Ohun ìní pàtàkì ni fóònù jẹ́, ọlọ́pàá kò ní ẹ̀tọ́ láti yẹ fóònù aráàlú wò - Ọlọ́pàá

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi ti sọ pe ko si ọlọpaa kankan to lẹtọọ lati da araalu duro, ki wọn si maa yẹ foonu wọn wo.

Oyeyẹmi lo sọrọ naa lori eto ori redio kan to ti jẹ alejo niluu Abẹokuta, ipinlẹ naa l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii.

Nibẹ lo tun ti jẹ ko di mimọ pe araalu ko gbọdọ bẹru lati yẹ ọlọpaa to ba wa yẹ ile wọn wo fun iwadii, nitori pe oju lalakanfinṣọri.

O ni bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa lẹtọọ lati da araalu ti wọn ba fura si duro, ki wọn si yẹ ẹ wo, ti wọn ko ba si ti ba nnkan ifura lọwọ rẹ, dandan ni lati fi iru ẹni bẹẹ silẹ, ko maa lọ.

Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe bi ọlọpaa ba ti wa n wa nnkan ti ko sọnu kiri, o di dandan lati fi ẹjọ iru ọlọpaa bẹẹ sun awọn alaṣẹ.

''Araalu lẹtọọ lati yẹ ọlọpaa to ba lọ yẹ ile wọn wo fun iwadii''

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:

"Ọlọpaa ni ẹtọ lati da ẹnikẹni duro, ki wọn si yẹ iru ẹni bẹẹ wo. Wọn le fura si eeyan wi pe awọn fẹẹ yẹ iru ẹni bẹẹ wo. Ti wọn ko ba ti wa ba nnkan ifurasi lọwọ tabi lara rẹ, wọn a sọ pe ko maa lọ.

"Ṣugbọn to ba ti wa a di pe ọlọpaa wa yẹ eeyan wo, ti wọn ko si ba nnkankan, ti ọlọpaa naa wa fẹ maa wa ọna lati ṣe nnkan miran, ẹ gbiyanju lati tẹle e de teṣan. Ẹ ma ṣe ba ọlọpaa naa ja.

"Ti ẹ ba ti de teṣan, ẹ lọ fi ẹjọ ẹ sun, tabi ki ẹ pe wa lati fi iru ẹni bẹẹ sun wa. Ki ẹ wa duro lati maa wo iru iya to maa jẹ ọlọpaa bẹẹ. A maa beere lọwọ nipa ẹni to ran an niṣẹ. Mo ti maa n sọ ọ laimọye igba.

"Ọlọpaa ko lẹtọọ lati da eeyan duro lati maa yẹ foonu iru ẹni bẹẹ wo. Ko ni ẹtọ kankan. Ohun ini eeyan ti ẹlomiran ko lẹtọọ lati maa wo ni.

"Bi ọlọpaa ba wa sile ẹ pẹlu iwe aṣẹ lati yẹ ile rẹ wo, iwo gan-an ni ẹtọ lati yẹ awọn ọlọpaa wo ko to di pe wọn bẹrẹ ayẹwo wọn. Aimọye awọn eeyan to n ṣe bẹẹ daadaa, ki awọn araalu ma ṣe bẹru lati yẹ ọlọpaa wo.

"Ti o ba kọ lati yẹ ọlọpaa wo, ti wọn ba lọ fi nnkan ti kii ṣe tiẹ sinu ile ẹ nkọ."