Lórí ọ̀rọ̀ ikú Bola Ige, Bisi Akande, Rashidi Ladoja sọ òkò ọ̀rọ̀ sí ara wọn

Bola Ige, Bisi Akande, Rashidi Ladoja

Oríṣun àwòrán, Bola Ige/Bisi Akande/Rashidi Ladoja/ Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo tẹ́lẹ̀ rí, Oba Rashidi Ladoja ti ní gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tẹ́lẹ̀ rí, olóyè Bisi Akande gbọdọ̀ tọrọ àforíjì lọ́wọ́ òun ní gbangba lórí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ikú olóyè Bola Ige.

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹta, oṣù Kejì, ọdún 2025, nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ nílé rẹ̀ tó wà ní agbègbè Bodija ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ni Ladoja ní Bisi Akande gbọ́dọ̀ tọrọ àforíjì lọ́wọ́ òun tàbí kí òun gbé e lọ sílé ẹjọ́.

Ladoja ní ó pọn dandan kí Bisi Akande kó ọ̀rọ̀ náà jẹ́ tàbí kí òun ti ọwọ́ òfin bọ ọ̀rọ̀ náà.

Kí ni Bisi Akande sọ nípa Ladoja?

Ní òpin ọ̀sẹ̀ ni ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tí Bisi Akande ṣe pẹ̀lú akọ̀ròyìn Edmund Obilo gba orí ayélujára níbi tí Akande ti sọ pé Ladoja nímọ̀ nípa àwọn nǹkankan lórí ikú Bola Ige.

Ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2001 ni àwọn kan ṣekúpa Bola Ige sí ilé rẹ̀ ní ìlú Ibadan.

Láti ìgbà náà, wọ́n kò ì tíì ṣàwárí ẹni tó pa Bola Ige títí di àsìkò yìí.

Akande nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà sọ pé ó ṣeni láàánú pé àwọn tó yẹ kí wọ́n tan ìmọ́lẹ̀ sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bíi gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Oyo, Lam Adeshina ni wọ́n ti jáde láyé tán.

Ó fẹ̀sùn kàn pé Ladoja, nígbà tó àkóso ìpínlẹ̀ Oyo gẹ́gẹ́ bí gómìnà lọ́dún 2003, kò tẹ̀síwájú lórí ẹjọ́ tí wọ́n pè lórí ikú Bola Ige.

Ó ní òun mọ̀ pé Lam Adeshina lọ sí ilé ẹjọ́ lórí ikú Bola Ige àmọ́ tí Ladoja tó gba ìjọba lẹ́yìn rẹ̀ gbé ẹjọ́ náà kúrò nílé ẹjọ́.

"Ẹ bèèrè lọ́wọ́ Ladoja, ó máa mọ nǹkan nípa ikú Bola Ige," Akande sọ.

"Mo ní ìgbàgbọ́ pé Ladoja ní àwọn ìròyìn kan nípa ikú Bola Ige tí ẹnikẹ́ni kò mọ̀."

Irọ́ lò ń pa mọ́ mi, sọ ohun tí o bá mọ̀ - Ladoja fèsì

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀rọ̀ tí Akande sọ yìí kò tẹ́ Ladoja lọ́rùn rárá, tó sì fẹ̀sùn kan Akande pé irọ́ ló ń pa mọ́ òun.

Ladoja ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé àgbà ló ń da Akande láàmú tó fi ń da lúúrú pọ̀ mọ́ Ìṣápá àti pé ó ń da ojú òótọ́ bolẹ̀.

Ladoja, tó tún jẹ́ Otun Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan, sọ pé òun kò ì tíì di gómìnà Oyo lásìkò tí wọ́n ṣekúpa Bola Ige ní ilé rẹ̀ àti pé ó ti pé ọdún àti oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé kí òun tó di gómìnà.

Ó fi kun pé ìjọba òun kò gbé ẹjọ́ náà kúrò ní ilé ẹjọ́, tí wọ́n sì fà ẹjọ́ ọ̀hún títí dé ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà ìyẹn Supreme Court.

"Irọ́ ni Olóyè Akande pa mọ́ mi lórí ọ̀rọ̀ náà, àgbàlagbà sì ni wọ́n."

Ó tẹ̀síwájú pé òun kò ní èrè kankan láti jẹ tí òun bá dọwọ́ bo ẹjọ́ náà nítorí òun àti Bola Ige súnmọ́ ara àwọn gidi nígbà tó wà láyé àti pé gbogbo àwọn ni ikú rẹ̀ bà lọ́kàn jẹ́.

"Mi ò mọ nǹkan tí Baba Akande gbàgbọ́ pé mo ní lórí ikú Bola Ige tí àwọn náà kò mọ̀, gbogbo àwọn nǹkan tí mo gbọ́ nípa ikú náà ló jẹ́ pé orí ayélujára ni mo ti gbọ́ wọn.

"Àwọn èèyàn ti máa ń sọ pé Bàbá Akande máa ń parọ́ tí mi ò gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀, kódà Bàbá Ayo Adebanjo sọ pé ó parọ́ sínú ìwé rẹ̀ tó kọ. Bóyá ọ̀kan lára àwọn irọ́ wọn náà tún ní èyí.

"Gbogbo ẹnu ni mo fi ń sọ ọ́ pé Baba Akande parọ́ mọ́ mi nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọn yìí."

Ladoja fi kun pé ó yẹ kí Olóyè Bisi Akande le sọ àwọn nǹkan tó mọ nípa ikú náà fún aráyé láti gbọ́ dípò bí ó ṣe ń ra ọ̀ràn ikú náà bọ òun lọ́rùn.

Ó ní to bá jẹ́ pé òun mọ ohunkóhun nípa ikú náà ni, òun ni ariwo òun máa lọ sókè jùlọ nígbà tí àwọn ń wá ìdájọ́ òdodo lórí ikú Bola Ige.

P parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí olóyè Bisi Akande tọrọ àforíjì lọ́wọ́ òun ní gbangba tàbí kí ilé ẹjọ́ bá àwọn dá sí ọ̀rọ̀ náà.