Wo àǹfààní orin kíkọ àti ijó jíjó fún àwọn olóyún.

Àkọlé fídíò, Wo àǹfààní orin kíkọ àti ijó jíjó fún àwọn olóyún.

Ọkan lara nnkan pataki to se anfani fun oloyun ni sise ere idaraya ati jijẹ ounjẹ to se ara loore sugbọn oni ọna kan ti ilewosan fi n se ere idaraya yii fun awọn oloyun.

Ileeṣẹ BBC News Yoruba ṣe abẹwo si ile wosan ijọba lati mọ anfani ere idaraya ti awọn oloyun maa n se paapa orin aramọnda ati ijo ti wọn jo si.

Nọọsi agba, Folake Fasasi Bakare ni orin kikọ fun awọn oloyun jẹ nnkan pataki to n jẹ ki ilera to peye wa fun awọn oloyun.

Bakare ni anfani ere idaraya yii ni lati mu inu oloyun dun ti ko si ni le ri aye lati ronu

"O da bii idaraya fun awọn oloyun, boya oloyun ti inu rẹ kodun lati ile wa,

"Nibi ti a ba ti n jo, ti a n rẹrin, oun naa a tura ka, inu rẹ dun."

Bakara ni ko da fun oloyun lati maa ironu abaadi nitori ko da fun ago ara ati oyun ti wọn ni.

"Orin ti a n kọ yii, ara isẹ wa ni"

Bakare ni awọn orin ti awọn kọ yii ni o wa lara orin ti awọn nọọsi kọ nigba ti wọn n gba idanilẹkọ ni ile ékọ.

O ni ile ẹkọ jẹ ki o ye awọn pe ara isẹ awọn ni lati se fun oloyun

"Awọn orin kan wa ti a kọ fun ara wa, imi wa ti ni lati lọ lati le lo fun awọn oloyun

"Ibi ti a ba ti n ṣe awada, ti a n kọrin, inu ọmọ inu gan a dun"

Bakare salaye siwaju pe yatọ si pe a n fi awọn orin yii se awada, anfani lo jẹ fun wọn lati le ba awọn oloyun sọrọ pe bawo ni ago arawọn se ri.

"Lẹyin ijo ni a ma ni ki wọn lo se ayẹwo wa, ni a sọ fun wọn pe ki wọn maa wa si ipade oloyun daada."

Ki ni awọn nnkan aramọnda ti awọn oloyun maa fẹ jẹ lasiko ti wọn ba loyun

Ileeṣẹ BBC News Yoruba ba awọn oloyun sọrọ lori anfani ijo ti wọn jo ati pe ki ni awọn nnkan aramọnds ti wọn ma n jẹ lasiko ti wọn wa ni oyun.

Ọpọ awọn oloyun yii ni ko ni fẹ si pe ki a darakọ wọn sugbọn wọn salaye orisirisi itu ti wọn ma pa lasiko ti oyun wa lara wọn.

Yatọ si iyẹn, awọn oloyun yii salaye ohun ti wọn wa fi oju awọn baale wọn ri lasiko

Ẹkọ pọ ninu fọnran yii, ẹ wo