45% àwọn ọmọdébìnrin ní Naijiria ló ń gboyún kí wọ́n tó pé ọdún méjìdínlógún – World Bank

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Banki agbaye ti kede pe ida marundinlaadọta ọmọdebinrin ni Naijiria lo ti bimọ, ki wọn to pe ọdun mejidinlogun.
Ọrọ yii ni adari banki agbaye ni Naijiria, Ndiame Diop sọ nibi ipade kan to da lori eto ẹkọ awọn obinrin, eyii to waye niluu Abuja.
Lasiko to n sọrọ lori bi awọn ọmọdebinrin ko se lọ sile ẹkọ, o ni ida meji ninu mẹta awọn ọmọbinrin Naijiria lo fi ile ẹkọ silẹ ṣaaju ki wọn to wọ ile ẹkọ girama.
Diop, ti igbakeji rẹ, Taimur Samad, ṣoju fun sọ pe "Ida 35% lo ti lọ sile ọkọ ki wọn to pe ọdun marundinlogun, nigba ti ida 45% ti bimọ ki wọn to pe ọmọ ọdun mejidinlogun."
O ṣalaye siwaju si pe pẹlu ifọwọsowọpọ ijọba atawọn olori agbegbe, o ṣeeṣe ki ọrọ ọhun di ohun igbagbe.
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni minisita eto ẹkọ Naijiria, Tunji Alausa.
Alausa sọ pe eredi ti pupọ ninu awọn ọmọde naa ko ṣe si nile ẹkọ ko ṣẹyin iṣẹ ati iya, isinru ọmọde, ti tete lọ ile ọkọ atawọn aṣa abinibi mii to n ṣakoba fun awọm ọmọde ọhun.
O sọ siwaju si pe "O jẹ ohun ibanujẹ lati ri awọn ọmọde to n kiri ọja laarin adugbo tabi ti wọn n ṣiṣẹ ọmọ ọdọ lasiko to yẹ ki wọn wa nile ẹkọ nibi ti ẹbun wọn yoo ti jade.
Alasusa ni bo tilẹ jẹ pe eto ẹkọ ọfe wa lawọn agbegbe kan, o ṣeni laanu pe pupọ ninu awọn ọmọ naa lo ṣoro fun lati kawe.
O fi kun pe iṣe n lọ lọwọ lati ri daju pe gbogbo awọn ọmọdebinrin to yẹ ko kawe ni wọn jẹ anfani naa ni Naijiria.















