Àṣà àwọn ọ̀dọ́ ni mo kì wọnú orin Àpàlà, tó fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà - Rasheed Apala
Bi aye ba n yi, ka maa baye yi ni asa kan to n se akoba pupọ fun iran Yoruba.
Idi ni pe ède, asa ati ise Yoruba lo ti n l sokun igbagbe nitori bi a se n baye yi, bo se n yi lọ.
Ọkan lara orin ilẹ Yoruba to rinlẹ julọ, to si jẹ itẹwọgba pupọ ni orin Apala jẹ, asiko aye awọn oyinbo amunisin si lo rinlẹ julọ.
Lara awọn eeyan to si bẹrẹ orin Apala ni Haruna Ishola, Ayinla Omowura, Ligali Mukaiba, Adisa Aniyameta, Raimi Dogo, Lasisi Layemi, Aminu Olaribigbe, Lasisi Onipede ati Kasunmu Alao, eyi to jẹ itẹwọgba yika ilẹ Yoruba
Amọ fun iyalẹnu orin Apala naa, to bẹrẹ laarin ọdun 1930 si lo ti n sun kẹrẹ-kẹrẹ maa di ohun igbagbe bayii tori awọn akọrin to n kọrin Apala ko to nnkan.

Lọwọ lọwọ bayii, awọn ọdọ kan ti n dide lati maa kọ orin Apala, ko le di itẹwọgba pada.
Lara iru ọdọ bẹẹ si la ti ri Rasheed Adejumo ẹni to yan lati gba ọna atijọ nidi kikọ orin ilẹ Yoruba yatọ sawọn akẹẹgbẹ rẹ to n yan orin takansufe laayo.
BBC Yoruba se alabapade akọrin Apala naa, to si salaye fun wa ohun to mu ko nifẹ si orin Apala kikọ.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Rasheed ni ọpọ eeyan lo maa n ya lẹnu pe ọdọ bii ti emi lo n kọrin Apala.
Bi awọn eeyan ba gbọ orin mi, wọn a ni iru ohun wo ree, ti wọn ba wa ri mi, wọn a ni iru se iwọ lo ni ohun yii, maa si dahun pe emi naa ni Ọlọrun fun.

"Kekere ni mo ti nifẹ si orin Apala"
Rasheed tẹsiwaju pe kekere ni oun ti nifẹ lati maa gbọ orin Apala tori pe orin yẹn ni baba oun maa n gbọ.
"Agbalagba ni baba mi, agba ara lo fi bi wa, orin Apala ni baba mi maa n gbọ, lati ipasẹ bẹẹ ni emi naa se nifẹ si orin Apala.
Gbogbo awọn orin Haruna Ishola ni mo maa n gbọ debi pe emi naa dagba, tawọn orin yii si wu mi, ti mo si n kọrin naa funra mi.
Lootọ pupọ ọdọ le ma nifẹ si orin Apala amọ ni ti emi, ibi ti ẹbun mi wa ni idi orin yii, ibẹ si ni mo lọ."

"A n kọ awọn ajasa ati ede to jẹ tawọn ọdọ, ki wọn le tẹwọgba orin Apala"
Lori ọpọ ipenija to n koju rẹ nidi kikọ orin Apala, Rasheed ni ọ̀pọ̀ ipenija lo koju oun nidi kikọ orin Apala, paapaa nidi jijẹ ki orin oun jẹ itẹwọgba.
"Ọpọ ibi la ti lọ, to si jẹ pe wọn n yinmu si wa pe ki la n kọ.
Amọ dipo ki ọkan mi rẹwẹsi, se ni a ronu ọna ti orin Apala mi yoo fi jẹ itẹwọgba.
Tori naa la se n kọ awọn ajasa ati ede to jẹ tawọn ọdọ, ki wọn le tẹwọgba orin naa.
Ti a ba gbọ orin takansufe ti aye gba tiẹ, awa naa yoo yi si orin Apala, aye yoo ba tun gba tiẹ.
Ọpọ eeyan lo maa n foju Alagbe wo awọn olorin sugbọn isẹ alalubarika ni isẹ orin kikọ, awọn baba to ti kọrin saaju, ti wọn ti se aseyọri nidi rẹ pọ.
Imọran mi fawọn ọdọ ti ko fẹ se ohun atijọ ni mo n gba nimọran pe ko si ẹbun ti Ọlọrun fun eeyan, to gbe.
Mo si tun n rọ wọn lati ni ifarada, ki wọn ma tete gba kamu."






