Ilé ẹjọ́ gíga ìlú Ado Ekiti da ẹjọ́ ìwà ọ̀daràn tí ọlọ́pàá pè tako Farotimi nù

Dele Farotimi

Oríṣun àwòrán, Dele Farotimi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile ẹjọ giga kan niluu Ado Ekiti ti da ẹjọ iwa ọdaran ti wọn fi kan ajafẹtọ ọmọniyan, Dele Farotimi nu.

Adajọ Babs Kuewumi lo da ẹjọ ọhun nu lẹyin ti ọlọpaa to pe ẹjọ naa, Samson Osobu kọ iwe sile ẹjọ naa ọlọpaa ko ṣe ẹjọ mọ.

Osobu sọ fun ile ẹjọ pe "oni lo yẹ ki igbẹjọ tẹsiwaju amọ a ti kọwe si ile ẹjọ pe a ko ṣe ẹjọ mọ, a si ti fi iwe naa ṣọwọ si ile ẹjọ laarọ oni."

Lẹyin ti ikọ olupẹjọ sọrọ tan, ikọ agbẹjọro Farotimi, eyii ti Adeyinka Olumide-Fusika dari wọn ko tako ọrọ naa.

Eyii lo mu ki adajọ Kuewumi da ẹjọ ọhun nu, to si kede pe "a ti da ẹjọ yii nu."

Olumide-Fusika sọ fun awọn akọroyin pe oun ti gba Farotimi nimọran lati maṣẹ ba awọn akọroyin sọrọ kankan nipa ẹjọ naa.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ẹjọ mii ti wọn pe tako Farotimi ṣi wa nile ẹjọ majistreeti niluu Ado Ekiti yii kan naa.

Ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2025 yii ni wọn sun ẹjọ ile ẹjọ majistreeti si, igbagbọ si wa pe ọlọpaa yoo kọwe sile ẹjọ naa pe awọn ko ṣe ẹjọ mọ.

Yatọ si awọn ẹjọ ti wọn pe Farotimi niluu Ado Ekiti, Farotimi tun n koju awọn ipẹjọ mii nile ẹjọ giga ilu Abuja, ile ẹjọ giga ipinlẹ Ogun, ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo ati ile ẹjọ giga ipinlẹ Rivers, ti awọn agbẹjọro Afe Babalola pe tako o.

A ko tii le sọ boya wọn yoo wọgile awọn ẹjọ naa.

Awọn kan lara awọn ile ẹjọ naa ti fofin de Farotomi tabi ẹnikẹni to ba n ṣiṣẹ fun pe wọn ko gbọdọ tẹsiwaju ninu titẹ iwe "Nigeria and its Criminal Justice System," ninu eyii ti wọn ni o ti ba orukọ Afe Babalola jẹ.

Ẹwẹ, baba Afe Babalola ti sọ pe oun forijin Farotimi, lẹyin ti Ooni Ile Ife, Ewi ilu Ado Ekiti, atawọn lọbalọba mii ṣabẹwo si niluu Ado Ekiti, nibi ti wọn ti rọ ọ pe ko fi iye denu lori iwe ti Farotimi kọ, to si sọ pe oun yoo jẹ eburẹ.