NLC tako àfikún owó ìpè àti dátà, gbèrò láti bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de lọ́jọ́ Ajé

Aworan Joe Ajaero

Oríṣun àwòrán, Joe Ajaero/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ti kede pe awọn oṣiṣẹ yoo bẹrẹ ifẹhonuhan lọjọ kẹrin oṣu Keji ọdun yii lori afikun ida 50% owo tariiifu lori ipe ati data ori foonu ti ajọ NCC to n ri si eto ibaraẹnisọrọ buwọlu laipẹ yii.

Ninu atẹjade kan ti aarẹ ẹgbẹ naa, Joe Ajaero, buwọlu ni NLC ti kede igbesẹ yii nibi ipade igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa to waye l'Ọjọru ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kinni niluu Abuja.

Igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ NLC tako afikun owo tariifu pẹlu ida 50% nibi ipade wọn Ọjọru, eyi ti wọn ṣapejuwe wi pe o ti pọju fun araalu.

"Kii ṣe asiko ti ijọba gbe owo gun ina mọnamọna ati epo bẹntiroolu, lo tun yẹ ko se afikun owo ipe ori foonu ati data"

Ajọ NLC tun bu ẹnu ẹtẹ igbesẹ ajọ NCC lori bi o ti buwọlu afikun owo tariifu lori ipe ati data.

NLC paṣẹ ninu atẹjade naa wi pe ki gbogbo oṣiṣẹ dẹyẹ si lilo foonu tabi rira data

lati ọjọ kẹrin oṣu Keji ti ijọba ba kọ lati ṣe idaduro afikun owo tariifu naa.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni igbesẹ ajọ NCC yii buru jai, o si le ṣakoba fawọn oṣiṣẹ atawọn araalu lapapọ papaa julọ lasiko yii ti ọpọ ti ilu le koko latari awọn eto ti ijọba to wa lode n ṣe ti ko tii kẹsẹjari.

NLC ni awọn oṣiṣẹ yoo fẹhonu wọn han lori igbesẹ ajọ NCC yii nipa siṣe kaakiri orilẹede lọjọ kẹrin oṣu Keji to n bọ.

Ajọ NCL sọ ninu atẹjade naa wi pe iwọde yii yoo jẹ ikilọ fun ijọba lati jẹ ki wọn mọ akoba ti afikun owo tariifu yii le ṣe fawọn oṣiṣẹ to n gba N70,000 gẹgẹ bii owo oṣu to kere julọ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ tun fikun ọrọ rẹ pe kii ṣe lasiko ti ijọba gbe owo ina mọnamọna ati epo bẹntiroolu lọ soke ti ọwọngogo nnkan gbode lo tun yẹ ki afikun tun ba owo tariifu fun ipe ori foonu ati data.

Gbogbo ẹka awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn ipinlẹ kaakiri Naijiria atawọn ẹgbẹ mii ni ajọ NLC ti rọ bayii lati darapọ mọ iyanṣẹlodi ọhun ti yoo waye lọjọ kẹrin oṣu Keji to n bọ.

NLC ko ṣai kepe ijọba apapọ, ajọ NCC ati ile aṣofin agba l'Abuja lati ṣepade pọ pẹlu awọn tọrọ kan lẹka eto ibaraẹnisọrọ, ki wọn da afikun owo tariifu naa duro.

Ajọ NLC ni ti ijọba ba kọ lati ṣe eleyii, ẹgbẹ oṣiṣẹ yoo tẹsiwaju pẹlu ifẹhonuhan to fẹ ṣe, ati pe awọn tun le dẹyẹ si ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ kaakiri orilẹede Naijiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Awọn onibaara pariwo lori afikun tariifu ori ipe ati data

Ẹwẹ, lati igba ti ajọ NCC ti kede afikun ida 50% owo tariifu ori ipe ati data lọpọ onibaara ti n fi aidunnu wọn han.

Funmi Adejumo to jẹ oniṣowo niluu Eko sọ pe ''gbogbo igba ni wọn maa n sọ fun wa pe Naijiria lawọn eeyan ti n sanwo to kere julọ lori ipe, atẹjiṣẹ ati data nilẹ Afirika.

Amọ, ki ni eyi tumọ si nigba tawọn eeyan ko ba lagbara ra data ọhun mọ?

Lai ṣe ani ani, afikun owo tariifu yii yoo mu aye le sii fun ọpọ ọmọ Naijiria.

Ṣugbọn oninmọ nipa ọrọ aje, Aliyu Ilias, sọ pe ko si bi awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ sẹ fẹ tẹsiwaju lati maa ṣiṣẹ ti wọn ko ba fowo kun owo tariifu ori ipe, atẹjiṣẹ ati data.

Akọsilẹ kan ti ajọ ITU to n ri si eto ibaraẹnisọrọ lagbaaye lọdun 2023 sọ pe $2.35 lawọn eeyan n ra data giigi meji (2GB) ni Naijiria, eyi ti wọn n ra n ni $2.66 lorilẹede Ghana, $2.92 ni Kenya, ati $7.98 lorilẹede South Africa.

''Ipe ori foonu tawọn eeyan n lo N11 fun tẹlẹ yoo di N16.50''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ipe ori foonu tawọn eeyan n lo N11 fun tẹlẹ yoo di N16.50 pẹlu afikun owo tariifu ti ajọ NCC kede bayii.

Atẹjiṣẹ tawọn eeyan n lo N4 lati fi ranṣẹ lori foonu tẹlẹ yoo di nnkan ti wọn n lo N6 lati fi ranṣẹ bayii.

Bakan naa, data giigi kan tawọn eeyan n fi N1000 ra tẹlẹ yoo di N1,500 bayii pẹlu afikun owo tariifu ti ajọ NCC kede.

Ohun tawọn akọṣẹmọṣẹ nipa eto ibaraẹnisọrọ ṣalaye ni pe alekun ko ba owo tariifu ni Naijiria fun bi ọdun mẹwaa bayii.

Bakan naa ni wọn sọ pe awọn nnkan tawọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ nilo lati ri awọn onibaara wọn n pe lori foonu gaara, fi atẹjiṣẹ ranṣẹ ati ṣe awọn nnkan mii ti gbowo lori.

Ọga agba ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ Airtel, Dinesh Balsingh, sọ pe afikun owo tariifu tawọn onibaara n san sẹ pataki ti wọn ba fẹ maa tẹsiwaju lati maa gbadun lilo foonu wọn fun ohun ti wọn ba fẹ.

Ọgbẹni Balsingh ṣalaye pe alekun ida 300% lo ba owo tawọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ fi n ṣiṣẹ laarin ọdun meji pere.

Bakan naa ni o tun sọ pe bi owo Naira ko ti ra nnkan kan mọ naa wa lara awọn nnkan to ṣakoba fun awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ.

Ọga ileeṣẹ Airtel fikun ọrọ rẹ pe owo lita kan epo disu tawọn n lo fun ẹrọ amunawa ti lọ soke lati N230 si N1,000.

Ti ẹ o ba gbagbe, ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ MTN ati Airtel kede pe awọn jẹ gbese nitori bi awọn nnkan ti wọn fi n ṣiṣẹ ṣe gbowo lori .

MTN kede pe awọn padanu owo ti ko din ni ₦514.9bn laarin oṣu mẹsan an akọkọ ninu ọdun 2024, nigba ti Airtel padanu $89m lọdun 2023.