''Irọ́ ni APC ń pa, Aregbesola ló fẹgbẹ́ sílẹ̀ fúnra rẹ̀, á kéde ẹgbẹ́ tuntun tí Aregbe ń lọ láìpẹ́''

Oríṣun àwòrán, Rauf Aregbesola/Facebook
Yoruba bọ wọn ni isọrọ ni igbesi, eyi lo mu ki ẹgbẹ Omoluabi Progressive to tẹ le gomina ipinlẹ Osun tẹlẹ, Ọgbẹni Rauf Aregbesola kuro ninu ẹgbẹ oselu APC fesi sọrọ ti ẹgbẹ APC sọ wi pe awọn ti le Ọgbẹni Aregbesola kuro ninu ẹgbẹ naa.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ l'Ọjọbọ, alukoro ati akọwe ẹgbẹ Omoluabi Progressive, Abosede Oluwaseun, ṣalaye pe funra Aregbesola lo kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC kii ṣe wi pe ẹgbẹ lo le e.
Ọgbẹni Oluwaseun sọ pe ''irọ, ahesọ ọrọ, ailọmọluabi, ailootọ ọkan, ati ai le sọ ododo to ba APC jẹ nipinlẹ Osun ati ni gbogbo Naijiria naa ni ẹ tun ri ti wọn gbe jade yẹn.
Lọjọ Aiku ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kinni ọdun yii ni mo fi atẹjade kan sita eyi ti a fi kede pe gbogbo awọn ọmọlẹyin Aregbesola ati oun gan an funra rẹ ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
A si sọ ninu atẹjade naa wi pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ wa lo fọwọ si igbesẹ yii, kii ṣe nnkan ti Ọgbẹni Aregbesola nikan da ṣe.''
Ọgbẹni Oluwaseun ṣalaye pe lẹyin ti Aregbe atawọn ọmọlẹyin rẹ ti kuro ninu ẹgbẹ APC tan ni ẹgbẹ naa ṣẹṣẹ wa sọ l'Ọjọru wi pe awọn lo le e kuro ninu ẹgbẹ.
O ni a ọrọ naa ti di abamọ fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ tori wọn o mọ wi pe bi ọrọ ti maa ri niyẹn.
Ohun to mu Aregbesola kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC
Oriṣiiriṣii nnkan lo ṣẹlẹ eyi to mu Aregbesola pinnu lati fi APC silẹ, gẹgẹ bi Ọgbẹni Oluwaseun ṣe ṣalaye.
Alukoro ẹgbẹ Omoluabi Progressive sọ pe ''lọdun 2018 ti Aregbesola fẹ kuro ni ijọba gẹgẹ bi gomina ni ede-ai-yede kọkọ waye lori ẹkun to yẹ ki oludije gomina ti wa ninu ẹkun mẹtẹẹta to ni sẹnẹtọ kọọkan.
A si rii wi pe ẹkun iwọ oorun ipinlẹ Osun lo yẹ ki oludije gomina ti wa nigba naa tori lati ẹkun aarin gbungbun ni Aregbe ti wa.
Ṣugbọn Aregbesola tako ẹgbẹ lati gbaruku ti Gboyega Oyetola nitori adehun to wa laarin oun ati ọga rẹ Aṣiwaju Bola Tinubu nigba naa pe oun fẹ ki aburo oun Oyetola rọpa Aregbe nigba naa.
Eleyii ko dun mọ ọpọ ọmọ ẹgbẹ, koda, awọn ọmọ ẹgbẹ kan binu fi ẹgbẹ silẹ nigba naa.
Ṣugbọn o ṣeni laanu wi pe Oyetola kọ ẹyin si Aregbesola ati awọn ọmọ ẹgbẹ to ṣiṣẹ fun un to fi wọle ibo gomina.
Niṣe lo bẹrẹ si ni yọ ọpọ ninu wọn lẹgbẹ, bakan naa, lo n lo awọn ọmọ janduku lati dunkoko mawọn ọmọ ẹgbẹ.''
Ọgbẹni Oluwaseun ṣalaye pe ẹsun ti wọn fi kan Aregbe ni pe oun ni ko jẹ kawọn tete wọle ibo gomina lọdun 2018.
Bakan naa ni o tun sọ pe wọn yan Ọgbẹni Aregbesola atawọn alẹnulọrọ mii sinu igbimọ ipolongo APC nigba naa.
Ọgbẹni Oluwaseun fikun ọrọ rẹ pe Aregbesola gbe igbesẹ akin lati pari aawọ to n lọ ninu ẹgbẹ APC nipa kikepe awọn to ba n binu soun ninu ẹgbẹ wi pe ki wọn dari jin oun.
O ni Aregbe naa sọ pe oun ti darijin awọn to ṣẹ oun naa ninu ẹgbẹ APC, amọ, Ọgbẹni Oluwaseun ni ẹti iku ni wọn tun kọ si igbesẹ yii.
Alukoro ẹgbẹ Omoluabi Progressive wa fidi rẹ mulẹ pe igun Oyetola ninu APC kọ lẹta si ẹgbẹ APC lati ipinlẹ Osun lọdun to kọja pe awọn fẹ le Aregbe kuro ninu ẹgbẹ.
Ọgbẹni Oluwaseun ni lẹyin eyi lawọn ọmọlẹyin Aregbesola korawọn jọ pọ gẹgẹ bi ẹgbẹ Omoluabi Progressive ninu ẹgbẹ APC nipinlẹ Osun.
O ni ayọrisi ẹgbẹ yii ni ikede ọjọ Aiku to kọja pe Aregbesola atawọn ọmọlẹyin rẹ ti kuro ninu APC nipinlẹ Osun.
Ẹgbẹ oṣelu wo ni Aregbesola fẹ darapọ mọ lẹyin to fi APC silẹ?
Nigba ti o n sọrọ lori ẹgbẹ oṣelu ti o ṣee ṣe ki Aregbesola darapọ mọ, Ọgbẹni Oluwaseun sọ pe ''eeyan kii mọ ẹyẹ ti a ba de mọ igba, a ṣẹṣẹ n ṣi ẹyẹ naa ni, awọn eeyan ti wa n ri ẹnu ẹyẹ naa.
Awọn eeyan n wo nnkan ti a de mọ inu igba bo ya dudu ni tabi funfun.
Laipẹ lai jina, ki ọsẹ meji to pe, a o kede ibi ti a n lọ fawọn eeyan.''
Ọgbẹni Oluwaseun ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ahesọ ọrọ lasan ni APC n gbe kiri pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni Aregbesola ati awọn ọmọlọyin rẹ fẹ darapọ mi.
O ni ẹgbẹ PDP, ẹgbẹ NNDP ati LP atawọn ẹgbẹ oṣelu mii ti wa bawọn lati le darapọ mawọn.
Alukoro ẹgbẹ Omoluabi ni bi awọn ṣe ṣe niyẹn ti awọn alẹnulọrọ fi wa darapọ mawọn.
O ni gbogbo eeyan lo maa mọ ẹgbẹ ti Aregbesola atawọn ọmọlẹyin rẹ yoo darapọ ni bi ọjọ meloo kan si akoko yii.
Ẹ̀ṣẹ̀ Rauf Aregbesola rèé tí a fi lé e kúró nínú ẹgbẹ́ - APC
Ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Osun ti kede pe oun ti le gomina tẹlẹ nipinlẹ naa, Rauf Aregbesola kuro ninu ẹgbẹ oselu naa.
Atẹjade kan ti APC Osun fisita ni irọlẹ ọjọru salaye pe awọn igbesẹ ti minisita tẹlẹ fọrọ abẹle naa n gbe, eyi to tako idagbasoke ẹgbẹ oselu naa lo mu ki oun le kuro ninu ẹgbẹ.
Atẹjade naa ti deeti ọjọ keje osu kinni ọdun yii wa ninu rẹ ni nibi ipade igbimọ alasẹ ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Osun ni wọn ti pinnu lati yọ Aregbesola.

