Àsọdùn ọ̀rọ̀ ni wí pé wọ́n rán agbénipa sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀sun- Tunde Badmus

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Asiwaju Musulumi nilẹ Yoruba, Edo ati Delta , Dokita Khamis Olatunde Badmus ti sapejuwe ija to bẹ silẹ laarin Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ati Sẹnẹtọ Ajibola Bashir ni bi irun Yidi gẹgẹ bi nnkan to jẹ ẹdun ọkan ati pe ko yẹ ki irufẹ rẹ waye rara.

Ninu atẹjade ti Asiwaju fi lede fun awọn akọroyin, o tọrọ aforijin lọwọ Gomina lori isẹlẹ naa, eyi ti ko fun gomina ni anfani lati darapọ mọ awọn Musulumi lati kirun Yidi niluu Osogbo.

O tẹsiwaju pe awọn janduku oloselu lo ko ina mọ isẹlẹ naa, to fi di tọrọfọnkale, ati pe asọdun ni pe wọn ran awọn agbanipa lati sekupa gomina ni bi irun Yidi naa

"Isẹlẹ yii jẹ nnkan ti ko yẹ ko waye, to si mi dun mi pupọ.

"Asọdun ni lati sọ pe awọn agbanipa fẹ sekupa gomina.

"Iponlogo ibo ti pari ti isejọba si ti bẹrẹ bayi, ẹ fi gomina silẹ, ko gbajumọ sise ijọba ti yoo mu ayipada to da de ba awọn araalu.

"Mo ki Ọga fun ileeṣẹ Ọlọpa, DSS ati ẹẹsọ alaabo si gomina fun bi wọn se fi ọmọniyan se lasiko ti ija naa bẹẹ silẹ.

"O se koko pe ki ọfisi to n mojuto irina gomina mojuto bi gomina yoo joko si, ki se pe wọn yoo wa gbe le oloselu kan lọwọ pe ko gba aye silẹ fun gomina."

N ko ro pe ẹ mọ itumọ pe wọn fẹ sekupa eeyan.- Ajibola Bashir

Sẹnẹtọ Ajibola Bashir ti fesi si isẹlẹ, to si oun ko ro pe awọn n ka si oun pe oun fẹ sakupa gomina mọ itumọ ọrọ ti fi sapejuwe isẹlẹ .

"N ko orukọ kankan to ni aye gomina ni ibi ti mojoko si, n ko ri awọn ẹẹsọ allabo gomina ati awọn ti ẹgbẹ oselu nibẹ"

Bashir ni oun ko ni isoro kankan pẹlu Gomina Ademola Adeleke, ati pe nnkan to waye ni o jẹ is\w ọwọ awọn alatilẹyin gomina ti wọn isoro pẹlu rẹ.