Ìdí rèé tí Makinde fi ní káwọn òṣìṣẹ́ Oyo máa wọ Aṣọ Òkè ní gbogbo Ọjọ́bọ

Aworan Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Laipẹ yii ni ijọba ipinlẹ Oyo sọ fawọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa lati maa wọ Asọ Oke lọ sibi iṣẹ ni gbogbo Ọjọbọ.

Eyi jẹ afikun si ọjọ Ẹti tawọn oṣiṣẹ maa n wọ aṣọ ibilẹ lọ ibi iṣẹ tẹlẹ ni ipinlẹ naa.

Lọjọ Aje ọjọ kẹtadinlọgbọn ni ijọba Oyo sọ fun gbogbo ileeṣẹ ijọba lati maa tẹle ọrọ ti ijọba sọ yii.

Gẹgẹ bii atẹjade kan to wa lati ọfiisi adari oṣiṣẹ nipinlẹ Oyo ṣe sọ, wiwọ asọ oke lọ si ọfiisi ni gbogbo Ọjọgbọ jẹ ọna lati sẹ igbelarugẹ aṣa ati iṣe awọn eeyan ipinlẹ Oyo.

Bakan naa ni ijọba tun ṣalaye wi pe eto yii yoo ṣe tun jẹ ki ọrọ aje ipinlẹ Oyo gbooro si.

Atẹjade naa sọ pe igbesẹ yii ṣe pataki tori ọpọ eeyan bii awọn to n hun aṣẹ, awọn to n rẹ aṣọ laro atawọn telọ to n ran aṣọ ni yoo tun maa ri iṣẹ ṣe sii.

''Ọpọ eeyan lo jẹ wi pe nibi iṣẹ aṣọ oke ni wọn ti n jẹun, tori naa, eyi yoo mu adinku ba airiṣẹ ṣe, ati pe yoo tun pawo sapo awọn to n ṣe iru iṣẹ bayii.''

Adari awọn oṣiṣẹ sọ ninu atẹjade naa wi pe Gomina Seyi Makinde n wa oriṣiiriṣii ọna lati ri pe eto ọrọ aje ipinlẹ Oyo gbooro si.

O ni ijọba n reti ki ọpọ eeyan bẹrẹ si ni ra aṣọ oke eyi ti yoo mu idagbasoke ba awọn oṣiṣẹ ti kii ṣe oniṣẹ ijọba.

Bakan naa ni ireti wa pe, eyi yoo tun jẹ ki ẹka irinajo igbafẹ nipinlẹ Oyo gbooro si.

Ijọba sọ ninu atẹjade to fi sita wi pe wiwọ aṣọ oke ni gbogbo Ọjọbọ kii ṣe nipa aṣọ wiwọ lasan, amọ, o nii ṣe pẹlu gbigbe aṣa ati iṣe ipinlẹ Oyo larugẹ ati imugbooro ọrọ aje ipinlẹ naa.

Adari oṣiṣẹ tun sọ ninu atẹjade to fi sita pe awọn oṣiṣẹ yoo jẹ aṣoju aṣa nipinlẹ Oyo bayii nipa wiwọ aṣọ oke ni gbogbo Ọjọbọ ati ọjọ Ẹti.

Awọn ipinlẹ Yoruba ti ijọba ti sọ ṣaaju pe kawọn oṣiṣẹ maa wọ aṣọ oke lọ sibi iṣẹ

Ipinlẹ Osun

Ni oṣu kọkanla ọdun 2023 ni Gomina Ademola Adeleke sọ pe kawọn oṣiṣẹ ipinlẹ Osun maa wọ aṣọ Adirẹ lọ sibi iṣẹ ni gbogbo Ọjọru.

Adari awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa, Ọgbẹni Ayanleye Aina lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita.

Ọgbẹni Aina sọ ninu atẹjade ọhun pe gbogbo oṣiṣẹ nipinlẹ Osun lo gbọdọ maa pa aṣẹ ijọba yii mọ.

Adari awọn oṣiṣẹ tun sọ pe eto yii ko yọ awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ lawọn ile ẹkọ giga ipinlẹ Osun naa silẹ to fi mọ awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ pẹlu.

O ni gbogbo awọn to n ba ijọba Osun ṣiṣẹ naa to fi dori awọn oludamọran patapata lo gbọdọ maa wọ aṣọ Adirẹ ni gbogbo Ọjọru bayii.

Adari awọn oṣiṣẹ fikun ọrọ rẹ wi pe ijọba ipinlẹ Osun ti n gbero lati ṣe ayajọ ọjọ aṣọ Adirẹ nipinlẹ Osun.

O ni igbesẹ yii yoo jẹ ki iṣẹ awọn to n ṣe Adirẹ gbooro ati eto ọrọ aje ipinlẹ Osun lapapọ.

Bakan naa ni o tun sọ pe wiwọ aṣọ Adirẹ lọ sibi iṣẹ tun nii ṣe pẹlun igbelarugẹ aṣa ati iṣẹ ipinlẹ Osun.

Ijọba ipinlẹ Ogun ni Adire lawọn akẹkọọ yoo maa wọ lọ ile ẹkọ

Ninu oṣu kọkanla ọdun 2020 ni Gomina Dapo Abiodun sọ pe aṣọ Adirẹ ni yoo rọpo aṣọ tawọn akẹkọọ n wọ lọ ile ẹkọ nipinlẹ naa.

Gomina Abiodun ni saa keji oun lọfiisi ni awọn akẹkọọ yoo bẹrẹ si ni ṣe eleyii.

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Ogun tun kepe ijọba apapọ lati maa lo aṣọ Adirẹ fawọn eto ti n wọn ba fẹ ṣe.

Nibi eto ifilọlẹ tita aṣọ Adirẹ lori itakun ayelujara ni Kuto l'Abeokuta ni Abiodun ti sọrọ yii.

Gomina ipinle Ogun ni wiwọ aṣọ Adirẹ n ṣe agbelarugẹ aṣa ilẹ Yoruba fun gbogbo agbaye.

Koda, Ọmọba Abiodun tun rọ ijọba apapọ pe ko jẹ kawọn elere idaraya maa wọ aṣọ Adirẹ lọ sawọn idije ti wọn ba ti n lọ kaakiri agbaye.

Gomina ni gbogbo awọn abẹnugan lẹnu iṣẹ ijọba lo gbọdọ maa wọ aṣọ Adirẹ ni gbogbo ọjọ Ẹti nipinlẹ Ogun.

Gomina Abiodun ni lilo ati wiwọ aṣọ Adirẹ yoo jẹ ki idasoke ba iṣẹ aṣọ Adirẹ ni ipinlẹ Ogun.