Ìròyìn ayọ̀! Òṣèrébìnrin, Bimpe Akintunde 'Wasila Coded' di ọlọ́kọ

Adebimpe akintunde ati ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Adebimpe Akintunde/Instagram

Ẹnikan pataki lara awọn oṣerebinrin yoruba, Bimpe Akintunde, ti awọn ololufẹ rẹ tun mọ si Wasila Coded, ti kede pe ololufẹ rẹ ti fun ni oruka ileri igbeyawo.

Arabinrin Akintunde to jẹ iya ọlọmọ kan, fi ikede naa sita ni ori ayelujara Instagram rẹ ni ni owurọ ọjọ Aiku, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2023.

Ninu ọrọ to kọ si abẹ awọn aworan to fi sita, o ni ọkunrin naa to fẹ fi oun ṣe aya, ti wa ninu irinajo ifẹ pẹlu oun lati ọjọ pipẹ.

“Lonii, mo sọ pe bẹẹni fun ẹni to nifẹ iṣẹ mi, ololufẹ mi lati ọjọ pipẹ, ọkunrin to ti nifẹẹ mi ṣaaju ki n to mọ ọ.”

Akintunde ṣalaye pe ibukun nla lo jẹ fun oun lati pade ọkunrin naa.

Botilẹ jẹ pe ko kọkọ fi aworan ọkunrin naa sita, o fi aworan oruka wura ti ololufẹ rẹ ọhun fi da majẹmu igbeyawo pẹlu rẹ.

Ninu fidio ti ọkan lara awọn oṣere to sun mọ Bimpe Akintunde, Olatoun Olanrewaju fi sita ni ọjọ Aiku bakan naa, o jọ pe lonii yii gan-an ni Bimpe ati ọkọ afẹsọna rẹ ti n ṣe ayẹyẹ mọ̀mí-n-mọ̀ ọ́, laarin ẹbi awọn mejeeji.

Bakan naa ni oun funra rẹ fi awọn fidio kan si ori Instagram Story rẹ to tọka si pe ayẹyẹ naa ti waye.

Lati igba ti si ti fi ikede igbeyawo naa sita, ni awọn ololufẹ ati akẹẹgbẹ rẹ ti n ki ku oriire ati imura silẹ fun ọjọ ayẹyẹ igbeyawo.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ṣugbọn ṣa, nigba ti yoo fi di irọlẹ ọjọ Aiku, Arabinrin Adebimpe ṣe afihan bi eto Nikkai ṣe n waye laarin awọn mejeeji han awọn ololufẹ rẹ lori ayelujara Instagram.

Taa ni Adebimpe Akintunde ‘Wasila Coded’?

Gbajumọ ni Arabinrin Akintunde lagbo ere tiata yoruba.

Ni nnkan bi ọdun 1980 ni wọn bi i. Yatọ si pe o jẹ oṣere, Wasila coded tun jẹ olukọtan, ati agbohunsafẹfẹ lori redio ati tẹlifisan.

O kẹkọọ jade ni fasiti Olabisi Onabanjo to wa ni ipinlẹ Ogun.

O ti bi ọmọ obinrin kan ṣaaju.

Laipẹ yii ni oṣerebinrin naa sẹ ifilọlẹ ileeṣẹ redio to da silẹ, eti to pe orukọ rẹ ni Coded FM.

Nnkan to yẹ ki o mọ nipa ọkọ Bimpe Akintunde

Orukọ ọkọ oṣerebinrin to di iyawo tuntun ni Yousuph O Ganiyu, gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni oju opo Instagram rẹ ti Bimpe fi sita.

Ilu Minnesota, orilẹ-ede America ni ọgbẹni Ganiyu n gbe, botilẹ jẹ pe ọmọ Naijiria ni.

O jẹ ẹni to n ba ni gbe sinima agbelewo jade, orin, ati awọn okoowo miran ni ẹka amuludun.

Ọgbẹni Ganiyu ni oludasilẹ Yoruba Plug TV, oju opo ti wọn ti n ṣe afihan awọn sinima Yoruba lori ayelujara.

Bakan naa lo tun jẹ oniṣowo ni ẹka irinna.