Ìdílé kan rèé tó fi iṣẹ́ sàárè gbígbẹ́ ṣe iṣẹ́ ìrandíran láì gba kọ́bọ̀
Isẹ kekere kọ ni isẹ gbigbẹ saare fun oku jẹ nitori ko si fun ọmọ ọlẹ, ti ọpọ ọkunrin to sangun si maa n sa fun.
Ni ilẹ Yoruba, awọn ana oku lo maa n gbẹ iboji ti wọn yoo sin oku si amọ laye ode oni, owo ni wọn n san fawọn eeyan kan lati gbẹ iboji oku.
Isẹ naa si ti di itẹwọgba debi pe idile kan wa ti wọn sọ isẹ gbigbẹ saare di isẹ afisilẹ fun ọmọ.

"Idile Adamu kii gba owo osu, owo ọya tabi owo kankan fun isẹ saare gbigbẹ, awọn oku to n rare ni ibudo igbokusi tabi ni oju popo ni wọn n sin"
Nilu Kaduna ni idile kan wa, idile Mogaji Ibrahim Adamu ati ẹbi rẹ to yan isẹ gbigbẹ saare ni aayo.
Idile naa si ti gbẹ saare fun ọpọlọpọ ọdun ni itẹ oku to tobi julọ nilu naa to wa ni adugbo Tundun Wada.
Iyalẹnu si lo jẹ pe idile kii gba owo osu, owo ọya tabi owo kankan fun isẹ saare gbigbẹ ti wọn n se, ọfẹ lo ba de.
Idi ni pe awọn oku to n rare ni ibudo igbokusi tabi ni oju popo ni wọn mu bii isẹ lati maa sin.
Owo ti awọn eeyan ba si bun wọn ni wọn fi n gbọ bukata aye wọn.
Yooba ni ohun ti eeyan ba mọ se, bii idan lo n ri , bẹẹ ni ọrọ Ibrahim ati ẹbi rẹ ri lasiko ti wọn ba n gbẹ saare tori bi wọn se n jẹun, ni wọn yoo maa se awada, ti wọn yoo si maa sinmi.
Ki lo sun ẹbi yii de idi isẹ saare gbigbẹ, ki lo de ti wọn se nifẹ si isẹ naa, awọn nnkan rere wo ni wọn ti se nidi isẹ naa, ki si ni ọjọ iwaju wọn nidi isẹ naa?
BBC ba Mogaji Ibrahim Adamu sọrọ lati wa idahun sawọn ibeere yii.

"Ẹnu ọna itẹ oku yii ni baba mi ku si lasiko to fẹ wọ isẹ, emi ati aburo mi mẹtẹẹta n sisẹ nitẹ oku yii, mo gbagbọ pe ọkan ninu ọmọ mi yoo jogun isẹ naa"
Mogaji Adamu to jẹ olori awọn eeyan to n gbẹ saare ni iboji Tundun Wada ni o le ni ọgbọn ọdun ti oun ti n sisẹ naa.
Amọ osu to kọja ni oun kọkọ gba owo isẹ ri, fun isẹ saare gbigbẹ ti oun n se.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Ibrahim ni osu keje ọdun 1992 ni oun ti n sisẹ ni itẹ oku naa.
O ni baba oun ati aburo rẹ gan ti sisẹ yii saaju nitẹ oku Tundun Wada naa fun ọpọlọpọ ọdun.
"Ẹnu ọna itẹ oku yii ni baba mi ku si lasiko to fẹ wọ isẹ ni aarọ ọjọ kan, ẹni ọdun mejilelogoji si ni baba mi nigba to jade laye.
Emi ati aburo mi mẹtẹẹta si lo n sisẹ yii nitẹ oku yii, mo si nigbagbọ pe ọkan ninu ọmọ mi yoo jogun isẹ naa.

"Owo ti awọn eeyan ba bun wa, ni a fi n gbọ̀ bukata aye wa amọ alaga tuntun ni ijọba ibilẹ n san ẹgbẹrun mẹtalelogoji fun emi ati ẹbi mi"
"Ẹgbọn mi Abdullahi Adamu lo kọkọ isẹ gbigbẹ saare nibi lai gba owo kankan.
A maa n sin awọn oku lorisirisi, paapaa awọn oku ti wọn ko ri ẹbi wọn tabi to n rare.
Owo ti awọn eeyan ba bun wa, ni a fi n gbọ̀ bukata aye wa tori a ko gba owo ọya tabi owo osu lori isẹ gbigbẹ saare yii.
Ẹnikẹni ti ẹ ba ri, to n se iru isẹ yii, o n se nitori Ọọrun ni."
Mogaji Adamu wa salaye pe oun gbogbo ti yipada bayii nitori ipenija ọrọ aje to n pọ si.
O fikun pe awọn ni bukata aya, ọmọ lati gbọ pẹlu ilera ati ipese fun idile awọn.
"Agidi la fi maa n ri idamẹwa ohun ti a nilo, ti a si n ke si awọn eeyan lati wa se iranwọ fn to n gbẹ saare."
Lọwọ lọwọ bayii, alaga ijọba ibilẹ n san ẹgbẹrun mẹtalelogoji fun Mogaji ati ẹbi rẹ.






