun

ọpọ dukia lo ṣofo tawọn eeyan si farapa yanayana

Fun ẹkunrẹrẹ iroyin yii.....