Tinubu kò fẹ́ dupò ààrẹ, gbogbo ẹni tó ń rọ̀ ọ́ láti díje, ló ń bá jà, èmi ni mo paṣẹ pé kó díje - Bisi Akande

Bola Ahmed Tinubu àti Bisi Akande

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/Bisi Akande/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Osun, Bisi Akande ti sọ̀rọ̀ lórí ipa tó kó, kí ààrẹ Bola Tinubu tó gbà láti du ipò ààrẹ.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí Bisi Akande ṣe ló ti ṣàlàyé pé Tinubu kò fẹ́ díje dupò ààrẹ àti pé gbogbo bí àwọn ṣe ń bá a sọ̀rọ̀ láti díje ló ń gbọnrí pé òun kò fẹ́ ṣe ààrẹ.

Akande ní Tinubu sọ pé òun kò ní owó tí òun lè fi díje àti pé àwọn ìpèníjà nípa ìlera òun yóò kò jẹ́ kí òun lè díje.

"Nígbà tí mo lọ bá a, ó ní bàbá, ṣé ẹ lówó?

Tí mo bá lówó láti fi dupò ààrẹ, èmi àti Dangote ni a jọ máa figagbága," Akande ṣàlàyé.

Ó sọ pé gbogbo àwọn tó bá ti bá Tinubu sọ̀rọ̀ láti díje ipò ààrẹ ló máa ń bá jà èyí ló mú mi gbéra lọ sí ìlú Eko láti bà sọ̀rọ̀ nígbà náà.

Àgbà olóṣèlú náà sọ pé òun sọ fún Tinubu pé ìran Yorùbá ló fẹ́ ṣe ààrẹ fún, pé kìí ṣe nítorí ara rẹ̀ ni àwọn ṣe ní kó díje.

"Mo sọ fún pé tí èèyàn bá fẹ́ bọ òrìṣà, ẹran ńlá tàbí iṣu tó bá tóbi ni èèyàn máa ń fun. Yorùbá fẹ́ ṣe ààrẹ, ìwọ sì ni èèyàn ńlá tí a ní báyìí láti dé ipò náà."

"Tinubu kọminú láti du ipò ààrẹ torí ẹsẹ̀ tó ń dùn-ún, mo sọ fún-un pé ara rẹ máa yá láàárín oṣù mẹ́fà."

Ó ní fún ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀jú ni Tinubu kò fi nǹkan tó máa sọ lẹ́yìn tí òun bá sọ̀rọ̀ náà, tó sì ń wo òun bí ẹni tí nǹkan ń ṣe.

"Nígbà tó máa fún mi lésì, ó ní ẹ ní kí n wá du ipò ààrẹ, ẹsẹ̀ mi yìí wá ń kọ́?

Ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìpèníjà ìlera rẹ̀, mó sọ fún pé Ọlọ́run á ṣe é. Ọjọ́ ṣì wà nílẹ̀, ara rẹ máa yá láàárín oṣù mẹ́fà."

Akande tún wòye lórí àwọn ìpèníjà tí Tinubu kojú kó tó di ààrẹ, ó ní òun gbàgbọ́ pé àwọn kan ló mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ìwọ́de #EndSARS láti fi bá ipò òṣèlú Tinubu jẹ́.

Ó ní wọ́n fẹ́ fi ìwọ́de náà fòpin sí ipa Tinubu lágbo òṣèlú ni.

'Wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ìwọ́de #EndSars láti fẹ́ fi bá Tinubu lórúkọ jẹ́ ni'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó fi kun pé àwọn kan "The Obidients" láti orílẹ̀ èdè America ló wà nídìí ìwọ́de náà, tí wọ́n sì mọ̀ọ́mọ̀ gbé ìwọ́de náà wá láti fẹ́ rẹ́yìn Tinubu.

"Mi ò sọ pé Obi ló wà nídìí ìwọ́de náà bíkòṣe àwọn "Obidients. Láti America ni wọ́n ti wá ṣe endsars, tí wọ́n sì sọ ara wọn di ìgbìmọ̀ kan lẹ́yìn ìwọ́de náà tí wọ́n fẹ́ dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀, nígbà tí wọn kò rí ẹgbẹ́ òṣèlú dá sílẹ̀ ni wọ́n pinnu láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan.

Bákan náà ló tún sọ̀rọ̀ lórí àjọṣepọ̀ tó wà láàárín Tinubu àti igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀, Yemi Osinbajo bó ṣe ní ipa tí òun kó lórí ìyànsípò rẹ̀ kó kéré rárá.

Ó ní ọdún 2011 tí Tinubu ń bá Buhari sọ̀rọ̀ lórí ẹni tí wọ́n máa fi rọ́pò Bakare ni òun sọ fún Tinubu pé òun máa sọ fún Buhari kó lo Osinbajo gẹ́gẹ́ bí igbákejì rẹ̀.

Akande sọ pé gbogbo ipá ni àwọn sà láti ri pé kò sí ìkùnsínú láàárín àwọn èèkàn Yorùbá lásìkò ìdíje sípò ààrẹ àti pàápàá bí Osinbajo kò ṣe ju ọwọ́ sílẹ̀ fún Tinubu.

Ó ní òun mọ̀ pé Tinubu nímọ̀ nípa òṣèlú gidigidi, tí òun sì kan sáárá sí ìmọ̀ rẹ̀ nínú òṣèlú pàápàá òṣèlú ìpínlẹ̀ Eko àti ti Amẹ́ríkà àmọ́ kò ní ìmọ̀ nípa òṣèlú Nàìjíríà.

Ó sọ pé òun gbàgbọ́ pé Tinubu yóò ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa òṣèlú Nàìjíríà nígbà tó ti wà nípò ààrẹ báyìí.