Oríṣun àwòrán, Rauf Aregbesola Facebook
"Ìgbesẹ Aregbesola tako irẹpọ ati orukọ rere APC, ko sì gbọdọ pe ara rẹ ni ọmọ ẹgbẹ mọ tabi ko dibọn bẹẹ nibikibi"
Bẹẹ ba gbagbe, saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe igun Omoluabi ti Aregbesola ko sodi ni wọn ti kọkọ kede pe awọn ti fi ẹgbẹ oselu APC silẹ.
Nibi ipade naa si ni Aregbesola peju si atawọ ọmọ ẹgbẹ oselu to jẹ igun Ọmọluabi lati wọọdu ojilelọọdunrun o din mẹjọ 332.
Ninu iwe ti ẹgbẹ APC kọ naa lo ti n naka aleebu si Aregbesola pe o tapa si ẹsẹ ofin kọkanlelogun ẹgbẹ naa, eyi to sọ awọn ijiya to wa fun ọmọ ẹgbẹ to ba tapa si ofin naa.
Wọn ni igbesẹ Aregbesola naa ti tako irẹpọ ati orukọ rere ẹgbẹ oselu APC, ti wọn si n kilọ fun pe ko mase pe ara rẹ ni ọmọ ẹgbẹ oselu naa mọ tabi ko dibọn bẹẹ nibikibi.
Ìdí rèé tí Aregbesola àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ṣe fẹ́ kúrò nínú APC
Saani la ti mu iroyin wa fun yin pe, Gomina ipinle Osun tẹlẹ, Ọgbẹni Rauf Aregbesola ati awọn to n tẹle e ninu ẹgbẹ Omoluabi Progressives ti wọn da silẹ, ti kuro ninu ẹgbẹ APC bayii.
Ninu atẹjade kan ti Abosede Oluwaseun, Akọwe ipolongo ẹgbẹ naa fi sita ni wọn ti fidi ẹ mulẹ, pe gbogbo ẹgbẹ lo fọwọ si ipinnu yii.
Iroyin sọ pe ipade oloṣooṣu to maa n waye ni wọn ti ṣe ipinnu naa, eyi to waye lọjọ Aiku ọsẹ yii niluu Ilesa.
Gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati wọọdu 332 ni wọn ti fẹnuko, pe ki Aregbesola atawọn ọmọ ẹgbẹ yooku kọyin si APC.

