Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ọ̀jọ̀gbọ́n Lai Oso, olùkọ́ LASU tó di olóògbé

Profeesor Lai Oso

Oríṣun àwòrán, @GERMANEO

Ọjọgbọn Lai Oso, to jẹ olukọ nipa imọ iroyin kikọ ni fasiti ijọba ipinlẹ Eko, LASU, ti di oloogbe.

Oloogbe naa jade laye lẹyin ijamba ọkọ kan to waye lalẹ ọjọ Abamẹta.

Iroyin ni ijamba ọkọ ọhun waye lasiko ti ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin naa n bọ lati ibi ipade kan niluu Abraka, nipinlẹ Delta.

Awọn to mọ olukọ naa nigba aye rẹ juwe rẹ gẹgẹ bii oniwa rere ti ọpọ awọn akẹkọọ rẹ fẹran pupọ, ti wọn si bu ọla fun.

Awọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa oloogbe ọhun

Orukọ abisọ rẹ ni Muraino Olayiwola Oso, o si kẹkọọ gboye nipa imọ iroyin kikọ ni fasiti ijọba ipinlẹ Eko, UNILAG.

O tẹsiwaju lati kẹkọọ gboye si ni fasiti Obafemi Awolowo, OAU, nibi to ti gboye ‘masters’ nipa ibaṣepọ laarin awọn orilẹ-ede.

Lati ibẹ lọ, Oso tẹkọ leti lọ silẹ Gẹẹsi lọdun 1977 lati kẹkọọ siwaju si ni fasiti Leicester.

Oloogbe naa ṣiṣẹ gẹgẹ bii akọroyin lori redio ati nileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria fun ọpọ ọdun.

Laarin ọdun 2011 si 2015, o ṣiṣẹ gẹgẹ bii olori awọn olukọ ni ẹka imọ ‘Mass Communication and Media Studies’ ni LASU.

Ṣaaju iku rẹ, oun ni Aarẹ ẹgbẹ awọn ọmọwe nipa ẹkọ imọ iroyin kikọ ni Naijiria.

Oloogbe naa kọ awọn akẹkọọ nipa imọ iroyin kikọ fun ọpọ ọdun, pupọ ninu awọn akẹkọọ rẹ lo si n ṣiṣẹ lawọn ileeṣẹ iroyin to lamilaka kaakiri Naijiria ati loke okun.

Wo diẹ lara nnkan ti awọn eeyan n sọ nipa oloogbe ọhun

Ọpọ awọn mọlẹbi, akẹkọọ ati ojulumọ oloogbe naa lo ti bẹrẹ si n ṣedaro lẹyin iku rẹ bayii.

Pupọ ninu wọn ni wọn lo sọrọ lori ipa rere to ko ninu igbesi aye wọn gẹgẹ bii akẹkọọ ati lẹyin ile ẹkọ.

aworan

Oríṣun àwòrán, @Damilola

Profeesor Lai Oso

Oríṣun àwòrán, Abiodun Lasile

Awọn miran ti wọn tun sọrọ nipa oloogbe naa ni Akọṣemọṣẹ ayaworan ile to tun jẹ olukọni agba, Dodo Madariola to sọ pe:

" N ko mọ́ bi mi ko ba ṣe juwe ọjọgbọn to jẹ Baba oninuure yii; ọpọ igba ni wọn maa n ni ara wọn lára lati fa ọmọ ẹlomii soke lẹ́nu iṣẹ. Ojọgbọn Lai Oso jẹ baba fún ọpọlọpọ ni Moshood Abiola Polytechnic ati fun awọn ojulumọ yatọ si ni adugbo ti wọn ti gbe ni Aṣero ati kaakiri.

Igi nla lo wo ninu igbo awọn ọmọwe lasiko yii ati ninu ijọ Olọrun.

Ki Olodumare tu gbogbo ẹbi ọjọgbọn Lai Oso ninu ki o si ba wa tẹ wọn si afẹfẹ rere" .

Profeesor Lai Oso

Oríṣun àwòrán, Anike-ade Funke Treasure