Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí mẹ́ta lórí ikú òṣìṣẹ́ 'Navy' ní Ondo

SEKESEKE

Oríṣun àwòrán, Others

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ní ọjọ́rú ní ọwọ́ àwọn ti tẹ àwọn afurasí mẹ́ta tó lọ́wọ́ nínú ikú òṣìṣẹ́ ọmọ ogun orí omi ní ìlú Idoani, ìjọba ìbílẹ̀ Ose.

Ní ọjọ́ Ajé ni àwọn ọmọ gànfé kan lu òṣìṣẹ́ ọmọ ogun orí omi náà tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Akingbohumi ní ànàbolẹ̀ nígbà tí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàárín wọn.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Funmilayo Odunlami nígbà tó ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọwọ́ ti tẹ àwọn mẹ́ta nínú àwọn afurasí mẹ́fà tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó ní àwọn ti ń fimú fínlẹ̀ láti ṣe àwárí àwọn yòókù.

Odunlami ní kò ní pẹ́ tí àwọn máa fi gbé àwọn afurasí náà lọ sí oríkò Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fún ìwádìí tó péye.

Ìròyìn ní ọwọ́ tẹ àwọn afurasí náà ní àwọn ibi tí wọ́n fi ara pamọ́ sí lẹ́yìn tí àwọn adarí ìlú náà bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti ṣe àwárí wọn.

Olórí ìlú ọ̀hún nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ tí Akingbohumi ti ń ṣiṣẹ́ ṣèlérí fún ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà pé ìlú máa fi ojú àwọn aṣebi hàn.

Wọn ṣèlérí pé láàárín ọjọ́ kan ni àwọn máa pèsè àwọn afurasí náà.

Àwọn ọ̀dọ́ ṣekúpa ‘Navy’ ní ìpínlẹ̀ Ondo, làwọn ológun bá ya wọ ìlú

Navy

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ọmọ-ogun ori omi ti ya bo ilu Idoani, nijọba ibilẹ Ose, nipinlẹ Ondo latari bi awọn janduku kan ṣe ṣekupa ọkan lara awọn ologun naa.

Iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ ni awọn ologun naa ya wọ ilu ọhun lati fi panpẹ ọba mu awọn to lọwọ ninu iṣekupani naa.

Eyi lo fa inu fuu aya fuu, leyi to mu ki ọpọ awọn ọlọja o gbe ibutaja wọn ti lati wa ibi ti wọn yoo fara pamọ si.

Ọpọ ọdọ ninu ilu naa ni wọn ti sa kuro nibẹ bi wọn ṣe ni awọn ologun naa ṣeleri lati gbẹsan iku akẹgbẹ wọn to padanu ẹmi rẹ ninu ilu ọhun.

Bi wahala naa ṣe bẹrẹ

Ọkan lara awọn olugbe ilu Idoani ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni “ọmọ ologun ‘navy’ naa fi ọkọ rẹ ta omi si okunrin kan lara lori ọkada nibi to ti n gbiyanju lati ya fun koto”.

“Oloogbe ọun sọkalẹ ninu ọkọ rẹ lati bẹ ọlọkada ọhun ati ero rẹ amọ wọn ko feti si ẹbẹ ọkunrin naa.”

“Ọlọkada naa ti wọn pe orukọ ni Ayo, to si ni ọpọ janduku to n wari fun-un kesi awọn alatilẹyin rẹ lati waa fi iya jẹ ọmọ ologun naa.”

“Awọn janduku ọhun ya bo ologun naa ti ọkan ninu wọn si la irin mọọ lori leyi to mu ko wo lulẹ.”

Ọmọ ologun naa ni wọn wi pe wọn gbe digbadigba lọ ile iwosan ijọba to wa ni ilu naa amọ to ti dakẹ ki wọn too gbe debẹ.

Ọlọkada naa ni a gbọ pe wọn fa le awọn ọlọpaa lọwọ amọ ẹni to la irin mọ oloogbe lori lo fi ẹsẹ fẹẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC News Yoruba wipe “ọkunrin kan to n jẹ Sunday Olaoluwa ni agbegbe Iyayu nilu Idoani lo fi ẹjọ sun awọn ọlọpaa pe ọrẹ ohun kan, M. Akingbohun to jẹ ‘Navy’ to wa pẹlu ile ẹkọ girama awọn ‘Navy’ nilu Imeri ni awọn mẹfa kan ti ‘Oyibo’ dari wọn ṣe akọlu si lẹyin ariyanjiyan to waye laarin wọn.”

“Ọkan lara awọn to ṣe akọlu sii naa la irin mọọ lori leyi to ṣe ipalara to pọ fun-un.”

“Awọn dokita fi idi rẹ mulẹ nile iwosan pe ọkunrin naa ti jade laye nigba ti wọn gbe debẹ.

“A ṣi n wa awọn afunrasi to lọwọ ninu iku ologun ọun.”

Ẹwẹ, alaga ijọba ibilẹ Ose, Dennis Adekunle, ti bu ẹnu atẹ lu iṣekupani naa to si juwe rẹ bii ohun to buru pupọ.

Adekunle, ninu atẹjade kan to buwọlu funra rẹ rọ awọn ‘Navy’ lati ṣe pẹlẹ nipa wiwa awọn to lọwọ ninu iṣekupani ọkan lara wọin ko ma baa di yanpọnyanrin.

Alaga kansu naa ran awọn ọmọ-ogun naa leti ajọṣepọ to dan mọran to ti wa laarin wọn ati awọn araalu agbegbe naa lati ọjọ ti wọn da ile ẹkọ naa silẹ di akoko yii.

Adekunle wi pe: “mo fi da awọn adari ile ẹkọ naa loju pe ijọba ibilẹ wa ati gbogbo araalu yoo ṣe atilẹyij to jọju fun wọn lati pinwọ laasigbo ni agbegbe naa”.