Oríṣun àwòrán, Ọgbẹni Rauf Aregbesola/ Facebook
Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an tí wọ́n fi yapa?

Oríṣun àwòrán, Ọgbẹni Rauf Aregbesola/ Facebook
Ninu awọn idi ti wọn la kalẹ fun iyapa kuro lara APC ni: Dídá-ẹyẹ-si-ni laaarin ẹgbẹ, idaduro ati yiyọ awọn to le di olori ẹgbẹ kuro lai gbọ ti ẹnu wọn rara.
Bi wọn ṣe n fa ọwọ aago ẹgbẹ sẹyin ati awọn ẹsun mi-in to farapẹ ẹ tun jẹ idi mi-in ti Aregbesola atawọn to n tẹle e ṣe fi APC silẹ.
Atẹjade naa ka pe, "Wọn tun fi aidunnu wọn han si rogbodiyan abẹle to n lọ ninu ẹgbẹ APC Osun, eyi to jẹ ki ẹgbẹ naa padanu ipo gomina si ẹgbẹ alatako lọwọ.
"Eyi tumọ si pe ẹgbẹ naa ti n sọ agbara ati gbajumọ rẹ nu l'Osun niyẹn."
"Awọn ọmọ ẹgbẹ dibo nipa sisọ ohun ti wọn fẹ, wọn si ni awọn ṣetan lati bọ sinu ẹgbẹ oṣelu miran, ṣaaju idibo gomina ti yoo waye ni 2026 nipinlẹ Osun."
Kí ni Aregbesola wí?

Oríṣun àwòrán, Ogbeni Rauf Aregbesola/ Facebook.
Nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ, Ọgbẹni Rauf Aregbesola, gboriyin fun wọn bi wọn ṣe duro ṣinṣin ti i lẹyin.
Aregbesola, ni, "Inu mi dun gidi lati ri i pe gbogbo yin fi ohun ṣọkan, ki i ṣe pe ẹ tun fohun ṣokan lasan, itumọ rẹ ni pe a jọ ṣetan lati wọnu aṣeyọri to n duro de wa ni.
"Mo fẹẹ ran yin leti, pe irinajo ta a fẹẹ rin yin wa fun gbigbe ipinlẹ wa debi oriire nipasẹ idari ọmọluabi ni.
"Ọna taara la rin yii, o kun fun rere ti yoo gbe ipinlẹ wa debi giga.
" Fun idi eyi, ẹ gbọdọ fi ara jin si i, kẹ ẹ si mu awọn olootọ eeyan to ṣetan lati ba wa rin ọna iye yii wa"
Aregbe to ti figba kan jẹ minisita ọrọ abẹle ri lorilẹede yii, sọ pe ẹgbẹ awọn ko fi ti oṣelu, ẹsin tabi ẹya ṣe, gbogbo eeyan lo wa fun.
O ni awọn pọ, ọgbọn n bẹ, eeyan si wa lati gbe Osun gunke. Awọn yoo ṣe aṣeyọri pẹlu aṣẹ Oluwa lo fi kadi rẹ nillẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju idibo gomina Osun ni 2022 ni wọn da ẹgbẹ Omoluabi Progressives sile, lẹyin ti wọn tu ẹgbẹ 'The Osun Progressives, TOP, ka.
Ni 2024, ẹgbẹ APC Osun yọ awọn agbaagba to n tẹle Aregbesola danu, lẹyin naa ni wọn si da Aregbe funra rẹ duro ninu ẹgbẹ.
















