Adeleke àti àwọn jàndùkú rẹ̀ ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ wàhálà ní Yídì - APC

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/ajibola Bashiru
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ti sọ pe oun ko ni fi ara mọ ija oṣelu ati dida alaafia ilu ru, lati ‘ọwọ ẹni to yẹ ko jẹ olori alaabo ipinlẹ Osun’.
APC sọ eyi gẹgẹ bi esi si wahala to waye laarin Gomina Ademola Adeleke ati Sẹnetọ ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ, Ajibola Bashiru nbi adura ọdun ilya niluu Osogbo.
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Osun to sọ ọrọ naa, Sooko Tajudeen Lawal, sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe ẹgbẹ koro oju si bi Gomina Adeleke ṣe da wahala silẹ ni gbagede Yidi nilu Osogbo.
O ni aṣilo ipo ni iwa ti Gomina Ademola Adeleke ati awọn to wa pẹlu rẹ hu.
“Bi awọn janduku gomina ṣe fẹ fi ipa le Sẹnetọ Ajibola Bashiru ati Alhaji Tunde Badmus, to jẹ Asiwaju ti ilu Osogbo, kuro ni aaye ti wọn joko si ni Yidi, ati bi gomina ṣe paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa mu awọn mejeeji lo da wahala silẹ.
Ẹgbẹ osẹlu APC tun fi ẹsun kan pe gomina tun paṣẹ pe ki wọn o ti ilẹkun Yidi pa nitori ki ọwọ le tẹ awọn eeyan mejeeji – eyi si lo mu ki awọn araalu gbena woju awọn janduku gomina.
“Gomina ko sọkalẹ rara kuro ninu ọkọ rẹ ni Yidi, bakan naa si ni ko duro ki adura bẹrẹ to fi lọ.”
Eyi tako nnkan ti Gomina Adeleke sọ ninu atẹjade to fi sita lori iṣẹlẹ naa, pe igba meji ti oun gbiyanju lati wọle sinu Yidi ni awọn janduku Sẹnetọ Ajibola di ọna.
Ó yà mí lẹ́nu láti bá àwọn agbanipá tí wọ́n rán sí mi ní Yídì ọdún - Adeleke

Oríṣun àwòrán, OSUN STATE GOVERNMENT
Gomina ipinlẹ Osun, Sẹnetọ Ademola Adeleke, ni alaafia ni oun pada de ile lẹyin rogbodiyan to waye laarin oun ati Sẹnetọ tẹlẹ to tun jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, Ajibola Bashiru nibi adura ọdun.
Owurọ Ọjọru ni iroyin jade pe Gomina Adeleke binu kuro ni ibi adura ọdun lẹyin ti awọn janduku to jẹ ti Sẹnetọ Ajibola kọju ija si i.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun gomina, Mallam Olawale Rasheed fi sita, o ni iyalẹnu nla lo jẹ fun gomina lori ipa ti Sẹnetọ Ajibola ko ninu ikọlu naa pẹlu bo sẹ “joko si aaye ijoko ti wọn yà sọtọ fun gomina nibi adura ọdun naa.
“Gbogbo igbiyanju lati mu ki sẹnetọ nigba kan ri ọhun fi aaye naa silẹ lo ja si òfò.”
Mallam Olawale sọ pe lílù ni awọn tọọgi sẹnetọ naa lu awọn ọmọ ẹgbẹ osẹlu PDP to beere apọnle fun gomina.
O ni gbogbo Eid ti daru nigba ti gomina funra rẹ yoo fi de sibi eto adura ọdun , to si ya a lẹnu pupọ lati ri awọn janduku to di ihamọra kaakiri gbogbo ibudo Eid.
“Awọn oṣiṣẹ alaabo fi to wa leti pe wọn ko awọn janduku naa wọle si Eid, pẹlu erongba lati pa gomina ati awọn eeyan pataki miran to wa ninu iṣejọba.”
Atẹjade naa tun sọ pe igba meji ni gomina gbiyanju lati wọle sibi adura, amọ ti awọn janduku n yi i ka, eyi to mu ki awọn ẹṣọ alaabo rẹ tete gbe e kuro wọ inu ọkọ̀ rẹ.
Gomina Adeleke tun wa rawọ ẹbẹ si awọn eniyan ipinlẹ Osun lati gba alaafia laaye lori iṣẹlẹ naa.
Bakan naa lo ni oun ti paṣẹ fun awọn ileeṣẹ alaabo, to fi mọ kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Osun, lati fi ofin mu gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu si gomina.
Ohun táa mọ̀ nípa ìjà tó wáyé láàrin Adeleke àti Bashir nibi ìrun Eid nílùú Osogbo

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun ni o binu kuro ni ibudo irun Eid, to si palasẹ pe ki wọn gbae agadagodo si ẹnu ilẹkun Eid naa.
Iroyin to tẹ Ileeṣẹ BBC News Yoruba leti nipe ija bẹ silẹ ni bi ti awọn eeyan ti fẹ kirun naa lẹyin Sẹnẹtọ ana nipinlẹ Osun, Ajibola Bashir kọ lati kuro ni aaye ti wọn fi silẹ fun Adeleke lati jọkọ lẹgbẹ Ataoja ti ilu Osogbo, Oba Jimoh Olanipẹkun Oyetunji ati Asiwaju ilẹ Osogbo, Oloye Tunde Badmus.
Akọrọyin wa to wa nibẹ ni Asiwaju ti ilẹ Osogbo, Oloye Tunde Badmus, Sẹnẹtọ Ajibola Bashir ati awọn eeyan jankankan miiran lo ti kọkọ de si ibudo irun Eid naa lati kirun.
Sẹnẹtọ Bashir joko si iwaju sugbọn awọn ẹsọ alabo gomina sọ pe aye to wa lo jẹ ti gomina ipinlẹ Osun, pe ko ma joko sibẹ rara.
Gẹgẹ bi akọroyin wa se sọ, kete ti Gomina Adeleke de si Eid ni Oloye Badmus dide kuro laye rẹ lati lọ ki Gomina kaabo si Eid
Gomina Adeleke sakiyesi pe ọkan lara awọn agbofinro n ba Sẹnẹtọ Bashir sọrọ pe ko kuro ni aye iwaju, ti awọn eyan kan to jẹ ọmọ ilu si yari pe ọkan lara eeyan pataki ni Ajibola Bashir naa jẹ nipinlẹ Osun.
Ọrọ naa lo ni gbọmisi omioto ti Gomina Ademola Adeleke si fi Eid silẹ to si gbaa ibẹ lọ ilẹ
Iroyin tẹsiwaju pe akitiyan awọn Ọlọpaa lati gbe Ṣẹnẹto Ajibola Bashir ni o jasí paabo nitori bi Asiwaju ilẹ Osogbo, Alhaji Tunde Badmus ko ṣe fi aye gba awọn Ọlọpaa lati le gbe Ajibola Bashir
Saaju ni Bashir Ajibola ni aanu awọn ara ipinlẹ Osun n ṣe oun bi wọn se faye gba awọn alawada lati maa se ijọba ipinlẹ Osun.















