Adewale and Funmilayo Deaf couple taylor: Bí a ṣe tọ́ àwọn mọ wà dàgbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ya ni lẹ́nu

Àkọlé fídíò, 'Ìjámbá Ọ̀kadà ló dédé sọ mi di òdi, ìyàwó tí mo yó ìfẹ́ rẹ̀ náà tún wá jẹ́ odi'

"Àwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta táa bí ń gbọ́ran wọ́n sì le sọ̀rọ̀".

Yoruba ni ba o ku, iṣe o tan, eyi lo difa fun lọkọlaya yii ti wọn o jẹ ki ireti wọn o pin botilẹ jẹ pe odi ni awọn mejeeji.

Adewale to jẹ ọkọ ṣalaye nipa fifi ọwọ rẹ sọ̀rọ̀ fun BBC Yoruba pe nigba ti wọn bi oun, oun le sọrọ, "ṣugbọn nigba ti mo n dagba ni mo ni ijamba ọkada to fa bi mo ṣe di odi".

O ṣalaye pe igba ti wọn maa fi gbe oun de ile iwosan, ti wọ̀n tọju rẹ ti ara rẹ ya tan ni wọn ṣakiyesi pe ko le gbọ ọrọ mọ.

Ilu Akure ni Adewale ati OluwaFunmilayo iyawo rẹ ti jọ da owo pọ ti wọn yan jọ yan iṣẹ ranṣọ-ranṣọ laayo.

" Mo gbọrọ lati kekere, igba ti mo dagba to ọmọ ọdun mẹsan si mẹwa ni mo ya odi".

Adewale ṣalaye pe ile iwe fun awọn odi to wa ni Akure lawọn ti pade.

Ọmọ iṣẹ Adewale to n ṣe ongbufọ fun BBC Yoruba, Damilola Faroye ni ọga oun ninu iṣẹ telọ, Adewale lo kọ oun ni ọpọ nkan ti oun mọ nipa fifi ọwọ sọrọ bii odi titi ti oun ti gbayi ni ṣọọṣi oun toun maa n ṣe ongbufọ.

Nibayii, Adewale ti n ran aṣọ igbalode "suit" ti awọn alakọwe maa n wọ to fi mọ oniruuru awọn aṣọ igba de igba.